Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 19
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 19
Orin 86
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
lv-YR orí 11 ìpínrọ̀ 20 sí 22, àpótí tó wà lójú ìwé 131
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Diutarónómì 7-10
No. 1: Diutarónómì 9:1-14
No. 2: Ìdí Tó Fi Yẹ Kí Á Fẹ́ràn Jésù (lr orí 38)
No. 3: A Lè Bọlá fún Ẹ̀dá Èèyàn, Àmọ́ Ọlọ́run Nìkan La Gbọ́dọ̀ Jọ́sìn (td-YR 22B)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 44
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
15 min: Ìwádìí Máa Ń Jẹ́ Ká Túbọ̀ Ní Òye. Àsọyé tá a gbé ka ìsọfúnni tó wà nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ojú ìwé 33 sí ìsọ̀rí tó wà lójú ìwé 34. Bó o ṣe ń jíròrò àpilẹ̀kọ náà, ṣàlàyé báwọn akéde ṣe lè fún àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níṣìírí nípa fífi hàn wọ́n bí wọ́n ṣe lè ṣèwádìí láti mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára sí i àti bí wọ́n ṣe lè múra sílẹ̀ láti wàásù fáwọn ẹlòmíì. Ṣàṣefihàn bí akéde kan ṣe lè ṣèrànwọ́ fún ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó lè lóye ìjẹ́pàtàkì ṣíṣe ìwádìí.
15 min: “Fífi Fóònù Wàásù Máa Ń Gbéṣẹ́ Gan-an.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní kí akéde méjì ṣàṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n lo ìwé tá a máa lò lóṣù yìí.
Orin 75