Bí A Ṣe Lè Wàásù Ní Ìpínlẹ̀ Táwọn Èèyàn Ti Ń Ṣiṣẹ́ Ajé
1. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tó wà nínú jíjẹ́rìí ní ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé?
1 Ṣé wàá fẹ́ láti wàásù ní ìpínlẹ̀ tí inú wọn ti máa ń dùn láti rí èèyàn, tí wàá sì rí ẹni bá sọ̀rọ̀? Ó ṣeé ṣe kí irú àwọn ibi bẹ́ẹ̀ wà nínú ìpínlẹ̀ ìjọ yín. O lè rí wọn tó o bá ń lọ sáwọn ibi ìtajà tó wà ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín. Ìsapá àwọn akéde tó ń jẹ́rìí láti ibi ìtajà sí ibi ìtajà máa ń sèso rere lọ́pọ̀ ìgbà.
2. Báwo la ṣe lè ṣètò ìjẹ́rìí níbi táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé?
2 Àwọn ibi táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé (títí kan ọjà) wà lára àwọn ìpínlẹ̀ tí a yàn fún àwọn ìjọ kan. Arákùnrin tó ń bójú tó ìpínlẹ̀ ìjọ lè ṣètò àwọn àkànṣe káàdì ìpínlẹ̀ tí yóò fi àwọn àgbègbè táwọn ibi iṣẹ́ ajé pọ̀ sí gan-an yìí hàn. Bó bá hàn lórí káàdì ìpínlẹ̀ kan pé àwọn ibi táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé wà nínú ìpínlẹ̀ náà, kí a sàmì tó ṣe kedere sórí káàdì náà láti fi hàn pé a kò ní láti ṣe àwọn ibi iṣẹ́ ajé náà pa pọ̀ mọ́ ibi táwọn èèyàn ń gbé. Àmọ́ láwọn ìpínlẹ̀ mìíràn, a lè wàásù láwọn ibi ìtajà nígbà kan náà tá à ń wàásù láwọn ibi táwọn èèyàn ń gbé. Bó ò bá tíì wàásù rí níbi táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé, bẹ̀rẹ̀ nípa wíwàásù láwọn ibi ìtajà kéékèèké bíi mélòó kan.
3. Kí ló máa jẹ́ kí ìjẹ́rìí wa múná dóko nígbà tá a bá ń jẹ́rìí láti ibi ìtajà sí ibi ìtajà?
3 Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Rọrùn Láti Lóye: Nígbà tó o bá ń wàásù láti ibi ìtajà sí ibi ìtajà, ó ṣe pàtàkì pé kó o múra bó o ṣe máa ń múra tó o bá ń lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bákan náà, àkókò tí ọwọ́ wọn ò ní dí níbi ìtajà náà ló yẹ kó o lọ. Bó bá ṣeé ṣe, ìgbà tí kò bá sí oníbàárà kankan tí wọ́n fẹ́ dá lóhùn ni kó o wọlé. Sọ pé o fẹ́ rí ọ̀gá wọn níbẹ̀. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe ṣókí, kó sì ṣe tààràtà. Kí lo lè sọ?
4-6. Kí la lè sọ nígbà tá a bá ń jẹ́rìí fún òṣìṣẹ́ ibi ìtajà kan tàbí ọ̀gá ibẹ̀?
4 Nígbà tó o bá ń bá òṣìṣẹ́ ibi ìtajà tàbí ọ̀gá tó wà níbẹ̀ sọ̀rọ̀, o lè sọ pé: “Ọwọ́ àwọn oníṣòwò máa ń dí gan-an débi pé a kì í fi bẹ́ẹ̀ bá wọn nílé, ìyẹn la fi wá bá yín níbi iṣẹ́. Ṣé ẹ rí i, àwọn ìwé ìròyìn wa máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ kárí ayé.” Lẹ́yìn èyí, tọ́ka sí kókó kan ní ṣókí látinú ìwé ìròyìn kan.
5 Yàtọ̀ síyẹn, o lè gbìyànjú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó rọrùn yìí: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa fẹ́ láti túbọ̀ lóye Bíbélì sí i àmọ́ tó jẹ́ pé wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè. Ìwé ìléwọ́ yìí ṣàlàyé ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀fẹ́ tẹ́ ẹ lè jàǹfààní látinú rẹ̀, èyí tó máa jẹ́ kẹ́ ẹ rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tẹ́ ẹ bá ní nínú Bíbélì.” Lẹ́yìn èyí, tọ́ka sí ojú ìwé 4 àti 5 nínú ìwé ìléwọ́ náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì?
6 Bó bá dà bíi pé ọwọ́ alábòójútó ibi ìtajà náà dí, o kàn lè fún un ní ìwé ìléwọ́ kan kó o wá sọ pé: “Màá tún wá síbí nígbà míì tí ọwọ́ yín ò bá fi bẹ́ẹ̀ dí. Màá fẹ́ mọ ohun tẹ́ ẹ rò nípa ìwé ìléwọ́ yìí.”
7. Báwo la ṣe lè mú kí ìfẹ́ táwọn èèyàn fi hàn ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ajé jinlẹ̀ sí i?
7 Mímú Kí Ìfẹ́ Táwọn Èèyàn Fi Hàn Jinlẹ̀ Sí I: Kódà, o tiẹ̀ lè máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé. Aṣáájú ọ̀nà àkànṣe kan máa ń mú ìwé ìròyìn lọ fún ọkùnrin oníṣòwò kan nígbà gbogbo. Nígbà tí ọkùnrin náà fi ìmọrírì hàn fún ohun tó ń kà, aṣáájú ọ̀nà náà fi ọ̀nà tá à ń gbà ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án, nípa lílo ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbi iṣẹ́ ọkùnrin yẹn gan-an. Arákùnrin náà máa ń gba ti oníṣòwò náà rò, nípa bẹ́ẹ̀ ó máa ń ké ìkẹ́kọ̀ọ́ náà kúrú sí ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní gbogbo ìgbà tó bá wá. Lọ́nà kan náà, ẹ jẹ́ káwa náà máa wá àwọn ẹni yíyẹ rí nípa jíjẹ́rìí ní ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé.