Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ July 12
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 12
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 9-11
No. 1: 1 Àwọn Ọba 9:10-23
No. 2: Ìjọba Ọlọ́run Máa Mú Ìwòsàn Ti Ara Wíwàpẹ́títí Wá (td 32B)
No. 3: Bí Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Ṣe Ń Fi Ọgbọ́n Àtọ̀runwá Hàn (Ják. 3:17)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
15 min: Ṣé O Ti Lo Àwọn Àbá Wọ̀nyí? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ní ṣókí, sọ àwọn àbá tó jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa lẹ́nu àìpé yìí, ìyẹn àwọn àbá tó jáde nínú àpilẹ̀kọ wọ̀nyí: “Ẹ Sapá Gidigidi Láti Wàásù Fáwọn Ọkùnrin” (8/09), “Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ni Wá Nígbà Gbogbo” (11/09) àti “Máa Ṣèrànwọ́ fún Ẹni Tẹ́ Ẹ Jọ Ń Wàásù Lóde Ẹ̀rí” (3/10). Ní kí àwùjọ sọ bí wọ́n ṣe fi àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà sílò àti àwọn àǹfààní tí wọ́n ti rí.
15 min: “Ohun Tá A Kà Sí Pàtàkì Jù Lọ.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.