Àpótí Ìbéèrè
◼ Ṣé ó yẹ kí ìjọ gbé àwòrán-ilẹ̀ tó ń fi gbogbo ìpínlẹ̀ ìjọ hàn kọ́ sára ògiri nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba?
Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kí ẹ lẹ àwòrán-ilẹ̀ tó ń fi gbogbo ìpínlẹ̀ ìjọ hàn mọ́ ara pátákó kan kí ẹ sì gbé e kọ́ ara ògiri nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ẹ má ṣe lẹ̀ ẹ́ mọ́ ara pátákó ìsọfúnni. Kí àwòrán-ilẹ̀ ọ̀hún fi gbogbo ààlà ìpínlẹ̀ tí a yàn fún ìjọ yín hàn, kí ó sì fi ààlà ìpínlẹ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan àti nọ́ńbà rẹ̀ hàn. Kí ẹ fi ààlà ìpínlẹ̀ gbogbo ìjọ tó bá jọ ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà hàn. Èyí yóò jẹ́ kí àwọn akéde àti àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fìfẹ́ hàn lè mọ inú ìpínlẹ̀ ìjọ tí wọ́n ń gbé. Fífi ibi tí ẹ ti ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ hàn lórí àwòrán-ilẹ̀ náà yóò tún ran gbogbo ìjọ lọ́wọ́ láti lè mọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ táa yàn wọ́n sí. Kí ẹ rí i pé ẹ ń mú kí àwòrán-ilẹ̀ náà bá ìgbà mu.
Gbígbé irú àwòrán-ilẹ̀ yìí kọ́ sára ògiri máa ń rán gbogbo akéde létí pé bó bá ṣeé ṣe, yóò dára pé kí olúkúlùkù wọn ní ìpínlẹ̀ tí a yàn fún wọn. Àwòrán-ilẹ̀ yìí ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tó bá fẹ́ yan ìpínlẹ̀ tó sún mọ́ ilé wọn. Ó lè dín àkókò tí ẹ ń lò níbi ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn kù nígbà míì, tí yóò sì jẹ́ kí olùdarí lè tètè darí olúkúlùkù àwùjọ àwọn akéde sí àgbègbè tí a yàn fún wọn láti lọ ṣiṣẹ́.
Àwòrán-ilẹ̀ yìí tún jẹ́ ẹ̀rí pé ìjọ yín ní ètò tó dáa fún wíwàásù ìhìn Ìjọba náà kúnnákúnná ní ìpínlẹ̀ táa yàn fún un.—Lúùkù 9:6.