ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/03 ojú ìwé 8
  • Kí Lò Ń Fi Sí Ipò Àkọ́kọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Lò Ń Fi Sí Ipò Àkọ́kọ́?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Ò Ń Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Láṣeyanjú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Olórí Iṣẹ́ Wa
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • “Máa Ṣọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí o Tẹ́wọ́ Gbà Nínú Olúwa”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • “Ẹ Lọ, Kí Ẹ sì Máa Sọ Àwọn Ènìyàn Gbogbo Orílẹ̀-Èdè Di Ọmọ Ẹ̀yìn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 2/03 ojú ìwé 8

Kí Lò Ń Fi Sí Ipò Àkọ́kọ́?

1 Ọ̀pọ̀ ètò ẹ̀sìn máa ń tẹnu mọ́ ṣíṣe àwọn iṣẹ́ àánú, irú bíi kíkọ́ ilé ìwé tàbí ilé ìwòsàn. Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gbàgbé “rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn,” ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí lohun tí à ń fi sí ipò àkọ́kọ́.—Héb. 13:16.

2 Àpẹẹrẹ Ọ̀rúndún Kìíní: Jésù ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ rere lákòókò iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé, àmọ́ olórí iṣẹ́ rẹ̀ ni jíjẹ́rìí sí òtítọ́. (Lúùkù 4:43; Jòh. 18:37; Ìṣe 10:38) Ó pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí ‘wọ́n lọ kí wọ́n sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n sì máa kọ́ wọn.’ (Mát. 28:19, 20) Ó tún sọ pé àwọn tó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú òun yóò ṣe iṣẹ́ tí òún bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ yìí lọ́nà tó túbọ̀ gbòòrò ju ti òun lọ. (Jòh. 14:12) Iṣẹ́ ìwàásù ni Jésù fi sí ipò àkọ́kọ́, nítorí pé iṣẹ́ náà ń jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ ọ̀nà ìgbàlà.—Jòh. 17:3.

3 Ohun “àìgbọ́dọ̀máṣe” ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ka ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ sí, ìyẹn ni pé ó jẹ́ ohun kan tí kò lè dágunlá sí. (1 Kọ́r. 9:16, 17) Ó múra tán láti ṣe ìrúbọ èyíkéyìí, láti fara da àdánwò tàbí ìpọ́njú èyíkéyìí tó bá pọn dandan kí ó lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láṣeparí. (Ìṣe 20:22-24) Àpọ́sítélì Pétérù àtàwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ náà fi irú ẹ̀mí yìí kan náà hàn. Àní, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n sọ wọ́n sẹ́wọ̀n tí wọ́n sì nà wọ́n, “wọ́n . . . ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.”—Ìṣe 5:40-42.

4 Àwa náà ńkọ́? Ǹjẹ́ à ń wo iṣẹ́ pípolongo ìhìn rere Ìjọba náà àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn gẹ́gẹ́ bí ohun tó ṣe pàtàkì ju ohunkóhun mìíràn lọ? Bíi ti Jésù, ǹjẹ́ à ń dàníyàn gidigidi nípa àwọn tí a ‘bó láwọ, tí a sì fọ́n ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.’ (Mát. 9:36) Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé báyìí àti àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbangba pé àkókò ti ń tán lọ fún ètò àwọn nǹkan yìí! Fífi sọ́kàn nígbà gbogbo pé iṣẹ́ ìwàásù yìí ṣe pàtàkì gan-an yóò máa sún wa láti máa fi ìtara wàásù nìṣó.

5 Gbé Ipò Rẹ Yẹ̀ Wò: Níwọ̀n bí ipò wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ti sábà máa ń yí padà, ó bọ́gbọ́n mu pé, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ká máa ronú bóyá a lè ṣe àwọn àtúnṣe kan láti lè túbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Arábìnrin kan ti ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé láwọn ọdún 1950, 1960, àtàwọn ọdún 1970, ṣùgbọ́n ó pọn dandan fún un láti dáwọ́ dúró nítorí àìlera ara. Àmọ́ bí àkókò ti ń lọ, ìlera rẹ̀ gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó tún ipò rẹ̀ gbé yẹ̀ wò ó sì pinnu pé òún ṣì tún lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lẹ́ẹ̀kan sí i. Inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tó ṣeé ṣe fún un láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà lẹ́ni àádọ́rùn-ún ọdún! Ìwọ náà ńkọ́? Ǹjẹ́ àkókò ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó fún ọ láti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ tàbí láti jáde ní ilé ẹ̀kọ́? Ǹjẹ́ wàá lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà nígbà tí ipò rẹ bá yí padà?

6 Nígbà tí Jésù ṣàkíyèsí pé Màtá “ní ìpínyà-ọkàn nítorí bíbójútó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojúṣe,” ó fi tìfẹ́tìfẹ́ gbà á nímọ̀ràn pé, bó bá lè dín gbogbo ohun tó kó máyà kù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún ni yóò rí gbà. (Lúùkù 10:40-42) Ṣé o lè dín ohun tó o kó máyà kù? Ǹjẹ́ lóòótọ́ ló pọn dandan pé kí tọkọtaya máa ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́? Ṣé ìdílé á lè ní àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé bí ẹnì kan ṣoṣo bá ń ṣiṣẹ́? Ọ̀pọ̀ ti jàǹfààní nípa tẹ̀mí nípa ṣíṣe àwọn àtúnṣe kan kí wọ́n bàa lè kópa síwájú sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà.

7 Ǹjẹ́ kí gbogbo wa lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì fi lélẹ̀! Ó dájú pé a óò rí ìbùkún Jèhófà gbà lórí àwọn ìsapá tá a fi tọkàntọkàn ṣe láti lè kópa kíkún nínú iṣẹ́ pàtàkì ti wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà.—Lúùkù 9:57-62.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́