Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 12
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 12
Orin 110
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Diutarónómì 4-6
No. 1: Diutarónómì 4:15-28
No. 2: Bí A Ṣe Lè Rántí Jèhófà àti Ọmọ Rẹ̀ (lr orí 37)
No. 3: Ìgbà Wo La Lè Sọ Pé Díẹ̀ Sàn Jù? (Òwe 15:16)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 13
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Bó O Ṣe Lè Máa Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àsọyé tá a gbé ka ìsọfúnni tó wà nínú ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 98, ìpínrọ̀ 1, sí ojú ìwé 99, ìpínrọ̀ 1. Ní káwọn ará sọ̀rọ̀ ṣókí nípa ayọ̀ tí wọ́n ti rí látàrí kíkọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
10 min: Ìwé tá a máa lò lóṣù October. Ṣàṣefihàn méjì. Nínú ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà, kí akéde bi ẹni tó wàásù fún ní ìbéèrè kan tó máa pa dà wá dáhùn nígbà ìpadàbẹ̀wò. Kí àṣefihàn kejì dá lórí bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́. Lẹ́yìn àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, o lè ní káwọn ará sọ ohun tí wọ́n rí kọ́.
10 min: “Ṣó O Ti Múra Sílẹ̀ Láti Jẹ́rìí Láìjẹ́-bí-Àṣà?” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 48