ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/03 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 9
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 16
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 23
  • Ọ̀ṣẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 30
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 7
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 6/03 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 9

Orin 81

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Nípa lílo àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn kan nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ June 15 lọni. Ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan nínú àṣefihàn náà.

8 min: “Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?” Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn yóò bojú tó. Tẹnu mọ́ àwọn ọ̀nà tí ìwé pẹlẹbẹ tuntun yìí yóò gbà wúlò gan-an ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín, àti fún dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣe àṣefihàn ìwàásù ilé-dé-ilé oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́ta nípa lílo ọ̀kan lára àwọn kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé pẹlẹbẹ náà, kí a sì ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó tan mọ́ kókó ẹ̀kọ́ náà. Gba àwọn akéde níyànjú pé kí wọ́n ṣe ìpínkiri ìwé tuntun tá a dìídì ṣe fáwọn ará ilẹ̀ Áfíríkà yìí, kí wọ́n sì máa lò ó.

17 min: “Ìfẹ̀yìntì Lẹ́nu Iṣẹ́—Ǹjẹ́ Ó Ṣí Àǹfààní Sílẹ̀ fún Ìgbòkègbodò Púpọ̀ Sí I?”a Bó bá ṣeé ṣe, ṣe ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò ṣókí pẹ̀lú akéde kan tó ti lo àkókò ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Bi í léèrè àwọn ìyípadà tó ti ṣe àtàwọn ìbùkún tó ti rí látàrí èyí.

Orin 190 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 16

Orin 55

8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti ìlàjì oṣù June sílẹ̀

12 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

25 min: “Ẹ Jẹ́ Aláápọn Nínú ‘Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná.’”b Lo àwọn ìbéèrè tí a pèsè. Lẹ́yìn tó o bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 5 àti 6, ṣe àṣefihàn ṣókí nípa bí a ṣe jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà fún akọ̀wé ilé ìtajà kan àti bí a ṣe fi àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? lọ̀ ọ́. Kó o tó jíròrò ìpínrọ̀ 7 àti 8, jẹ́ kí á kọ́kọ́ kà wọ́n sókè ketekete.

Orin 131 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 23

Orin 95

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ July 1 àti Jí! July 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí a fi àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì náà lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹyọ kan ṣoṣo la ó sọ̀rọ̀ lé lórí. Nínú ọ̀kan lára àṣefihàn náà, fi hàn pé akéde náà wà lẹ́nu ìjẹ́rìí òpópónà.

20 min: Kí La Lè Ṣe Nípa Ìrẹ̀wẹ̀sì? Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí a gbé ka Ilé Ìṣọ́ November 15, 1999, ojú ìwé 28 sí 29 títí dé ìsọ̀rì náà “Níní Ẹ̀mí Tó Dáa,” kí o sì fi ìsọ̀rí náà kún un. Jíròrò àwọn àbá tó ṣeé mú lò àti ìmọ̀ràn tó bá Ìwé Mímọ́ mú tó wà níbẹ̀. Ṣètò ṣáájú fún ògbóṣáṣá akéde kan tàbí méjì láti ṣàlàyé àwọn ohun tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa láyọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn.

15 min: “Iṣẹ́ Ìwàásù Nínú Ayé Tí Kò Dúró Sójú Kan.”c Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 2 sí 3, bi àwùjọ léèrè àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ tá a lè lò láti bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ní ìpínlẹ̀ yín. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, ṣe àṣefihàn kúkúrú kan nípa lílo ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí a mẹ́nu kan.

Orin 15 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀ṣẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 30

Orin 3

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti ìparí oṣù June sílẹ̀. Sọ̀rọ̀ nípa ìwé tí a ó fi lọni ní oṣù July àti August. Sọ̀rọ̀ lórí méjì nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ tẹ́ ẹ ní lọ́wọ́. Jẹ́ kí a ṣe àṣefihàn tí a ti múra sílẹ̀ dáadáa nípa bí a ṣe lè fi àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà lọni lóde ẹ̀rí.

15 min: “Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Olórí Iṣẹ́ Wa.”d Gba àwọn ọ̀dọ́ níyànjú pé kí wọ́n ronú nípa àwọn ìbùkún tí wọn yóò gbádùn bí wọ́n bá wọṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Fi àwọn ọ̀rọ̀ tá a sọ lórí kókó yìí nínú Ilé Ìṣọ́ November 1, 2000, ojú ìwé 19 sí 20 kún un, lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Nígbà Tí Àṣà Ìbílẹ̀ àti Ẹ̀rí-Ọkàn Bá Forí Gbárí.”

20 min: Lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Lọ́nà Rere Láti Wàásù Ìjọba Náà. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí alàgbà kan yóò ṣe. Olúkúlùkù àwọn tí à ń bá pàdé lóde ẹ̀rí ni à ń sapá láti bá sọ ọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró nípa Ìjọba náà tá a gbé ka Ìwé Mímọ́. Àmọ́ ṣá o, ká kàn ka àwọn ẹsẹ Bíbélì nìkan kò tó. A ní láti ṣe àlàyé àwọn ẹsẹ náà, kí a fi àpèjúwe tì í lẹ́yìn, ká sì mú un bá ipò onílé mu. Fi bí a ṣe lè ṣe èyí hàn. Lẹ́yìn ìjíròrò náà, jẹ́ kí akéde kan tó múra sílẹ̀ dáadáa ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó dára nígbà ìpadàbẹ̀wò, kí ó ṣe àlàyé tó ṣe ṣókí, kí ó fi àpèjúwe tó rọrùn láti lóye tì í lẹ́yìn, kí ó sì fi han onílé ní ṣókí bí ìṣàkóso Ìjọba náà yóò ṣe ṣe é láǹfààní. Kí akéde náà bẹ̀rẹ̀ àṣefihàn yìí nípa kíka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà. Lẹ́yìn àṣefihàn náà, sọ̀rọ̀ lórí bó ṣe ṣàlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà, bó ṣe fi àpèjúwe tì í lẹ́yìn, àti bó ṣe mú un bá ipò onílé mu. Gba gbogbo akéde níyànjú pé kí wọ́n máa kọ́ bí wọ́n ṣe lè lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó dára.

Orin 171 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 7

Orin 165

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

15 min: Àwọn ìrírí tí àwọn akéde ní. Sọ ìrírí tí àwọn akéde ní tàbí kó o ṣe àṣefihàn ìrírí tí àwọn akéde ní (1) nígbà tí wọ́n ń wàásù fún onírúurú ẹ̀yà tàbí àwọn èèyàn tí ń sọ èdè mìíràn tàbí (2) nígbà tí wọ́n ń wàásù ní ọ̀nà mìíràn tó yàtọ̀ sí ìwàásù ilé-dé-ilé àti ìjẹ́rìí òpópónà. Gba gbogbo àwọn akéde níyànjú láti máa lo ìwé pẹlẹbẹ náà Good News for All Nations àti fọ́ọ̀mù Please Follow Up (S-43) nígbà tí wọ́n bá pàdé àwọn tí ń sọ èdè mìíràn.—Wo Àwọn Ìfilọ̀ tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 1999, ojú ìwé 2.

25 min: “Sísọ Orúkọ Ọlọ́run Di Mímọ̀.”e Lo àwọn ìbéèrè tí a pèsè. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, fi àlàyé tó wà nínú ìwé Proclaimers nínú àpótí náà “Making Known the Name of God” tó wà ní ojú ìwé 124 kún un. Jẹ́ kí akéde kan tó dáńgájíá ṣe àṣefihàn ìpadàbẹ̀wò kan. Nípa lílo méjì tàbí mẹ́ta lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú ìwé Reasoning, ojú ìwé 196 sí 197, fi ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti mọ orúkọ Ọlọ́run kí á sì máa lò ó hàn.

Orin 197 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́