Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Olórí Iṣẹ́ Wa
1 Gbogbo wa la ní onírúurú iṣẹ́ kan tàbí òmíràn tá a gbọ́dọ̀ ṣe. Pípèsè fún àwọn ara ilé ẹni jẹ́ ohun kan tí Ọlọ́run béèrè. (1 Tím. 5:8) Àmọ́ ṣá o, kò yẹ ká ka nǹkan tí Ọlọ́run béèrè yìí sí ohun tó ṣe pàtàkì ju iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.—Mát. 24:14; 28:19, 20.
2 Jésù fi àwòkọ́ṣe lélẹ̀ fún wa láti tẹ̀ lé ní ti “wíwá ìjọba náà . . . lákọ̀ọ́kọ́.” (Mát. 6:33; 1 Pét. 2:21) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ ní nǹkan tara, ó mú ṣíṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ lọ́kùn-únkúndùn. (Lúùkù 4:43; 9:58; Jòh. 4:34) Ó forí ṣe fọrùn ṣe láti jẹ́rìí ní gbogbo ìgbà táǹfààní rẹ̀ ṣí sílẹ̀. (Lúùkù 23:43; 1 Tím. 6:13) Ó rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti fi irú ìfẹ́ jíjinlẹ̀ yìí hàn nínú iṣẹ́ ìkórè náà.—Mát. 9:37, 38.
3 Bá A Ṣe Lè Fara Wé Jésù Lóde Òní: A lè fara wé àpẹẹrẹ Jésù nípa sísapá láti gbé ìgbésí ayé ṣe-bó-o-ti-mọ èyí tó máa jẹ́ ká lè gbájú mọ́ ṣíṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Bí a bá ti ní ohun kòṣeémáàní, ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì pé kí a má ṣe máa to ọrọ̀ jọ pelemọ. (Mát. 6:19, 20; 1 Tím. 6:8) Ẹ ò rí i pé ohun tó dára jù ni pé ká wá ọ̀nà tá a lè gbà ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù náà! Bí a bá níṣòro, ẹ jẹ́ ká sapá gidigidi bí Jésù ti ṣe, kí a má ṣe jẹ́ kí àníyàn ìgbésí ayé gba pípolongo ìhìn rere Ìjọba náà lọ́wọ́ wa, èyí tó jẹ́ olórí iṣẹ́ wa.—Lúùkù 8:14; 9:59-62.
4 Kódà àwọn tí wọ́n lẹ́rù iṣẹ́ púpọ̀ pàápàá ń fi iṣẹ́ ìwàásù náà sípò iwájú. Arákùnrin kan tó ní ìdílé ńlá, tó ní iṣẹ́ pàtàkì, tó sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ Kristẹni sọ pé: “Iṣẹ́ ìwàásù ni mo kà sí olórí iṣẹ́ mi.” Arábìnrin aṣáájú ọ̀nà kan sọ pé: “Iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ṣe pàtàkì fíìfíì ju iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó ń mówó gidi wọlé lọ.”
5 Láìka ipòkípò tá a lè wà sí, ẹ jẹ́ kí a máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Lọ́nà wo? Nípa fífi iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ṣe olórí iṣẹ́ wa.