ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/03 ojú ìwé 1
  • A Fi Ìhìn Rere Náà Síkàáwọ́ Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Fi Ìhìn Rere Náà Síkàáwọ́ Wa
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Àwọn Tí Ń mú Ìhìn Rere Ohun Tí Ó Dára Jù Wá’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Kí Lò Ń Fi Sí Ipò Àkọ́kọ́?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Ọjọ́ Àpéjọ Àkànṣe
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ìhìn Rere Tó Yẹ Kí Gbogbo Èèyàn Gbọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 5/03 ojú ìwé 1

A Fi Ìhìn Rere Náà Síkàáwọ́ Wa

1 Àǹfààní ńlá gbáà ni fífi tí a fi ìhìn rere Ọlọ́run síkàáwọ́ wa mà jẹ́ fún wa o! (1 Tẹs. 2:4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ò fẹ́ láti tẹ́wọ́ gba ìhìn tó ń wọni lọ́kàn gan-an yìí, ńṣe ló ń fa àwọn olóòótọ́ ọkàn mọ́ra bí ìgbà tí òórùn tó ń ta sánsán ń fa ẹnì kan mọ́ra. (2 Kọ́r. 2:14-16) Èyí á yọrí sí ìgbàlà fún àwọn tó bá tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà, tí wọ́n sì ṣègbọràn sí i. (Róòmù 1:16) Kí ló yẹ ká ṣe nípa ìhìn rere tí a fi síkàáwọ́ wa yìí?

2 Jésù Àtàwọn Àpọ́sítélì: Pípolongo ìhìn rere náà ló jẹ Jésù lógún jù lọ. (Lúùkù 4:18, 43) Kódà nígbà tó ti rẹ̀ ẹ́ tí ebi sì ń pa á pàápàá, ìfẹ́ tó ní fún àwọn èèyàn àti ọwọ́ pàtàkì tó fi mú ìhìn rere náà sún un láti ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. (Máàkù 6:30-34) Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó sọ àti àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀, ó tẹ ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́kàn.—Mát. 28:18-20; Máàkù 13:10.

3 Ní ṣíṣàfarawé Jésù, àwọn àpọ́sítélì fi ìtara polongo ìhìn Ìjọba náà. Kódà nígbà tá a lù wọ́n, tá a sì tún pàṣẹ pé kí wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró pàápàá, “wọ́n . . . ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere.” (Ìṣe 5:40-42) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe iṣẹ́ yìí ní àṣekára. (1 Kọ́r. 15:9, 10; Kól. 1:29) Ó fi àǹfààní tó ní láti mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn wé gbèsè tó jẹ ọmọnìkejì rẹ̀, ó sì ṣe tán láti fi àwọn ìgbádùn du ara rẹ̀ kó bàa lè ṣe iṣẹ́ náà.—Ìṣe 20:24; Róòmù 1:14-16.

4 Àǹfààní Tí A Ní Lónìí: Ìmọrírì tá a ní fún iṣẹ́ ọlọ́wọ̀ tí a gbé lé wa lọ́wọ́ yìí yóò sún wa láti wá onírúurú ọ̀nà tí a lè gbà mú ìpín wa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà gbòòrò sí i. (Róòmù 15:16) Edward, ẹni tó jẹ́ pé orí kẹ̀kẹ́ àwọn arọ ló máa ń wà, máa ń jókòó sẹ́nu ọ̀nà òtẹ́ẹ̀lì kan tí yóò sì máa bá àwọn àlejò tó wà ní òtẹ́ẹ̀lì náà sọ̀rọ̀ nípa ohun tó gbà gbọ́. Àmọ́, nítorí pé ó fẹ́ láti ṣe púpọ̀ sí i, ó ní kí wọ́n bá òun ṣe ilé kan sẹ́yìn ọkọ̀ akẹ́rù, ó sì tipasẹ̀ ọkọ̀ yìí ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ó tún lò ó láti rin ìrìn àjò ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà nínú iṣẹ́ náà. Lónìí, bíi ti Edward, ọ̀pọ̀ ló ti ṣètò ọ̀ràn ara wọn kó bàa lè ṣeé ṣe fún wọn láti ṣe púpọ̀ sí i ní títan ìhìn rere náà kálẹ̀.

5 Ǹjẹ́ kí àwa náà lónìí fi iṣẹ́ ìwàásù yìí sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa ní ṣíṣàfarawé Jésù àtàwọn àpọ́sítélì. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, àti pé a mọrírì ìhìn rere tí a fi síkàáwọ́ wa.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́