ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/09 ojú ìwé 1
  • Ṣó O Ti Múra Sílẹ̀ Láti Jẹ́rìí Láìjẹ́-bí-Àṣà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣó O Ti Múra Sílẹ̀ Láti Jẹ́rìí Láìjẹ́-bí-Àṣà?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • O Lè Jẹ́rìí Láìjẹ́-bí-Àṣà!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Ẹ Jẹ́ Aláápọn Nínú “Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Máa Yin Jèhófà Nípa Wíwàásù Lọ́nà Àìjẹ́ bí Àṣà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ni Wá Nígbà Gbogbo
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
km 10/09 ojú ìwé 1

Ṣó O Ti Múra Sílẹ̀ Láti Jẹ́rìí Láìjẹ́-bí-Àṣà?

1. Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà máa ń gbéṣẹ́ gan-an?

1 Ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà máa ń gbéṣẹ́ gan-an ni. Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà tó sèso rere ló wà nínú Bíbélì. (Jòh. 4:7-15) Kí la lè ṣe láti múra sílẹ̀ fún ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà?

2. Báwo ni aṣọ àti ìmúra wa ṣe lè jẹ́ ká túbọ̀ múra tán láti jẹ́rìí?

2 Aṣọ àti Ìmúra: Bá a bá ń rí i dájú pé aṣọ tá a wọ̀ àti ọ̀nà tá a gbà múra bójú mu nígbà gbogbo, èyí á jẹ́ ká lè sọ ohun tá a gbà gbọ́ fáwọn èèyàn ní fàlàlà. (1 Tím. 2:9, 10) Bí àwa fúnra wa bá mọ̀ pé ìmúra wa kò buyì kún Jèhófà, ńṣe la ó máa lọ́ tìkọ̀ láti jẹ́rìí. Àmọ́ tá a bá múra lọ́nà tó dára tí aṣọ wa sì mọ́ nigín-nigín, èyí lè fa àwọn èèyàn mọ́ra kí wọ́n sì fẹ́ gbọ́rọ̀ wa. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan tí ìmúra wọn bójú mu ń rìnrìn àjò, ẹ̀gbẹ́ ọkùnrin kan tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí ni wọ́n jókòó nínú ọkọ̀. Nígbà tí ọkùnrin náà ṣàkíyèsí ìmúra wọn, ó béèrè bóyá Kristẹni ni wọ́n. Èyí yọrí sí ìjíròrò Bíbélì fún wákàtí mẹ́ta gbáko.

3. Nípa títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù, ọ̀nà wo lo ti gbà bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò?

3 Bó O Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò: Nígbà tí Jésù rí obìnrin ará Samáríà kan níbi ìsun omi Jékọ́bù, ó bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò rẹ̀ nípa sísọ pé kí obìnrin yẹn fún òun lómi mu. Àwa náà lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wa nípa sísọ ọ̀rọ̀ ṣókí tàbí ká bi onítọ̀hún ní ìbéèrè kan tí kò ṣòro láti dáhùn. Òótọ́ ni pé nígbà míì a lè máa lọ́ tìkọ̀ láti jẹ́rìí, àmọ́ tá a bá gbára lé ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a lè “máyàle” ká sì bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò.—1 Tẹs. 2:2.

4. Báwo la ṣe lè múra tán láti jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà?

4 Máa Wá Bó O Ṣe Lè Jẹ́rìí Láìjẹ́-bí-Àṣà: Ọ̀pọ̀ akéde ti rí àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè máa gbà jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà. Ronú nípa àwọn ìgbòkègbodò rẹ àti àwọn tó ṣeé ṣe kó o bá pàdé lójoojúmọ́. Máa mú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó bá yẹ àti Bíbélì kékeré dání. Jẹ́ ẹni tó lákìíyèsí, kó o sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn máa jẹ ẹ́ lógún. Tó o bá ń ronú nípa àwọn tó ṣeé ṣe kó o bá pàdé lójoojúmọ́, wàá lè múra tán láti jẹ́rìí lọ́nà tó dára.—Fílí. 1:12-14; 1 Pét. 3:15.

5. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa múra sílẹ̀ láti jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà?

5 Ìdí méjì pàtàkì wà tá a fi ń lo àǹfààní tó bá yọjú láti jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà, ó jẹ́ nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, a sì tún nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. (Mát. 22:37-39) Torí pé iṣẹ́ ìwàásù ti di kánjúkánjú, ńṣe ló yẹ ká máa múra sílẹ̀ láti jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà. Ó yẹ ká múra tán láti lo àǹfààní èyíkéyìí tó bá yọjú láti sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn nígbà tí àkókò ṣì wà láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Róòmù 10:13, 14; 2 Tím. 4:2.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́