Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún June
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní June 2
Orin 181
8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá fún oṣù March, ti orílẹ̀-èdè àti ti ìjọ àdúgbò.
15 min: “Ẹ Máa Sa Gbogbo Ipá Yín.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.—Tún wo Ilé-Ìṣọ́nà, April 15, 1993, ojú ìwé 28 sí 30.
22 min: “Ìmọ̀ Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ń Dáhùn Ọ̀pọ̀ Ìbéèrè.” Olùbánisọ̀rọ̀ jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú akéde méjì tàbí mẹ́ta, tí ó ní èwe kan nínú. Sọ̀rọ̀ lórí ìpínrọ̀ 1, ní títẹnumọ́ ìdí tí ìwé Ìmọ̀ fi gbéṣẹ́ gidigidi ní ríràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè. Jẹ́ kí wọ́n ṣàṣefihàn ìfidánrawò kí o sì dábàá bí wọ́n ṣe lè ṣe dáradára sí i lẹ́yìn ìgbékalẹ̀ kọ̀ọ̀kan.
Orin 200 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní June 9
Orin 215
7 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Dábàá àwọn kókó ìbánisọ̀rọ̀ tí ó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́.
20 min: “Wàásù Ìhìn Rere Náà Níbi Gbogbo.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Kárí kìkì ìpínrọ̀ 1 sí 15 nìkan. Ka ìpínrọ̀ 3 àti 5. Fi àwọn ìrírí àdúgbò ti àwọn tí wọ́n ti ṣàṣeyọrí ní jíjẹ́rìí ní òpópónà tàbí nínú ọkọ̀ èrò kún un.
18 min: Kíkọ́ Àwọn Ẹlòmíràn—Àìní Kánjúkánjú Kan. Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà. Ṣàtúnyẹ̀wò ìròyìn iṣẹ́ ìsìn kárí ayé ti 1996 ní ojú ìwé 33 ìwé 1997 Yearbook. Ìsapá púpọ̀ sí i tí a ń ṣe láti jẹ́rìí fún àwọn ènìyàn níbikíbi tí a bá ti lè rí wọn ń so èso. Àìní kánjúkánjú tí ń bẹ nísinsìnyí jẹ́ láti ṣiṣẹ́ lórí gbogbo ìwé tí a ń fi sóde kí a sì kọ́ àwọn ènìyàn ní òtítọ́. Nígbà tí a bá pàdé wọn ní ìgboro, kí a fọgbọ́n béèrè orúkọ àti àdírẹ́sì wọn kí a baà lè ṣe ìpadàbẹ̀wò. A ní láti ṣe ju wíwulẹ̀ gbin irúgbìn Ìjọba náà; a tún gbọ́dọ̀ bomi rin ín. (1 Kọ́r. 3:6-8) Nígbà tí a bá gbin irúgbìn sórí ilẹ̀ dídára, ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ gbígbéṣẹ́ lè ran ẹni náà lọ́wọ́ láti lóye rẹ̀. (Mát. 13:23) Ó yẹ kí a nípìn-ín ní kíkún àti tòyetòye nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ náà bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. (Héb. 5:12a) Ṣàyọlò àwọn kókó láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 1996, ìpínrọ̀ 25 àti 26. Tẹnu mọ́ sísakun láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ yálà nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí ìwé Ìmọ̀.
Orin 204 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní June 16
Orin 171
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
20 min: “Wàásù Ìhìn Rere Náà Níbi Gbogbo.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Kárí ìpínrọ̀ 16 sí 33. Fi bí a ṣe lè fi àwọn àbá náà sílò ládùúgbò hàn. Ṣe àṣefihàn ìpínrọ̀ 22 sí 24. Ka ìpínrọ̀ 33.
15 min: Dídá Ìsìn Rẹ Mọ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Òtítọ́ Tàbí Èké. Alàgbà kan mú ipò iwájú nínú ìjíròrò kan tí a gbé karí Jí! December 22, 1989, ojú ìwé 26, pẹ̀lú akéde dídáńgájíá méjì tàbí mẹ́ta. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó hàn gbangba pé wọ́n jẹ́ olótìítọ́ inú ni a ń dé ọ̀dọ̀ wọn léraléra. Ṣùgbọ́n, wọn kò tí ì tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Jíròrò bí a ṣe lè lo àwọn kókó tí ó wà nínú àpilẹ̀kọ inú Jí! yìí láti mú kí wọ́n mọ àìní náà láti gbégbèésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye. Tọ́ka sí àwọn kókó pàtàkì nínú ìwé Ìmọ̀, Orí 5: “Ìjọsìn Ta Ni Ọlọrun Tẹ́wọ́gbà?” Ka ìpínrọ̀ 20. A lè ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láti fún wọn níṣìírí lọ́nà onínúure àti onímẹ̀tọ́mọ̀wà láti tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ àti láti máa wá sí àwọn ìpàdé.
Orin 201 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní June 23
Orin 193
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Sọ ètò tí a ṣe fún iṣẹ́ ìsìn pápá fún òpin ọ̀sẹ̀. Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run.
15 min: Kí Ni Wọ́n Ń sọ Nípa Wa? Ọ̀rọ̀ àsọyé tí a gbé karí ìsọfúnni tí ó wà nínú ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index 1986-1995, ojú ìwé 341 sí 343. Yan “Statements by Others” (Ọ̀rọ̀ Tí Àwọn Ẹlòmíràn Sọ) tí ó ta yọ lọ́lá nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—ìwà wa àti iṣẹ́ wa. Fi hàn bí a ti ṣe wú àwọn ẹlòmíràn lórí lọ́nà rere nípa ohun tí wọ́n rí lára wa. Ṣàlàyé ìdí tí ó fi yẹ kí èyí sún wa nígbà gbogbo láti máa hùwà lọ́nà títọ́ kí a sì dúró gangan nínú iṣẹ́ wa. Tọ́ka sí bí a ṣe lè lo irú àwọn gbólóhùn dáradára bẹ́ẹ̀ nígbà tí a bá ń bá àwọn ojúlùmọ̀ àti àwọn olùfìfẹ́hàn tí wọ́n ń fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa wa sọ̀rọ̀.
20 min: “Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Láti Wàásù.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi ìtọ́sọ́nà tí ó wà nínú ìwé Iṣetojọ, ojú ìwé 99 àti 100 kún un, lábẹ́ ìsọ̀rí orí ọ̀rọ̀ náà, “Riran Awọn Ọ̀dọ́ Eniyan Lọwọ.”
Orin 211 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní June 30
Orin 197
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo àwùjọ létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá fún oṣù June sílẹ̀.
20 min: “Ẹ̀yin Èwe—Kí Ni Àwọn Góńgó Yín Nípa Tẹ̀mí?” Bàbá méjì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pa pọ̀. Wọ́n ṣàyẹ̀wò bí wọ́n ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti mọ ìdí tí ó fi pọn dandan láti gbé àwọn góńgó ìṣàkóso Ọlọ́run kalẹ̀, tí yóò mú àwọn ìbùkún tẹ̀mí wá, dípò lílépa àwọn ire ohun ìní ti ara.—Tún wo ìwé Iṣetojọ, ojú ìwé 116 sí 118.
15 min: Mímúrasílẹ̀ fún Ìfilọni Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ti Oṣù July. Yan ìwé pẹlẹbẹ kan tàbí méjì tí ó ti ru ọkàn ìfẹ́ sókè ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín, kí o sì ṣàtúnyẹ̀wò díẹ̀ nínú àwọn kókó títayọ lọ́lá nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Dábàá àwọn ọ̀nà tí a lè gbà mú ìwọ̀nyí wọnú ìgbékalẹ̀. Rán gbogbo àwùjọ létí láti ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìwé tí wọ́n bá fi sódè, kí wọ́n sì pa dà láti mú ọkàn ìfẹ́ tí a fi hàn dàgbà.
Orin 109 àti àdúrà ìparí.