ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/03 ojú ìwé 1
  • Máa Yin Jèhófà Nípa Wíwàásù Lọ́nà Àìjẹ́ bí Àṣà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Yin Jèhófà Nípa Wíwàásù Lọ́nà Àìjẹ́ bí Àṣà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • O Lè Jẹ́rìí Láìjẹ́-bí-Àṣà!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Ṣó O Ti Múra Sílẹ̀ Láti Jẹ́rìí Láìjẹ́-bí-Àṣà?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Ẹ Jẹ́ Aláápọn Nínú “Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ni Wá Nígbà Gbogbo
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 5/03 ojú ìwé 1

Máa Yin Jèhófà Nípa Wíwàásù Lọ́nà Àìjẹ́ bí Àṣà

1 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà adúróṣinṣin máa ń wá àǹfààní tí yóò ṣí sílẹ̀ láti yìn ín lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan. (Sm. 96:2, 3; Héb. 13:15) Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe èyí ní láti máa wàásù lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn olùjọ́sìn Jèhófà lónìí ló ń dúpẹ́ pé àwọn rẹ́ni sọ fún wọn nípa ìhìn Ìjọba náà nípasẹ̀ ìwàásù lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà.

2 Wíwàásù fún ẹnì kan lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà sábà máa ń ṣí àyè sílẹ̀ fáwọn ẹlòmíràn láti gbọ́ ìhìn Ìjọba náà. Bí àpẹẹrẹ, ìjíròrò tí Jésù ní pẹ̀lú obìnrin ará Samáríà lẹ́bàá kànga Jákọ́bù ló mú kí ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere náà. (Jòh. 4:6-30, 39-42) Nígbà tí wọ́n fi Pọ́ọ̀lù àti Sílà sí àhámọ́ ní Fílípì, wọ́n wàásù fún onítúbú náà, gbogbo àwọn aráalé ọkùnrin yìí sì tẹ́wọ́ gba òtítọ́.—Ìṣe 16:25-34.

3 Àǹfààní Láti Wàásù: Àwọn àǹfààní wo ló máa ń ṣí sílẹ̀ fún ọ láti wàásù lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà? Àwọn kan ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n bá lọ sọ́jà, tí wọ́n bá wà nínú ọkọ̀ èrò, tàbí tí wọ́n bá ń dúró de oníṣègùn tó fẹ́ yẹ̀ wọ́n wò. Ó ti ṣeé ṣe fáwọn mìíràn láti jẹ́rìí lákòókò ìsinmi níbi iṣẹ́ tàbí nílé ìwé. Wíwulẹ̀ fi ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde wa tá a gbé ka Bíbélì síbi táwọn èèyàn ti lè rí i lè sún àwọn mìíràn láti béèrè nípa àwọn ohun tá a gbà gbọ́.—1 Pét. 3:15.

4 Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀: Ọmọbìnrin ọlọ́dún méje kan tó máa ń tijú gbọ́ nípàdé pé ó ṣe pàtàkì gan-an fún gbogbo wa láti wàásù. Nítorí náà, nígbà tí òun àti ìyá rẹ̀ fẹ́ lọ ra nǹkan nílé ìtajà, ó fi ìwé pẹlẹbẹ méjì sínú àpò rẹ̀. Nígbà tí ọwọ́ ìyá rẹ̀ ṣì dí nídìí káńtà, ọmọbìnrin yìí fi ìwé pẹlẹbẹ kan lọ obìnrin kan tó tẹ́wọ́ gbà á tìfẹ́tìfẹ́. Nígbà tí wọ́n béèrè ohun tó mú kó ní ìgboyà láti fìwé lọ obìnrin náà, ọmọbìnrin onítìjú yìí fèsì pé: “Ńṣe ni mo kàn sọ nínú ọkàn mi pé, ọmọ ó yá, gbéra ńlẹ̀! Bí mo ṣe lọ bá a nìyẹn!”

5 Láti wàásù lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà, gbogbo wa la nílò irú ẹ̀mí ìmúratán tí ọmọbìnrin náà ní. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti nírú ẹ̀mí yìí? Gbàdúrà fún ìgboyà láti lè lanu sọ̀rọ̀. (1 Tẹs. 2:2) Múra ìbéèrè tàbí ọ̀rọ̀ kan táwọn èèyàn á fẹ́ gbọ́ nípa rẹ̀ sílẹ̀ tó o lè lò láti fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Lẹ́yìn náà kí o wá ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà yóò bù kún ìsapá rẹ̀.—Lúùkù 12:11, 12.

6 Wíwàásù lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà fáwọn èèyàn tí à ń bá pàdé lójoojúmọ́ ń fi ìyìn fún Jèhófà, ó sì ń mú wa láyọ̀. Ó lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí tọ ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́