Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ July 19
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 19
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cf orí 7 ìpínrọ̀ 17 sí 21 àti àpótí tó wà lójú ìwé 75
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 12-14
No. 1: 1 Àwọn Ọba 12:12-20
No. 2: Kí Ló Lè Jẹ́ Ká Máa Wo Àwọn Arákùnrin Wa bí Jèhófà Ṣe Ń Wò Wọ́n?
No. 3: Ọlọ́run Kò Fọwọ́ Sí Ìgbàgbọ́ Wò-ó-sàn Òde Òní (td 32D)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I—Apá Kejì. Àsọyé tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 112 ìpínrọ̀ 3, sí ojú ìwé 114, ìpínrọ̀ 1. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu aṣáájú-ọ̀nà kan tàbí méjì, ní kí wọ́n sọ àwọn àyípadà tí wọ́n ti ṣe kí wọ́n lè ráyè ṣe aṣáájú-ọ̀nà.
10 min: Bó O Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ Láti Pa Dà sí Iléèwé. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ní kí àwọn ará sọ díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tí àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni máa ń bá pàdé ní iléèwé. Ṣàlàyé bí àwọn òbí ṣe lè lo ìwé Index, Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé àti àwọn ìwé míì tí ètò Ọlọ́run ṣe, nígbà Ìjọsìn Ìdílé láti múra àwọn ọmọ wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè yẹra fún àwọn ohun tó lè dẹ wọ́n wò àti bí wọ́n ṣe lè ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́. (1 Pét. 3:15) Yan kókó ọ̀rọ̀ kan tàbí méjì, kó o sì sọ díẹ̀ lára ohun tí àwọn ìtẹ̀jáde náà sọ tó lè ṣèrànwọ́. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe wàásù níléèwé.
10 min: “Ǹjẹ́ Mò Ń Ṣe Tó Bó Ṣe Yẹ?” Ìbéèrè àti ìdáhùn.