Ẹ Jẹ́ Aláápọn Nínú “Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná”
1, 2. Kí ló wú ọ lórí nípa irú ojú tí Pọ́ọ̀lù fi wo wíwàásù ìhìn rere náà, báwo la sì ṣe lè fara wé àpẹẹrẹ rẹ̀ ní ti “jíjẹ́rìí kúnnákúnná”?
1 Gẹ́gẹ́ bíi Jésù àti ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ olóòótọ́ ìgbàanì, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ oníwàásù ìhìnrere tí ó nítara, ó ‘jẹ́rìí kúnnákúnná’ láìka ipòkípò tó wà sí. Àní, nígbà tí wọ́n há a mọ́nú ilé pàápàá, ó “fi inú rere gba gbogbo àwọn tí wọ́n wọlé wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ní wíwàásù ìjọba Ọlọ́run fún wọn àti kíkọ́ni ní àwọn nǹkan nípa Jésù Kristi Olúwa pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ńláǹlà.”—Ìṣe 28:16-31.
2 Àwa pẹ̀lú lè jẹ́ aláápọn nínú “jíjẹ́rìí kúnnákúnná” nígbà gbogbo. Èyí kan jíjẹ́rìí fún àwọn èèyàn tá a bá pàdé nígbà tí a bá rìnrìn àjò.—Ìṣe 28:23; Sm. 145:10-13.
3. Báwo la ṣe lè yẹra fún sísọ ìjẹ́rìí aláìjẹ́-bí-àṣà di ohun tá ò rò tẹ́lẹ̀?
3 Kí Ni Ìjẹ́rìí Aláìjẹ́-bí-Àṣà? Ìjẹ́rìí aláìjẹ́-bí-àṣà kì í ṣe ìjẹ́rìí tá à ń ṣèèṣì ṣe o tàbí tá à ń ṣe láìsí pé a ti ní in lọ́kàn ṣáájú, bí ẹni pé a ò wéwèé rẹ̀ tẹ́lẹ̀ tàbí pé kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Ó dájú pé àpèjúwe yìí kò bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa mu rárá. Fífi ògo fún Ọlọ́run nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ṣe pàtàkì fún wa gẹ́gẹ́ bó ti rí nínú ọ̀ràn ti Pọ́ọ̀lù, ó sì yẹ ká ní in lọ́kàn láti máa wàásù níbikíbi tó bá ti yẹ nígbà ìrìn àjò. Àmọ́ ṣá o, a lè ṣàpèjúwe ọ̀nà tá a gbà ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn gẹ́gẹ́ bí aláìjẹ́ bí àṣà—ìyẹn ni pé, à ń fara balẹ̀ ṣe é, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ sọ́rẹ̀ẹ́. Irú ọ̀nà yìí lè mú ìyọrísí rere wá.
4. Kí ló ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láti jẹ́rìí nínú ilé tó háyà?
4 Múra Sílẹ̀ Láti Jẹ́rìí: Nígbà tí wọ́n há Pọ́ọ̀lù mọ́nú ilé ní Róòmù, ó wá ọ̀nà tí yóò máa gbà jẹ́rìí. Látinú ilé tó háyà, ó ránṣẹ́ sáwọn aṣáájú Júù pé kí wọ́n wá sínú ilé òun. (Ìṣe 28:17) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọ Kristẹni kan wà ní Róòmù, Pọ́ọ̀lù rí i pé ìwọ̀nba ìsọfúnni tààràtà díẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ Kristẹni ni àwùjọ àwọn Júù tó wà ní ìlú yẹn ní. (Ìṣe 28:22; Róòmù 1:7) Kò lọ́ tìkọ̀ láti ‘jẹ́rìí kúnnákúnná’ nípa Jésù Kristi àti Ìjọba Ọlọ́run.
5, 6. Àwọn àǹfààní wo ló lè ṣí sílẹ̀ fún wa láti jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà, kí sì ni àwọn ìmúrasílẹ̀ tá a lè ṣe láti lè jẹ́rìí lọ́nà tó múná dóko?
5 Ronú ṣáájú nípa gbogbo àwọn tó o lè bá pàdé nígbà ìrìn àjò rẹ, tó jẹ́ pé ìwọ̀nba bíńtín lohun tí wọ́n mọ̀ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n tiẹ̀ lè má mọ̀ pé à ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn. Wà lójúfò fún àwọn àǹfààní tó lè ṣí sílẹ̀ fún ọ láti jẹ́rìí fáwọn tó o lè bá pàdé nígbà tó o bá ń rìnrìn àjò, tó o bá dúró sinmi lọ́nà, tó o bá ń ra epo sínú ọkọ̀, tó o bá lọ rajà, tó o bá dé sí hòtẹ́ẹ̀lì, tó o bá ń jẹun nílé àrójẹ, tó o bá lọ wọ ọkọ̀ èrò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Pinnu ohun tí wàá sọ ṣáájú láti lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò kí o sì jẹ́rìí ní ṣókí. Bóyá kí ọjọ́ náà tóó dé, o lè ṣe ìdánrawò nípa jíjẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà fún àwọn aládùúgbò rẹ, ìbátan rẹ, òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ àtàwọn ojúlùmọ̀ rẹ.
6 Wàá nílò àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ nígbà tó o bá fẹ́ jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà. Irú àwọn ìwé wo? O lè lo ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? Sọ̀rọ̀ lórí ìpínrọ̀ márùn-ún tó ṣáájú, níbi tá a ti mẹ́nu kan onírúurú ìdí tó fi yẹ ká máa ka Bíbélì. Fi àpótí tó wà lẹ́yìn ìwé náà táwọn èèyàn fi ń béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé han ẹni náà. Nígbà tó o bá bá ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ pàdé, fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọ̀ ọ́. Pẹ̀lú ìrètí pé o lè bá àwọn èèyàn tí ń sọ èdè mìíràn pàdé, mú ìwé pẹlẹbẹ náà Good News for All Nations dání. Ojú ìwé kejì ṣàlàyé bí a ṣe lè lo ìwé náà láti wàásù. Tó bá jẹ́ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tàbí bọ́ọ̀sì lo fẹ́ fi rìnrìn àjò, èyí lè mú kó ṣeé ṣe fún ọ láti kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀ dání nítorí àwọn tó bá fìfẹ́ hàn nínú ìhìn Ìjọba náà.
7, 8. Ìkìlọ̀ wo nípa ìrísí wa àti ìwà wa nígbà tí a bá ń rìnrìn àjò àti lákòókò fàájì ló yẹ ká fiyè sí?
7 Kíyè sí Ìrísí àti Ìwà Rẹ: A ní láti rí i dájú pé ìwà wa títí kan ọ̀nà tá à ń gbà wọṣọ, tí a sì ń gbà múra kò ní mú káwọn èèyàn máa ní èrò tó lòdì nípa wa tàbí kó wá mú wọn máa ‘sọ̀rọ̀ òdì sí’ ètò àjọ Jèhófà. (Ìṣe 28:22) Kì í ṣe kìkì ìgbà tá a bá ń rìnrìn àjò nìkan ló yẹ ká fi kókó yìí sọ́kàn o, àmọ́ lákòókò fàájì pẹ̀lú. Ilé Ìṣọ́ August 1, 2002, ojú ìwé 18, ìpínrọ̀ 14, kìlọ̀ pé: “Kò yẹ ká múra lọ́nà ṣekárími, tàbí bí ewèlè, tàbí ká múra lọ́nà tí ń ru ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sókè, tàbí ká wọ aṣọ tí ń fi ibi kọ́lọ́fín ara hàn, tàbí ká múra bíi sóòyòyò. Láfikún sí i, ó yẹ ká máa múra lọ́nà tí ‘ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run’ hàn. Ǹjẹ́ ìyẹn ò gbèrò? Kì í ṣọ̀ràn mímúra lọ́nà tó bójú mu nígbà tá a bá ń bọ̀ nípàdé ìjọ [tàbí nígbà tá a bá ń lọ sí àwọn àpéjọ wa mìíràn] nìkan ni, ká sì wá di aláìbìkítà nípa ìmúra wa láwọn ìgbà mí ì. Ó yẹ kí ìrísí wa máa fi hàn pé olùfọkànsìn àti ẹni iyì ni wá nígbà gbogbo. Kristẹni àti òjíṣẹ́ sáà ni wá ní gbogbo wákàtí ọjọ́.”—1 Tím. 2:9, 10.
8 Ó yẹ ká máa múra níwọ̀ntúnwọ̀nsì àti lọ́nà tó ń buyì kúnni. Bí ìrísí wa àti ìwà wa nígbà gbogbo bá ń fi ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run hàn, a ò ní lọ́ tìkọ̀ láti jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà nítorí pé ìrísí wa kù díẹ̀ káàtó.—1 Pét. 3:15.
9. Àṣeyọrí wo ni Pọ́ọ̀lù ní nínú iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ ní Róòmù?
9 Ìjẹ́rìí Aláìjẹ́-bí-Àṣà Ń Méso Jáde: Ipa tí Pọ́ọ̀lù sà láti jẹ́rìí láàárín ọdún méjì tó fi wà ní àhámọ́ nínú ilé rẹ̀ ní Róòmù so èso rere. Lúùkù ròyìn pé “àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí gba àwọn ohun tí ó sọ gbọ́.” (Ìṣe 28:24) Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ sọ nípa bí ọ̀nà tí òun gbà ‘jẹ́rìí kúnnákúnná’ ṣe múná dóko tó nígbà tó kọ̀wé pé: “Àwọn àlámọ̀rí mi ti yọrí sí ìlọsíwájú ìhìn rere dípò kí ó jẹ́ òdì-kejì, tí ó fi jẹ́ pé àwọn ìdè mi ti di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi láàárín gbogbo Ẹ̀ṣọ́ Ọba àti gbogbo àwọn yòókù; púpọ̀ jù lọ lára àwọn ará nínú Olúwa, tí wọ́n ní ìgbọ́kànlé nítorí àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n mi, sì túbọ̀ ń fi ìgboyà púpọ̀ sí i hàn láti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láìbẹ̀rù.”—Fílí. 1:12-14.
10. Àṣeyọrí wo ni tọkọtaya kan ṣe nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí lọ́dún tó kọjá?
10 Lọ́dún tó kọjá, lẹ́yìn ọjọ́ àpéjọ àgbègbè kan, tọkọtaya kan wàásù láìjẹ́ bí àṣà fún obìnrin agbáwo oúnjẹ nílé àrójẹ kan, ẹni tó bi wọ́n léèrè ohun tí káàdì àpéjọ tí wọ́n lẹ̀ máyà wà fún, ìwàásù náà sì so èso rere. Wọ́n sọ fún un nípa ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àgbègbè náà, wọ́n sì tún jẹ́ kó mọ ìrètí tí Bíbélì fúnni nípa ọjọ́ ọ̀la aráyé. Wọ́n fún obìnrin yìí ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì?, wọ́n sì ṣàlàyé ètò tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé fún un. Obìnrin náà sọ pé òun fẹ́ kí ẹnì kan wá máa bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́, ó kọ orúkọ àti àdírẹ́sì rẹ̀ sẹ́yìn ìwé àṣàrò kúkúrú náà, ó wá ní kí tọkọtaya náà ṣètò yòókù. Àṣeyọrí wo lo lè ṣe nípa fífi aápọn ‘jẹ́rìí kúnnákúnná’?
11. Àwọn ànímọ́ wo ló yẹ ká mú dàgbà kí a bàa lè mú ìhìn rere náà lọ jìnnà nípa “jíjẹ́rìí kúnnákúnná”?
11 Mú Ìhìn Rere Náà Lọ Jìnnà: Fojú inú wo bí ayọ̀ Pọ́ọ̀lù á ṣe pọ̀ tó nígbà tó gbọ́ pé àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ń ṣàfarawé àpẹẹrẹ ìtara tó ní! Ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa láti mú ìhìn rere náà lọ jìnnà nípa wíwàásù láìjẹ́ bí àṣà nípa ìgbàgbọ́ wa èyí tá a gbé ka Bíbélì, ní gbogbo àkókò táǹfààní rẹ̀ bá ṣí sílẹ̀.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Tá A Nílò fún Ìjẹ́rìí Aláìjẹ́-bí-Àṣà
■ Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? (ìwé àṣàrò kúkúrú)
■ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? (ìwé pẹlẹbẹ)
■ Good News for All Nations (ìwé pẹlẹbẹ)
■ Àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn