Ohun Tá A Kà Sí Pàtàkì Jù Lọ
1. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà fi hàn pé iṣẹ́ ìwàásù ló ṣe pàtàkì jù lọ fún òun?
1 Iṣẹ́ ìwàásù ló ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé Jésù. Ó lo ara rẹ̀ tokuntokun, ó sì rin ọgọ́rọ̀ọ̀rún ibùsọ̀ yí gbogbo ẹkùn Palẹ́sínì ká, kó bàa lè wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Jésù jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ òun lọ́rùn, ìyẹn jẹ́ kó lè lo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́, kó sì túbọ̀ fún iṣẹ́ náà láfiyèsí. (Mát. 8:20) Nígbà táwọn kan fẹ́ dá Jésù dúró kó lè wo àwọn èèyàn wọn sàn, ó sọ pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.”—Lúùkù 4:43.
2. Kí nìdí tí iṣẹ́ ìwàásù fi gba Jésù lọ́kàn?
2 Kí nìdí tí iṣẹ́ ìwàásù fi gba Jésù lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀? Sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́ ló jẹ Jésù lógún jù lọ. (Mát. 6:9) Ó nífẹ̀ẹ́ Bàbá rẹ̀ ọ̀run débi pé ó wù ú láti ṣé ohun tí Bàbá rẹ̀ fẹ́ àti láti ṣègbọràn sí gbogbo àṣẹ rẹ̀. (Jòh. 14:31) Bákan náà, Jésù fẹ́ràn àwọn èèyàn látọkàn wá, ó sì fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́.—Mát. 9:36, 37.
3. Kí la lè ṣe láti fi hàn pé iṣẹ́ ìwàásù ló ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé wa?
3 Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù: Kò rọrùn láti pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ bíi ti Jésù tórí ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń gba àkókò wa nínú ayé yìí, tó sì ń fẹ́ pín ọkàn wa níyà. (Mát. 24:37-39; Lúùkù 21:34) Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù, ká sì ṣètò àkókò wa ká lè ní àkókò tó pọ̀ tó láti máa múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù ká sì máa kópa nínú rẹ̀ déédéé. (Fílí. 1:10) À ń sapá láti jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun tá a ní tẹ́ wa lọ́rùn, a kì í sì í lo ayé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.—1 Kọ́r. 7:31.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbájú mọ́ ṣíṣe ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nísinsìnyí?
4 Bí kò bá sí àkókò tó pọ̀ tó láti ṣe àwọn nǹkan, ńṣe ni ọlọgbọ́n èèyàn máa kọ́kọ́ ṣe ohun tó ṣe pàtàkì jù. Bí àpẹẹrẹ, tó bá mọ̀ pé ìjì líle máa tó jà, ó máa lo gbogbo àkókò àti okun rẹ̀ láti ṣètò bó ṣe máa dáàbò bo ìdílé rẹ̀ àti láti kìlọ̀ fún àwọn aládùúgbò rẹ̀. Ó máa kọ́kọ́ fi àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì sílẹ̀. Àkókò tó ṣẹ́ kù kí ogun Amágẹ́dọ́nì jà ti dín kù. (Sef. 1:14-16; 1 Kọ́r. 7:29) Bá a bá fẹ́ gba ara wa àtàwọn tó ń fetí sí wa là, a gbọ́dọ̀ máa fiyè sí ara wa nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ wa yálà nínú ìjọ tàbí níbòmíì. (1 Tím. 4:16) Láìsí àní-àní, ọwọ́ tá a bá fi mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ló máa pinnu bóyá a máa là á já!