O Lè Jẹ́rìí Láìjẹ́-bí-Àṣà!
1. (a) Kí là ń pè ní ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà? (b) Ẹni mélòó nínú àwa tá a wà nípàdé yìí ló tipasẹ̀ ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà mọ òtítọ́ fún ìgbà àkọ́kọ́?
1 Ẹni mélòó nínú ìjọ yín ló tipasẹ̀ ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà mọ òtítọ́ fún ìgbà àkọ́kọ́? Iye àwọn tó o máa rí lè yà ẹ́ lẹ́nu. Lára ohun tó túmọ̀ sí láti ṣe ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà ni pé, ká sọ ìhìn rere náà fún àwọn tá à ń bá pàdé nínú ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́, irú bí ìgbà tá a bá ń rìnrìn àjò, tá a bá ń bẹ àwọn mọ̀lẹ́bí wa tàbí àwọn aládùúgbò wa wò, tá a bá wà lọ́jà, ní iléèwé, ní ibiṣẹ́ àti láwọn ibòmíì. Nígbà tá a ṣèwádìí lẹ́nu àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tí wọ́n ti ṣèrìbọmi, tí iye wọn lé ní igba [200], àwọn tó tipasẹ̀ ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà mọ òtítọ́ fún ìgbà àkọ́kọ́ ju ọgọ́rin [80] lọ! Èyí fi hàn pé ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà wúlò gan-an ni.
2. Àpẹẹrẹ wo la rí nínú Ìwé Mímọ́ nípa ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà?
2 Àwọn tó wàásù ní ọ̀rúndún kìíní sábà máa ń jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà. Bí àpẹẹrẹ, Jésù jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà fún obìnrin kan tó wá fa omi látinú kànga Jékọ́bù. (Jòh. 4:6-26) Fílípì bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ìjòyè ara Etiópíà tó ń ka ìwé Aísáyà nípa bíbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ní ti gidi, ìwọ ha mọ ohun tí o ń kà bí?” (Ìṣe 8:26-38) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n ní ìlú Fílípì, ó wàásù fún onítúbú kan. (Ìṣe 16:23-34) Lẹ́yìn náà, nígbà tí wọ́n sé Pọ́ọ̀lù mọ́lé, ó máa ń “fi inú rere gba gbogbo àwọn tí wọ́n wọlé wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ní wíwàásù ìjọba Ọlọ́run fún wọn àti kíkọ́ni ní àwọn nǹkan nípa Jésù Kristi Olúwa.” (Ìṣe 28:30, 31) Ìwọ pẹ̀lú lè jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà, kódà bí ojú bá ń tì ẹ́. Báwo lo ṣe lè ṣe é?
3. Kí ló lè jẹ́ ká borí ìtìjú?
3 Bó O Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀: Ọ̀pọ̀ nínú wa ló máa ń ṣòro fún láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹni tá ò mọ̀ rí. Kódà, ó lè ṣòro fún wa láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nípa òtítọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn tá a ti jọ mọra dáadáa tẹ́lẹ̀. Àmọ́, ó máa wù wá láti sọ̀rọ̀, tá a bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn ohun rere tí Jèhófà ti ṣe fún wa, òtítọ́ tó ṣeyebíye tó fi síkàáwọ́ wa àti ipò tó ṣeni láàánú tí àwọn èèyàn wà nínú ayé. (Jónà 4:11; Sm. 40:5; Mát. 13:52) Yàtọ̀ sí èyí, a lè gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ ká lè “máyàle.” (1 Tẹs. 2:2) Akẹ́kọ̀ọ́ kan ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì sọ pé: “Mo ti kíyè sí lọ́pọ̀ ìgbà pé àdúrà máa ń ràn mí lọ́wọ́ nígbàkigbà tó bá ṣòro fún mi láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀.” Tó o bá ń lọ́ra láti sọ̀rọ̀, gba àdúrà ṣókí ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́.—Neh. 2:4.
4. Kí la lè kọ́kọ́ fi ṣe àfojúsùn wa, kí sì nìdí?
4 Tá a bá fiyè sí ìtúmọ̀ ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà, a ó rí i pé kò nílò pé ká bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò náà pẹ̀lú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí á mú kó dà bíi pé a wà lóde ẹ̀rí tàbí pé ká bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan. Ó máa ṣèrànwọ́ gan-an tá a bá fi ṣe àfojúsùn wa pé a kàn fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò láìjẹ́ pé a fẹ́ wàásù fún ẹni tá à ń bá sọ̀rọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn akéde ló sọ pé ṣíṣe èyí máa ń jẹ́ kí ọkàn àwọn balẹ̀ láti sọ̀rọ̀ nípa ìhìn rere lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Bí ẹni tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀ náà kò bá nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ rẹ, má fipá mú un. Fi ẹni náà sílẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.
5. Kí ló ran arábìnrin kan tó máa ń tijú lọ́wọ́ láti jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà?
5 Bí arábìnrin kan tó máa ń tijú bá lọ ra nǹkan lọ́jà, ó máa ń kọ́kọ́ jẹ́ kí ojú òun ṣe mẹ́rin pẹ̀lú ẹnì kan, á sì rẹ́rìn-ín músẹ́ sí ẹni náà. Bí ẹni yẹn bá rẹ́rìn-ín pa dà, á sọ ọ̀rọ̀ kan ní ṣókí. Bí ẹni náà bá fèsì tó dáa, ìyẹn á fi í lọ́kàn balẹ̀ láti máa bá ìjíròrò náà lọ. Á wá fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ẹni yẹn bá sọ dáadáa, kó bàa lè fòye mọ ohun tí ẹni náà máa nífẹ̀ẹ́ sí nípa ìhìn rere. Arábìnrin yìí ti tipa báyìí fi ọ̀pọ̀ ìwé sóde, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan.
6. Báwo la ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà?
6 Bó O Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò: Kí la lè sọ láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò? Nígbà tí Jésù fẹ́ bá obìnrin tó pàdé lẹ́bàá kàngan sọ̀rọ̀, ohun tó fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò náà ni pé ó ní kí obìnrin yẹn fún òun lómi mu. (Jòh. 4:7) Èyí fi hàn pé a lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nípa fífi ọ̀yàyà kí wọn tàbí ká bi wọ́n ní ìbéèrè. Bẹ́ ẹ bá ṣe ń bá ìjíròrò yín lọ, o lè wá ọ̀nà láti fa ọ̀rọ̀ kan yọ látinú Ìwé Mímọ́, o sì lè tipa bẹ́ẹ̀ fún irúgbìn òtítọ́. (Oníw. 11:6) Ohun tí àwọn kan ti ṣe tó sì ti sèso ni pé, wọ́n sọ ọ̀rọ̀ kan tó máa fa àwọn ẹlòmíì lọ́kàn mọ́ra, tí á sì mú kí wọ́n fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i débi pé wọ́n á béèrè ìbéèrè. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó o bá ń dúró láti rí dókítà, o lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò tó o bá kàn sọ pé, “Inú mi á dùn gan-an tí mi ò bá ṣàìsàn mọ́.”
7. Tá a bá ń kíyè sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, báwo ni ìyẹn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà?
7 Tá a bá ń kíyè sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ìyẹn pẹ̀lú lè ràn wá lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Tá a bá rí òbí kan tí àwọn ọmọ rẹ̀ níwà ọmọlúwàbí, a lè gbóríyìn fún un, ká wá bi í pé, “Ọ̀nà wo lẹ gbé e gbà tẹ́ ẹ fi lè tọ́ àwọn ọmọ yín yanjú?” Arábìnrin kan máa ń fiyè sí ọ̀rọ̀ tí àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ń sọ, ó sì máa ń bá wọn jíròrò ìsọfúnni tó bá ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí mu. Nígbà tó gbọ́ pé obìnrin kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ fẹ́ ṣègbéyàwó, ó fún un ní ìwé ìròyìn Jí! tó sọ̀rọ̀ nípa béèyàn ṣe lè múra ayẹyẹ ìgbéyàwó sílẹ̀. Èyí mú kí wọ́n jíròrò síwájú sí i látinú Bíbélì.
8. Báwo la ṣe lè fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò?
8 Ọ̀nà míì tá a tún lè gbà bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò ni pé ká máa ka àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa níbi tí àwọn ẹlòmíì ti lè rí wa. Arákùnrin kan máa ń ṣí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! síbi tí àkòrí tó fani lọ́kàn mọ́ra bá wà, á sì máa fohùn jẹ́jẹ́ kà á. Tó bá kíyè sí pé ẹnì kan tó wà nítòsí ń wo ìwé ìròyìn náà, ó lè bi ẹni yẹn ní ìbéèrè tàbí kó sọ ọ̀rọ̀ kan ní ṣókí. Èyí sábà máa ń fún un láǹfààní láti jíròrò pẹ̀lú ẹni náà, kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́rìí fún un. Tó o bá kàn fi ọ̀kan lára àwọn ìwé wa sí ibi tí àwọn ẹlòmíì ti lè rí i, èyí lè mú kí àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn ọmọ kíláàsì rẹ fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè nípa ìwé náà.
9, 10. (a) Báwo la ṣe lè wá ọ̀nà láti jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà? (b) Ọ̀nà wo lo ti gbà jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà?
9 Wá Ọ̀nà Láti Ṣe É: Torí bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe gba kánjúkánjú, a ò gbọ́dọ̀ ronú pé tó bá wulẹ̀ ṣeé ṣe la ó máa jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa wá ọ̀nà tá a lè gbà jẹ́rìí fáwọn ẹlòmíì nínú ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́. Ronú nípa àwọn èèyàn tó ṣeé ṣe kó o bá pàdé àti bó o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú wọn lọ́nà tó máa tù wọ́n lára. Máa mú Bíbélì àtàwọn ìwé tó o lè fún àwọn èèyàn tó bá fìfẹ́ hàn dání nígbà gbogbo.—1 Pét. 3:15.
10 Nípa lílo gbogbo àǹfààní tí wọ́n bá ní, ọ̀pọ̀ àkéde ló ti wá onírúurú ọ̀nà tí wọ́n lè gbà jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà. Arábìnrin kan tó ń gbé ilé kan tó ní àwọn ẹ̀ṣọ́ lẹ́nu géètì máa ń to àwòrán ẹlẹ́wà kéékèèké pọ̀ láti fi bí ìṣẹ̀dá ṣe lẹ́wà tó hàn. Bí àwọn èèyàn bá wá wo àwòrán náà, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe rẹwà tó, ó máa ń lo àǹfààní yẹn láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú wọn, ó sì máa ń sọ fún wọn nípa “ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun kan” tí Ọlọ́run ṣèlérí rẹ̀ nínú Bíbélì. (Ìṣí. 21:1-4) Ǹjẹ́ o lè ronú nípa àwọn ọ̀nà tó o lè gbà jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà?
11. Kí la lè ṣe láti koná mọ́ ìfẹ́ táwọn tá a jẹ́rìí fún láìjẹ́-bí-àṣà fi hàn?
11 Koná Mọ́ Ìfẹ́ Tí Wọ́n Fi Hàn: Bó o bá rí ẹni tó fetí sílẹ̀, gbìyànjú láti koná mọ́ ìfẹ́ tó fi hàn. O lè sọ fún un pé: “Mo gbádùn ìjíròrò wa yìí gan-an. Ibo ni mo ti lè rí ẹ, ká lè tún jọ sọ̀rọ̀ nígbà míì?” Àwọn akéde míì máa ń fún ẹni tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ ní àdírẹ́sì àti nọ́ńbà tẹlifóònù wọn, wọ́n á wá sọ pé: “Mo gbádùn ọ̀rọ̀ tá a jọ sọ yìí gan-an. Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ohun tá a jọ jíròrò yìí, o lè kàn sí mi ní àdírẹ́sì tàbí lórí nọ́ńbà fóònù yìí.” Bí o kò bá ní lè wá ẹni náà lọ fúnra rẹ, tètè kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sínú fóòmù padà-lọ-ṣèbẹ̀wò, ìyẹn Please Follow Up (S-43), kó o sì fún akọ̀wé ìjọ́ rẹ, kí ìjọ tó sún mọ́ ibi tẹni náà ń gbé lè ṣètò láti lọ sọ́dọ̀ ẹni náà.
12. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣàkọsílẹ̀ àkókò tá a bá fi jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà ká sì ròyìn rẹ̀? (b) Àwọn àbájáde wo la ti rí látinú ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà? (Wo àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ìjẹ́rìí Àìjẹ́-bí-Àṣà Máa Ń Yọrí sí Rere!”)
12 Ó yẹ ká máa ròyìn àkókò tá a bá fi jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà. Torí náà, gbìyànjú láti máa ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀, bí kò bá tiẹ̀ ju ìṣẹ́jú mélòó kan lọ lójúmọ́. Rò ó wò ná, bí akéde kọ̀ọ̀kan bá ń fi ìṣẹ́jú márùn-ún lójúmọ́ jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà, àròpọ̀ wákàtí tí gbogbo akéde á lò ní oṣù kan máa ju mílíọ̀nù mẹ́tàdínlógún lọ!
13. Kí nìdí tó fi yẹ kó máa wù wá láti jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà?
13 A ní ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ láti máa jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà, ìyẹn sì ni ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò wa. (Mát. 22:37-39) Ìmọrírì àtọkànwá tá a ní fún àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe fún wa máa ń mú ká fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa “ògo ọlá ńlá ipò ọba rẹ̀.” (Sm. 145:7, 10-12) Ojúlówó ìfẹ́ tá a ní fún àwọn aládùúgbò wa máa ń mú ká lo gbogbo àǹfààní tó bá yọjú láti sọ ìhìn rere náà fún wọn ní báyìí tí àkókò ṣì wà. (Róòmù 10:13, 14) Tá a bá ronú nípa rẹ̀ tá a sì múra sílẹ̀, gbogbo wa lè jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà, èyí á jẹ́ ká nírú ayọ̀ téèyàn máa ń ní tó bá sọ òtítọ́ Bíbélì fún ẹni tó fẹ́ mọ òtítọ́.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí tó wà ní ojú ìwé 2]
Ó máa ṣèrànwọ́ tó o bá fi ṣe àfojúsùn rẹ láti máa bá àwọn tó ò ń bá pàdé sọ̀rọ̀
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí tó wà ní ojú ìwé 3]
Nípa lílo gbogbo àǹfààní tí wọ́n bá ní, ọ̀pọ̀ àkéde ló ti wá onírúurú ọ̀nà tí wọ́n lè gbà jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Bó O Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò
◼ Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò
◼ Àwọn tó bá fara balẹ̀ tó o sì rí i pé wọ́n máa fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ni kó o bá sọ̀rọ̀
◼ Jẹ́ kí ojú yín ṣe mẹ́rin, rẹ́rìn-ín músẹ́, kó o wá sọ ọ̀rọ̀ kan tí ẹ̀yin méjèèjì jọ nífẹ̀ẹ́ sí
◼ Máa fetí sílẹ̀ dáadáa
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Ìjẹ́rìí Àìjẹ́-bí-Àṣà Máa Ń Yọrí sí Rere!
• Nígbà tí àwọn tó ń tún ọkọ̀ ṣe ń bá arákùnrin kan tún ọkọ̀ rẹ̀ ṣe, ó jẹ́rìí fún àwọn tó wà nítòsí rẹ̀, ó sì fún wọn ní ìwé ìkésíni láti wá gbọ́ àsọyé fún gbogbo ènìyàn. Ní àpéjọ àgbègbè tí wọ́n ṣe ní ọdún kan lẹ́yìn ìgbà náà, arákùnrin kan fi ọ̀yàyà kí i, ṣùgbọ́n kò dá onítọ̀hún mọ̀. Arákùnrin náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó fún ní ìwé ìkésíni ní ibi tó ti lọ tún ọkọ̀ ṣe ní ọdún kan sẹ́yìn! Ọkùnrin yẹn lọ gbọ́ àsọyé náà, ó ní kí wọ́n máa wá kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní báyìí òun àti ìyàwó rẹ̀ ti ṣèrìbọmi.
• Nígbà tí ọkùnrin kan tó ń polówó ọjà fún ilé iṣẹ́ abánigbófò kan wá sọ́dọ̀ arábìnrin kan, arábìnrin náà lo àǹfààní yẹn láti wàásù fún un. Arábìnrin náà béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin yẹn bóyá ó máa fẹ́ kí ẹnì kan fi dá a lójú pé ó máa ní ìlera tó jíire, ayọ̀ àti ìyè àìnípẹ̀kun. Ó dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, ó sì béèrè lọ́wọ́ arábìnrin náà pé ètò ìbánigbófò wo ló ní lọ́kàn? Arábìnrin náà fi ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nínú Bíbélì hàn án, ó sì fún un ní ọ̀kan lára àwọn ìwé wa, ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan péré ni ọkùnrin yẹn fi ka ìwé náà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọkùnrin náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí ìpàdé, ó sì ṣèrìbọmi.
• Arákùnrin kan tó jẹ́ afọ́jú, tó sì jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún [100] ọdún ń gbé ní ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó, ó sábà máa ń sọ pé, “A nílò Ìjọba náà.” Èyí máa ń mú kí àwọn nọ́ọ̀sì àtàwọn tó wá gbàtọ́jú máa bi í ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè, ó sì máa ń ṣàlàyé ohun tí Ìjọba náà túmọ̀ sí. Ọ̀kan lára àwọn obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìtọ́jú náà ní kí arákùnrin náà sọ ohun tó fẹ́ ṣe nínú Párádísè fún òun. Arákùnrin náà sọ pé: “Màá fojú mi ríran, màá sì fẹsẹ̀ mi rìn, màá wá dáná sun kẹ̀kẹ́ arọ tí mò ń lò yìí.” Torí pé arákùnrin náà jẹ́ afọ́jú, ó máa ń ní kí obìnrin yìí máa ka àwọn ìwé ìròyìn náà fún òun. Nígbà tí ọmọ arákùnrin náà wá wo bàbá rẹ̀, obìnrin yẹn béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá òun lè mú àwọn ìwé ìròyìn náà lọ sílé. Ọ̀kan lára àwọn nọ́ọ̀sì yẹn sọ fún ọmọ arákùnrin náà pé: “Ọ̀rọ̀ tó gbòde níbí yìí báyìí ni: ‘A nílò Ìjọba náà.’”