ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/03 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 12
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 19
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 26
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 2
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 5/03 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 12

Orin 1

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán gbogbo àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti ìlàjì oṣù May sílẹ̀. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ May 15 àti Jí! June 8 lọni. Lo àbá àkọ́kọ́ tó wà ní ojú ìwé 8 láti fi Jí! June 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí a fi àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì náà lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹyọ kan ṣoṣo la ó sọ̀rọ̀ lé lórí. Sọ fún onílé nípa ètò ọrẹ ṣíṣe.

20 min: Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Láti Tẹ̀ Síwájú. Àsọyé tí a óò fi jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ojú ìwé 9 sí 12 àti ojú ìwé 21 sí 38. Rọ àwọn òbí láti lò lára àwọn ìsọfúnni wọ̀nyí nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn, kí wọ́n ní in lọ́kàn láti dá àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ láti tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Pe àfiyèsí sí àwọn kókó pàtó kan tá a lè lò láti ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti kọ́ iṣẹ́ tó máa wúlò.

15 min: “A Fi Ìhìn Rere Náà Síkàáwọ́ Wa.”a Ṣètò ṣáájú fún akéde kan tàbí méjì láti ṣàlàyé ní ṣókí bó ṣe ṣeé ṣe fún wọn láti ṣètò ọ̀ràn ara wọn láti túbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù.

Orin 46 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 19

Orin 62

10 min:  Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.

15 min: “Máa Yin Jèhófà Nípa Wíwàásù Lọ́nà Àìjẹ́ bí Àṣà.” Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, béèrè lọ́wọ́ àwùjọ nípa ohun tí a lè sọ láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò Bíbélì nínú díẹ̀ lára àwọn ipò tó tẹ̀ lé e yìí: (1) nígbà tá a bá lọ sọ́jà, (2) nígbà tá a bá wà nínú ọkọ̀ èrò, (3) bí aládùúgbò wa kan bá ń ṣiṣẹ́ láyìíká ilé rẹ̀, (4) bí a bá wà pẹ̀lú òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa kan níbi iṣẹ́, (5) bí a bá wà pẹ̀lú ọmọ kíláàsì wa ní ilé ẹ̀kọ́. Ṣètò ṣáájú fún ìrírí tí akéde kan ní, láti fi hàn bí akéde náà ṣe kẹ́sẹ járí nínú wíwàásù lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà.

20 min: “Àpéjọ Àgbègbè ‘Ẹ Fi Ògo fún Ọlọ́run’ tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Yóò Ṣe ní Ọdún 2003.”b Kí akọ̀wé ìjọ bójú tó o, kó sì pe àfiyèsí sí ìpínrọ̀ 3 sí 13. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 13, tẹnu mọ́ ipa tí akọ̀wé ń kó gẹ́gẹ́ bí olùṣekòkárí àwọn ìṣètò àpéjọ àgbègbè fún ìjọ. Fi ọ̀yàyà gbóríyìn fún gbogbo àwọn ará fún mímúra sílẹ̀ fún àpéjọ náà bó ti lè ṣeé ṣe kó yá tó.

Orin 147 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 26

Orin 174

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán gbogbo àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti ìparí oṣù May sílẹ̀. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ June 1 àti Jí! June 8 lọni. Lo àbá kejì tó wà ní ojú ìwé 8 láti fi Jí! June 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí a fi àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì náà lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹyọ kan ṣoṣo la ó sọ̀rọ̀ lé lórí. Ní ìparí ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà, kí akéde fún onílé tí kò bá tẹ́wọ́ gba ìwé ìròyìn ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì?

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: “Òtítọ́ Ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”c Lo àwọn ìbéèrè tí a pèsè. Ké sí àwùjọ láti sọ bí a ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nígbà táwọn akéde lo Bíbélì láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọn. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, jẹ́ kí akéde kan tó dáńgájíá ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè lo Bíbélì nígbà ìbẹ̀wò àkọ́kọ́, kí ó lò lára àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Fí Ọwọ́ Tó Tọ́ Mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”—km-YR 12/01 ojú ìwé 1 ìpínrọ̀ 3 àti 4.

Orin 188 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 2

Orin 210

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Jíròrò ọ̀kan tàbí méjì lára àwọn àbá tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2002 fún fífi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè àti ìwé Ìmọ̀ lọni.

20 min: Ìgbéyàwó Tó Ní Ọlá—Ohun Ti Ọlọ́run Béèrè. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ó wọ́pọ̀ kí ọkùnrin àti obìnrin máa gbé pọ̀ láìṣègbéyàwó lábẹ́ òfin. Àwọn kan sọ pé àǹfààní wà nínú kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Sọ ojú ìwòye Bíbélì nípa ìgbéyàwó, kí o sì tẹnu mọ́ ọn pé Ọlọ́run ló pilẹ̀ ìṣètò yìí. (rs-E ojú ìwé 248 àti 249) Gbígbé pọ̀ láìṣègbéyàwó jẹ́ àgbèrè. (fy-YR ojú ìwé 17) Ní ìyàtọ̀ sí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn rò, ìwádìí ti fi hàn pé gbígbé pa pọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó kì í jẹ́ kí ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó kẹ́sẹ járí. (g02-E 3/8 ojú ìwé 29; g92-YR 9/8 ojú ìwé 28; g91-YR 11/8 ojú ìwé 28) Àwọn Kristẹni ń bọlá fún Jèhófà nípa gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ń ṣe ara wọn láǹfààní pẹ̀lú.—Aísá. 48:17, 18.

15 min: Àwọn Ọ̀nà Wo Lo Gbà Ń Jàǹfààní? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò bójú tó. Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù January, a ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìlànà tuntun fún dídarí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ní ṣókí, gbé díẹ̀ lára àwọn ohun tó jẹ́ tuntun nínú ilé ẹ̀kọ́ náà yẹ̀ wò. Pe àfiyèsí sí àwọn àǹfààní tí a ti jẹ látìgbà náà wá. Ǹjẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i ti forúkọ sílẹ̀ nínú ilé ẹ̀kọ́? Ǹjẹ́ àwọn ará ti múra tán láti túbọ̀ kópa nínú ilé ẹ̀kọ́ náà? Báwo làwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe ń jàǹfààní látinú ìṣètò tuntun fún fífúnni nímọ̀ràn? Ké sí àwùjọ láti sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní lẹ́nì kọ̀ọ̀kan látìgbà náà wá àti ọ̀nà tí wọ́n rò pé ìlànà tuntun náà lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ lọ́jọ́ iwájú.

Orin 225 àti àdúrà.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́