Wàásù Ìhìn Rere Náà Níbi Gbogbo
1 Àwọn Kristẹni ìjímìjí wàásù ìhìn rere náà níbi gbogbo. Wọ́n ní ìtara débi pé láàárín 30 ọdún lẹ́yìn tí a jí Jésù Kristi dìde, ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà ni a ti “wàásù nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.”—Kól. 1:23.
2 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n jẹ́ onítara lónìí ní ète ìlépa kan náà—láti mú ìhìn rere Ìjọba náà dé ọ̀dọ̀ gbogbo ẹni tí ó bá ṣeé ṣe láti dé. Kí ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàṣeparí góńgó yìí? Púpọ̀ ènìyàn sí i ń ṣiṣẹ́ fún àkókò kíkún, a kì í sì í sábà bá wọn nílé nígbà tí a bá ṣèbẹ̀wò. Nígbà tí wọn kò bá sí lẹ́nu iṣẹ́, wọ́n lè wà ní ìrìn àjò, wọ́n lè lọ rajà, tàbí kí wọ́n wà lẹ́nu irú àwọn eré ìtura kan. Báwo ni a ṣe ń mú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ó tọ́ sí lára wọn?—Mát. 10:11.
3 A ń kàn sí àwọn kan ní ibi iṣẹ́ wọn. Àní àwọn ìlú kékeré pàápàá máa ń ní ibi iṣẹ́ ajé tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sábà máa ń wà ní ọjọ́ púpọ̀ jù lọ. Ní àwọn ìlú ńlá, àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ní àwọn àgbègbè ilé iṣẹ́ tàbí àwọn ilé ọ́fíìsì olókè àti àwọn tí ń gbé ní àwọn ilé tí a dáàbò bò gidigidi ni a ń jẹ́rìí fún—tí ọ̀pọ̀ nínú wọn jẹ́ fún ìgbà àkọ́kọ́. Ní àwọn òpin ọ̀sẹ̀, a ti rí i pé àwọn kan tí a ti kàn sí nígbà tí wọ́n ń sinmi nínú àwọn ọgbà ìtura tàbí nínú àwọn ibi eré ìtura, tàbí nígbà tí wọ́n ń dúró ní ibi ìgbọ́kọ̀sí tàbí nínú ọjà, ní ìtẹ̀sí tí ó dára síhà ìhìn rere náà.
4 Iye àwọn akéde tí ó túbọ̀ ń pọ̀ sí i ń ṣe àkànṣe ìsapá láti jẹ́rìí ní ibi tí àwọn ènìyàn pọ̀ sí, níbikíbi tí wọ́n bá ti lè rí àwọn ènìyàn. Lákọ̀ọ́kọ́, Àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí lọ́ tìkọ̀ wọ́n sì ṣojora lọ́nà kan ṣáá nítorí pé jíjẹ́rìí ní àwọn ọ̀nà tí ó túbọ̀ jẹ́ bí àṣà, bíi láti ilé dé ilé ti mọ́ wọn lára. Báwo ni ìmọ̀lára wọn ṣe rí nísinsìnyí?
5 Arákùnrin onírìírí kan fi ìdánilójú sọ pé: “Ó ti túbọ̀ mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi jí pépé!” Òmíràn fi kún un pé: “Ó mú kí n pọkàn pọ̀.” Àgbàlagbà aṣáájú ọ̀nà kan sọ pé: “Ó ń fúnni lókun ní ti èrò orí, nípa ti ara, àti nípa ti ẹ̀mí, . . . mo sì ń tẹ̀ síwájú sí i.” Akéde kan sọ pé nísinsìnyí òun ń dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn tí kò tí ì bá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀ rí. Àwọn ọ̀dọ́ pẹ̀lú ń fi ìtara ọkàn nípìn-ín nínú iṣẹ́ tí ń gbádùn mọ́ni yìí. Èwe kan ṣàlàyé ara rẹ̀ lọ́nà yí: “Ìgbádùn ni, nítorí pé, àwọn tí ìwọ yóò bá sọ̀rọ̀ yóò pọ̀.” Òmíràn wí pé: “Mo ń fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sóde ju bí mo ti ń ṣe tẹ́lẹ̀!” Gbogbo èyí ń ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ tí a ń ṣe léraléra.
6 Àwọn Alábòójútó Arìnrìn-Àjò Ń Mú Ipò Iwájú: Ní mímọ̀ pé “ìrísí ìran ayé yìí ń yí pa dà,” lẹ́nu àìpẹ́ yìí Society dábàá pé kí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò máa yí ìṣètò iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ pa dà kí a baà lè mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. (1 Kọ́r. 7:31) Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn alábòójútó àyíká ti ya òwúrọ̀ àwọn ọjọ́ àárín ọ̀sẹ̀ sọ́tọ̀ láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ilé dé ilé, nígbà tí wọ́n ń fi ọ̀sán ṣe ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní àwọn àgbègbè kan, ìṣètò yẹn ṣì lè gbéṣẹ́. Ní àwọn ibòmíràn, a lè má fi bẹ́ẹ̀ ṣàṣeyọrí ohunkóhun nípa ṣíṣiṣẹ́ láti ilé dé ilé ní òwúrọ̀ àwọn ọjọ́ kan láàárín ọ̀sẹ̀. Nínú irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, alábòójútó arìnrìn-àjò lè pinnu pé ní ọwọ́ àárọ̀ yóò dára láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ilé ìtajà dé ilé ìtajà tàbí ìjẹ́rìí òpópónà. Tàbí ó lè ṣètò fún àwọn àwùjọ kéékèèké láti jẹ́rìí ní àwọn ilé ọ́fíìsì olókè, ibi ìrajà, ibi ìgbọ́kọ̀sí, tàbí ibòmíràn tí àwọn ènìyàn pọ̀ sí. Nígbà tí àwọn akéde bá lo àkókò tí ó ṣí sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́nà tí ó túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i, a óò lè dé ọ̀dọ̀ ènìyàn púpọ̀ sí i.
7 Ìròyìn fi hàn pé àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti àwọn akéde bákan náà tẹ́wọ́ gba ìyípadà yí dáradára. Ẹgbẹ́ àwọn alàgbà mélòó kan ti rọ alábòójútó àyíká láti dá àwọn akéde díẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ lórí àwọn apá iṣẹ́ náà tí ń fẹ́ àfiyèsí ládùúgbò wọn. Ó ti ṣèrànwọ́ fún àwọn akéde wọ̀nyí láti wà pẹ̀lú alábòójútó arìnrìn-àjò bí ó ti ń lọ́wọ́ nínú ọ̀kan nínú àwọn ìgbòkègbodò wọ̀nyí. Ó sì ti ṣeé ṣe fún àwọn náà láti dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́. (2 Tím. 2:2) Ní ìyọrísí rẹ̀, a ti ń mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ púpọ̀ ènìyàn sí i nísinsìnyí.
8 Àmọ́ ṣáá o, kò sí ìdí fún ọ láti dúró pé kí alábòójútó àyíká ṣèbẹ̀wò láti gbìyànjú díẹ̀ nínú àwọn ọ̀nà ìwàásù míràn wọ̀nyí. Onírúurú àwòkọ́ṣe tí o lè rí i pé ó gbéṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ rẹ nìyí:
9 Ìjẹ́rìí Òpópónà: ‘Ibo ni àwọn ènìyàn wà?’ nígbà míràn, a máa ń ṣe kàyéfì bẹ́ẹ̀ nígbà tí a bá ṣèbẹ̀wò sí àgbègbè tí àwọn ènìyàn ń gbé tí ó dá páro ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan láàárín ọ̀sẹ̀. Ó lè jẹ́ pé àwọn kan lọ jíṣẹ́ tí ẹnì kan rán wọn, wọ́n lè lọ ra nǹkan, tàbí kí wọ́n lọ sí ọjà. O ha ti gbìyànjú láti dé ọ̀dọ̀ wọn nípasẹ̀ ìjẹ́rìí òpópónà bí? Nígbà tí a bá ṣe é lọ́nà yíyẹ, apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí lè mú èso jáde dáradára. Dípò dídúró sí ojú kan ní kíkó àwọn ìwé ìròyìn lọ́wọ́, ó dára jù lọ láti tọ àwọn ènìyàn lọ kí a sì bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́. Kò pọn dandan pé kí a jẹ́rìí fún gbogbo ẹni tí ó bá ń kọjá. Bá àwọn tí kò bá kánjú sọ̀rọ̀, irú bí àwọn tí ó wà nínú ọkọ̀ tí a páàkì tàbí àwọn ènìyàn tí ń dúró de ọkọ̀ èrò. Lákọ̀ọ́kọ́, o wulẹ̀ lè fi ọ̀yàyà kí ẹni náà kí o sì jẹ́ kí ó fèsì. Bí ẹni náà bá múra tán láti sọ̀rọ̀, béèrè èrò ọkàn rẹ̀ lórí kókó ẹ̀kọ́ tí o rò pé yóò lọ́kàn ìfẹ́ sí.
10 Alábòójútó arìnrìn-àjò kan ké sí àwọn akéde mẹ́fà láti dara pọ̀ mọ́ òun àti aya rẹ̀ nínú ìjẹ́rìí òpópónà. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Ó ròyìn pé: “A gbádùn òwúrọ̀ yẹn gan-an! Kò sí àwọn tí a kò bá nílé. A fi 80 ìwé ìròyìn àti ọ̀pọ̀ ìwé àṣàrò kúkúrú sóde. A ní ọ̀pọ̀ ìjíròrò tí ń runi sókè. Ọ̀kan lára àwọn akéde náà, tí ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òpópónà fún ìgbà àkọ́kọ́ fi ìtara sọ pé: ‘Mo ti wà nínú òtítọ́ láti iye ọdún yìí wá, n kò sì mọ̀ pé mo ti ń pàdánù nǹkan!’ Ní òpin ọ̀sẹ̀ náà, ìwé ìròyìn ìjọ tí ó ti ṣẹ́ jọ lọ sílẹ̀ gidigidi.”
11 Nígbà tí ó ń bẹ ìjọ tí ó tẹ̀ lé e wò, alábòójútó arìnrìn-àjò kan náà tí a ń wí yìí gbọ́ pé àwọn akéde kan ti nípìn-ín nínú ìjẹ́rìí òpópónà ní òwúrọ̀ kùtù ọjọ́ kan ṣùgbọ́n tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ ṣàṣeyọrí. Ènìyàn méjì péré ni arábìnrin kan bá sọ̀rọ̀ ní gbogbo àkókò ìjẹ́rìí náà níwọ̀n bí gbogbo àwọn mìíràn tí ó bá pàdé ti ń kánjú lọ sí ibi iṣẹ́. Alábòójútó arìnrìn-àjò náà dábàá pé kí gbogbo wọn pa dà lọ sí òpópónà kan náà ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn náà ní òwúrọ̀ ọjọ́ yẹn. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì dúró síbẹ̀ di ọ̀sán. Arábìnrin tí ó jẹ́ pé ìjíròrò méjì péré ni ó ní tẹ́lẹ̀ ní òwúrọ̀ ṣe dáradára sí i nígbà tí ó pa dà lọ. Ó fi ìwé ìròyìn 31 àti ìwé pẹlẹbẹ 15 sóde, ó gba orúkọ àti àdírẹ́sì àwọn ènìyàn méje, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé méjì! Àwọn yòó kù nínú àwùjọ náà ṣe àṣeyọrí tí ń fúnni níṣìírí bákan náà.
12 Nígbà tí o bá rí ẹnì kan tí ó fi ọkàn ìfẹ́ hàn, gbìyànjú láti gba orúkọ, àdírẹ́sì, àti nọ́ńbà tẹlifóònù rẹ̀. Dípò bíbéèrè fún ìsọfúnni náà ní tààràtà, o lè sọ pé: “Mo gbádùn ìjíròrò yí. Ọ̀nà kan ha wà tí a lè gbà máa bá ìjíròrò yí lọ nígbà míràn bí?” Tàbí kí o béèrè pé: “Ọ̀nà kan ha wà tí mo fi lè dé ọ̀dọ̀ rẹ ní ilé?” Ọ̀pọ̀ tí a ti kàn sí lọ́nà yí tẹ́wọ́ gba ìpadàbẹ̀wò. Rí i dájú pé o ní ìwé ìléwọ́ tí ó pọ̀ tó láti fi ké sí àwọn tí yóò fẹ́ láti wá sí àwọn ìpàdé wa.
13 Bí o bá bá olùfìfẹ́hàn kan tí ń gbé ní ìpínlẹ̀ tí a yàn fún ìjọ mìíràn sọ̀rọ̀, ó yẹ kí o fi ìsọfúnni náà ránṣẹ́ sí àwọn ará tí ó wà lọ́hùn-ún kí wọ́n baà lè pa dà ṣiṣẹ́ lórí ọkàn ìfẹ́ náà. Ìjẹ́rìí òpópónà yóò ha jẹ́ ọ̀nà gbígbéṣẹ́ láti tan ìhìn rere náà kálẹ̀ ní àgbègbè rẹ bí? Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣàtúnyẹ̀wò àpilẹ̀kọ náà, “Wíwá Àwọn Olùfìfẹ́hàn Rí Nípasẹ̀ Ìjẹ́rìí Òpópónà Tí Ó Gbéṣẹ́,” nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti July 1994. Lẹ́yìn náà, ṣètò láti lọ́wọ́ nínú ìjẹ́rìí òpópónà ní àkókò ọjọ́ tí ó bá a mu wẹ́kú tí yóò jẹ́ kí o lè dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó.
14 Jíjẹ́rìí Nínú Ọkọ̀ Èrò: Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan, àwọn aṣáájú ọ̀nà mélòó kan pinnu láti jẹ́rìí fún àwọn ènìyàn tí ń dúró de bọ́ọ̀sì nítòsí kọ́lẹ́ẹ̀jì kan ládùúgbò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní àwọn ìjíròrò lílárinrin díẹ̀, ìṣòro kan ṣẹlẹ̀. Bí ìjíròrò bá ti ń lọ lọ́wọ́, bọ́ọ̀sì yóò dé, yóò sì mú ìjíròrò náà wá sí òpin láìròtẹ́lẹ̀. Àwọn aṣáájú ọ̀nà náà yanjú ìṣòro yìí nípa wíwọ bọ́ọ̀sì tí wọ́n sì ń bá a nìṣó láti jẹ́rìí fún àwọn èrò ọkọ̀ bí wọ́n ti ń rìnrìn àjò láàárín ìlú. Bí bọ́ọ̀sì bá ti dé ibi tí ó ń lọ, àwọn aṣáájú ọ̀nà náà yóò tún bá bọ́ọ̀sì míràn pa dà tí wọn yóò sì máa jẹ́rìí bí wọ́n ti ń lọ. Lẹ́yìn ìrìn àjò mélòó kan lálọ lábọ̀, wọ́n ro ìyọrísí ìsapá tí wọ́n ṣe pọ̀: Wọ́n fi ìwé ìròyìn tí ó lé ní 200 sóde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́fà. Àwọn èrò ọkọ̀ kan fínnúfíndọ̀ fún wọn ní àdírẹ́sì àti nọ́ńbà tẹlifóònù wọn kí àwọn aṣáájú ọ̀nà náà baà lè ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn ní ilé. Ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e, àwọn aṣáájú ọ̀nà pa dà lọ sí ibùdókọ̀ náà, wọ́n sì lo ọ̀nà kan náà bíi ti tẹ́lẹ̀. Wọ́n fi ìwé ìròyìn 164 sóde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan sí i. Ní ibùdókọ̀ kan, ẹnì kan wọ bọ́ọ̀sì ó sì jókòó sí àyè kan ṣoṣo tí ó ṣí sílẹ̀—lẹ́gbẹ̀ẹ́ aṣáájú ọ̀nà kan. Ó wo arákùnrin náà ó sì sọ tẹ̀ríntẹ̀rín pé: “Mo mọ̀, o ní Ilé Ìṣọ́ kan láti fún mi.”
15 Ọ̀pọ̀ akéde jẹ́rìí lọ́nà gbígbéṣẹ́ nígbà tí wọ́n ń rìnrìn àjò nínú bọ́ọ̀sì, nínú ọkọ̀ ojú irin, tàbí nínú ọkọ̀ òfuurufú. Báwo ni o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú èrò ọkọ̀ tí ó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ? Akéde ọmọ ọdún 12 kan wulẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ka ẹ̀dà Jí! nínú bọ́ọ̀sì ni, ní ríretí láti rú ẹ̀mí ìwádìí ọmọdébìnrin tí ó jẹ́ ọ̀dọ́langba tí ó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sókè. Ohun tí ó ń fẹ́ ṣẹlẹ̀. Ọmọdébìnrin náà béèrè ohun tí ó ń kà lọ́wọ́ rẹ̀, èwe náà sì dáhùn pé òun ń kà nípa ojútùú sí àwọn ìṣòro tí àwọn ọ̀dọ́ ń dojú kọ. Ó fi kún un pé òun ti jàǹfààní gidigidi láti inú àpilẹ̀kọ náà àti pé ó lè ran ọmọdébìnrin náà lọ́wọ́ pẹ̀lú. Ó fi ayọ̀ gba àwọn ìwé ìròyìn náà. Ìjíròrò wọn ta sí àwọn èwe méjì míràn létí tí àwọn náà sì béèrè fún ẹ̀dà àwọn ìwé ìròyìn náà. Nítorí èyí, awakọ̀ náà rọra páàkì kúrò lójú ọ̀nà ó sì béèrè ìdí tí àwọn ìtẹ̀jáde náà fi gba ọkàn ìfẹ́ tó bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó mọ ìdí rẹ̀ òun pẹ̀lú gba àwọn ẹ̀dà. Dájúdájú, kò sí èyíkéyìí nínú èyí tí ì bá ṣeé ṣe bí kì í bá ṣe pé ọ̀dọ́ akéde náà ní àwọn ìwé ìròyìn tí ó pọ̀ láti pín fún gbogbo ẹni tí ó fi ọkàn ìfẹ́ hàn ni!
16 Jíjẹ́rìí Nínú Àwọn Ọgbà Ìtura àti ní Ibi Ìgbọ́kọ̀sí: Jíjẹ́rìí nínú àwọn ọgbà ìtura àti ní ibi ìgbọ́kọ̀sí jẹ́ ọ̀nà kan tí ó ta yọ lọ́lá láti dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn. O ha ti gbìyànjú láti jẹ́rìí ní àgbègbè ìgbọ́kọ̀sí ti ibùdó ìtajà kan bí? Máa lo àkókò díẹ̀ láti wo àyíká rẹ. Kíyè sí ẹni tí kò kánjú tàbí tí ó wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí a páàkì kí o sì gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́. Bí ìjíròrò náà bá ń bá a nìṣó, mú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà wọ̀ ọ́. Gbìyànjú láti dá ṣiṣẹ́ ṣùgbọ́n kí akéde mìíràn wà nítòsí. Yẹra fún gbígbé àpò ńlá tí ó wú bẹ̀ǹbẹ̀ kí o sì yẹra fún pípe àfiyèsí sí iṣẹ́ rẹ ní àwọn ọ̀nà míràn. Lo òye. Ó lè dára jù lọ láti lo àkókò díẹ̀ ní ibi ìgbọ́kọ̀sí kan kí o sì lọ sí ibòmíràn. Bí kò bá wu ẹnì kan láti bá ọ sọ̀rọ̀, rọra máa bá tìrẹ lọ kí o sì wá ẹlòmíràn láti bá sọ̀rọ̀. Ní lílo àwọn ọ̀nà wọ̀nyí, arákùnrin kan fi ìwé ìròyìn 90 sóde nínú oṣù kan nígbà tí ó ń wàásù ní àwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí.
17 Àwọn ènìyàn kan máa ń lọ sí ọgbà ìtura láti sinmi; àwọn mìíràn máa ń lọ síbẹ̀ láti ṣe eré àṣedárayá kan tàbí láti lo àkókò pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Láìdí ìgbòkègbodò wọn lọ́wọ́ púpọ̀, máa wá àǹfààní láti jẹ́rìí fún wọn. Arákùnrin kan bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹni tí ń bójú tó ìmọ́tótó ilẹ̀ ọgbà ìtura kan, ó sì rí i pé ọkùnrin náà ń ṣàníyàn nípa oògùn líle àti ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọ rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, wọ́n sì ń ṣe é déédéé nínú ọgbà ìtura náà.
18 Jíjẹ́rìí Nínú Ọjà: Nígbà tí o bá ń kí ẹnì kan, bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò náà lọ́nà ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́. Bí ẹni tí o ń bá sọ̀rọ̀ bá dáhùn pa dà, béèrè ìbéèrè kan, lẹ́yìn náà tẹ́tí sílẹ̀ dáradára bí ó ṣe ń sọ̀rọ̀. Fi ọkàn ìfẹ́ hàn nínú ohun tí ó ń sọ. Fi hàn pé o mọrírì èrò ọkàn rẹ̀. Níbi tí ó bá ti ṣeé ṣe, fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀.
19 Arábìnrin kan bá àgbàlagbà obìnrin kan jíròrò lọ́nà tí ń gbádùn mọ́ni nípa mímẹ́nukan bí owó ìgbọ́bùkátà ti pọ̀ tó. Obìnrin náà gbà lójú ẹsẹ̀, ìjíròrò tí ń tani jí sì bẹ̀rẹ̀. Ó ṣeé ṣe fún arábìnrin náà láti gba orúkọ àti àdírẹ́sì obìnrin náà, ó sì ṣe ìpadàbẹ̀wò ní ọ̀sẹ̀ kan náà yẹn.
20 Ṣíṣiṣẹ́ Láti Ilé Ìtajà Dé Ilé Ìtajà: Àwọn ìjọ kan ní àwọn àgbègbè iṣẹ́ ajé gẹ́gẹ́ bí apá kan ìpínlẹ̀ tí a yàn fún wọn. Arákùnrin tí ń bójú tó ìpínlẹ̀ náà lè ṣètò àwọn káàdì àwòrán ilẹ̀ apá ibi tí ó kún fún ibi iṣẹ́ ajé yìí lákànṣe. Àwọn káàdì àwòrán ilẹ̀ èyíkéyìí tí ó jẹ́ ti ìpínlẹ̀ tí ènìyàn ń gbé, tí ó wọnú àwọn àgbègbè iṣẹ́ ajé wọ̀nyí gbọ́dọ̀ fi hàn pé àwọn àgbègbè iṣẹ́ ajé náà ni a kò gbọ́dọ̀ ṣe gẹ́gẹ́ bí apá kan ìpínlẹ̀ náà. Ní àwọn ìpínlẹ̀ míràn, a lè ṣe àwọn ibi iṣẹ́ ajé pọ̀ mọ́ àwọn ibi tí ènìyàn ń gbé. Àwọn alàgbà lè ké sí àwọn akéde tí ó tóótun láti ṣiṣẹ́ ní àwọn ìpínlẹ̀ iṣẹ́ ajé láti ìgbà dé ìgbà kí ó baà lè jẹ́ pé iṣẹ́ ilé ìtajà dé ilé ìtajà ni a kì yóò pa tì.
21 Bí a bá ké sí ọ láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ yìí tí o kò sì tí ì ṣe é rí, ọ̀nà kan láti “máyà le” jẹ́ láti kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ ní àwọn ilé ìtajà kéékèèké mélòó kan; lẹ́yìn náà, nígbà tí ìgboyà rẹ bá túbọ̀ pọ̀ sí i, kí o ṣiṣẹ́ ní àwọn tí ó túbọ̀ tóbi sí i. (1 Tẹs. 2:2) Nígbà tí o bá ń ṣiṣẹ́ láti ilé ìtajà dé ilé ìtajà, múra bí ìwọ yóò ṣe ṣe bí o bá ń lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí ó bá ṣeé ṣe, wọ inú ilé ìtajà nígbà tí kò bá sí àwọn oníbàárà tí ń dúró pé kí a dá wọn lóhùn. Sọ pé o fẹ́ bá ọ̀gá tàbí ẹni tí ń bójú tó ibẹ̀ sọ̀rọ̀. Fi ọ̀yàyà hàn, ju gbogbo rẹ̀ lọ, ṣe ṣókí. Kò sí ìdí láti máa bẹ̀bẹ̀. Ọ̀pọ̀ ibi iṣẹ́ ajé máa ń ní àwọn oníbàárà, nítorí náà wọ́n máa ń retí ìdíwọ́.
22 Lẹ́yìn kíkí ẹni tí ń bójú tó ilé ìtajà kan, o lè sọ báyìí pé: “Ọwọ́ àwọn oníṣẹ́ ajé máa ń dí débi pé a kì í sábà bá wọn nílé, nítorí èyí ni a ṣe ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ níhìn-ín ní ibi iṣẹ́ ajé rẹ láti fún ọ ní àpilẹ̀kọ kan tí ń múni ronú gidigidi láti kà.” Lẹ́yìn náà sọ gbólóhùn kan tàbí méjì nípa ìwé ìròyìn tí o fi lọ̀ ọ́.
23 O sì lè gbìyànjú èyí nígbà tí o bá fẹ́ bá ọ̀gá kan sọ̀rọ̀: “A ti ṣàkíyèsí pé àwọn oníṣẹ́ ajé máa ń sakun láti mọ̀ nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀. Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ (tàbí Jí!) tí ó dé kẹ́yìn gbé àpilẹ̀kọ kan tí ó kan gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan jáde lákànṣe.” Ṣàlàyé ohun tí ó jẹ́ kí o sì parí ọ̀rọ̀ rẹ nípa sísọ pé: “Ó dá wa lójú pé ìwọ yóò gbádùn kíkà á.” Lẹ́yìn náà, fi lọ̀ ọ́ ní iye tí a ń fi í síta.
24 Bí àwọn ẹni àgbàsíṣẹ́ bá wà, tí ó bá sì dà bíi pé ó bá a mu wẹ́kú, o lè fi kún un pé: “Ṣé ìwọ yóò fara mọ́ ọn bí mo bá bá àwọn ẹni àgbàsíṣẹ́ rẹ sọ ọ̀rọ̀ ṣókí kan náà?” Bí ó bá fún ọ láyè, rántí pé o ti ṣèlérí láti ṣe ṣókí, ọ̀gá náà yóò sì retí pé kí o ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti sọ. Bí àwọn ẹni àgbàsíṣẹ́ èyíkéyìí bá fẹ́ láti wọnú ìjíròrò gígùn, yóò dára jù lọ pé kí o kàn sí wọn ní ilé wọn.
25 Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn akéde mélòó kan ní ìlú kékeré kan dara pọ̀ mọ́ alábòójútó àyíká nínú iṣẹ́ ilé ìtajà dé ilé ìtajà. Ẹ̀rù kọ́kọ́ ba díẹ̀ lára àwọn akéde náà níwọ̀n bí wọn kò tí ì ṣe iṣẹ́ náà rí; ṣùgbọ́n kò pẹ́ tí ara fi tù wọ́n tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn rẹ̀. Láìtó wákàtí kan, wọ́n bá ènìyàn 37 sọ̀rọ̀ wọ́n sì fi ìwé ìròyìn 24 àti ìwé pẹlẹbẹ 4 sóde. Arákùnrin kan sọ pé bí ó ti máa ń rí àwọn kì yóò lè kàn sí àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ní oṣù kan nínú iṣẹ́ ilé dé ilé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ láti ilé ìtajà dé ilé ìtajà láàárín àkókò kúkúrú yẹn.
26 Dídá Àǹfààní Láti Wàásù Sílẹ̀: Jésù kò fi ìjẹ́rìí rẹ̀ mọ sí àwọn ìgbékalẹ̀ tí ó jẹ́ bí àṣà. Ó tan ìhìn rere náà kálẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí ó bá a mu wẹ́kú. (Mát. 9:9; Lúùk. 19:1-10; Jòh. 4:6-15) Ṣàkíyèsí bí àwọn akéde kan ṣe ń dá àǹfààní láti wàásù sílẹ̀.
27 Àwọn kan sọ ọ́ dàṣà láti jẹ́rìí fún àwọn òbí tí wọ́n ń dúró de àwọn ọmọ wọn nítòsí ibi àbáwọlé ilé ẹ̀kọ́. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ òbí tí máa ń dé ní nǹkan bí 20 ìṣẹ́jú ṣáájú, àkókò wà láti mú wọn wọnú ìjíròrò tí ń tani jí lórí kókó ọ̀rọ̀ kan nínú Ìwé Mímọ́.
28 Ọ̀pọ̀ aṣáájú ọ̀nà máa ń wà lójúfò láti dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n lè ní àkànṣe ọkàn ìfẹ́ nínú kókó ẹ̀kọ́ kan ní pàtó tí a jíròrò nínú àwọn ìwé ìròyìn wa. Fún àpẹẹrẹ, arábìnrin kan rí ìdáhùnpadà rere gbà nígbà tí ó ṣèbẹ̀wò sí ilé ẹ̀kọ́ mẹ́fà ní ìpínlẹ̀ ìjọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́ kókó ẹ̀kọ́ náà “Ilé Ẹ̀kọ́ Nínú Yánpọnyánrin,” tí ó fara hàn nínú Jí! December 22, 1995. Ó tún ṣèbẹ̀wò sí àjọ tí ń bójú tó ọ̀ràn ìdílé pẹ̀lú àwọn ìwé ìròyìn tí ó sọ̀rọ̀ lórí ìgbésí ayé ìdílé àti lílo ọmọdé nílòkulò wọ́n sì sọ fún un pé kí ó tún bá wọn mú àwọn ìtẹ̀jáde tí ó bá sọ̀rọ̀ lórí àwọn àkòrí kan náà wá lọ́jọ́ iwájú. Ìdáhùnpadà tí ó rí gbà, ní ọ́fíìsì tí ń bójú tó ọ̀ràn àìríṣẹ́ṣe, sí Jí! March 8, 1996, tí ó sọ̀rọ̀ lórí àìríṣẹ́ṣe ni ó ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan tí ó “kọ yọyọ.”
29 Alábòójútó àgbègbè kan ròyìn pé òun àti ìyàwó òun máa ń jẹ́rìí déédéé nígbà tí àwọn bá lọ ra àwọn èèlò oúnjẹ. Wọ́n máa ń lọ ra nǹkan ní àkókò tí ilé ìtajà kò bá kún fún èrò tí àwọn oníbàárà sì rọra ń rìn lọ rìn bọ̀ ní àwọn ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀. Wọ́n ròyìn ọ̀pọ̀ ìjíròrò àtàtà.
30 Ní àwọn àdúgbò kan, àwọn akéde tí a yàn ní ọlá àṣẹ láti jẹ́rìí ní àwọn pápákọ̀ òfuurufú. Nígbà míràn, wọ́n ti ní ayọ̀ jíjẹ́rìí fún àwọn arìnrìn-àjò jákèjádò orílẹ̀-èdè tí ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè níbi tí àwọn ènìyàn Jèhófà kò ti fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan. Níbi tí wọ́n bá ti rí ọkàn ìfẹ́, wọ́n ń fi ìwé àṣàrò kúkúrú tàbí ìwé ìròyìn lọni.
31 Bí a kò bá gbà wọ́n láyè láti jẹ́rìí lójúkojú fún àwọn ayálégbé tí ń gbé ní àwọn ilé tàbí ní agboolé tí a dáàbò bò gádígádí ní ìpínlẹ̀ ìjọ wọn, àwọn kan ti sọ ọ́ dàṣà láti fọgbọ́n jẹ́rìí fún àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò. Ọ̀nà kan náà ni wọ́n lò ní àwọn àdúgbò àdáni tí a ṣe ẹnubodè sí. Alábòójútó àyíká kan àti àwọn akéde mélòó kan ṣèbẹ̀wò sí àwọn ibi ilé gbígbé méje lọ́nà yí. Nínú ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan, wọ́n sọ fún ọ̀gá ibẹ̀ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò gbà wọ́n láyè láti ṣe ìkésíni sínú àwọn ilé náà lọ́nà tí a ń gbà ṣe é, wọn kò fẹ́ kí ó pàdánù ìsọfúnni tí ó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn tí ó dé kẹ́yìn. Àwọn ọ̀gá tí wọ́n wà ní àwọn ilé méjèèje náà fi ayọ̀ gba àwọn ìwé ìròyìn náà wọ́n sì tún béèrè fún àwọn ìtẹ̀jáde tí ó tẹ̀ lé e pẹ̀lú! Lẹ́yìn náà, wọ́n kàn sí àwọn tí ń gbé nínú irú àwọn ilé bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ tẹlifóònù.
32 Lo Ara Rẹ Dé Góńgó Láti Jẹ́rìí Níbi Gbogbo: Gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa wé mọ́ níní èrò ìjẹ́kánjúkánjú nípa iṣẹ́ àyànfúnni wa láti wàásù ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà. Láti lè dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ní àkókò tí ó rọgbọ fún wọn, a ní láti gbé àwọn ohun tí a fẹ́ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan kí a “lè gba àwọn kan là lọ́nàkọnà.” Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fẹ́ láti lè sọ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti sọ pé: “Mo ń ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, kí èmi lè di alájọpín nínú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.”—1 Kọ́r. 9:22, 23.
33 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé síwájú sí i pé: “Nítorí náà, dájúdájú èmi yóò kúkú fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gan-an ṣògo nípa àwọn àìlera mi, kí agbára Kristi lè wà lórí mi bí àgọ́ kan. . . . Nítorí nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.” (2 Kọ́r. 12:9, 10) Lédè míràn, kò sí ẹnikẹ́ni lára wa tí ó lè ṣàṣeparí iṣẹ́ yìí nínú okun àwa fúnra wa. A ní láti gbàdúrà sí Jèhófà fún ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ alágbára. Bí a bá gbàdúrà sí Ọlọ́run fún okun, a lè ní ìgbọkànlé pé òun yóò dáhùn àwọn àdúrà wa. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́ tí a ní sí àwọn ènìyàn yóò sún wa láti wá àwọn àǹfààní láti wàásù ìhìn rere náà fún wọn níbikíbi tí a bá ti lè rí wọn. Ní ọ̀sẹ̀ tí ń bọ̀, èé ṣe tí o kò fi gbìyànjú ọ̀kan nínú àwọn àbá tí a gbé jáde lákànṣe nínú àkìbọnú yìí?