Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ June 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń wo ìràwọ̀ ọjọ́ ìbí wọn kí wọ́n tó ṣe ìpinnu. Ǹjẹ́ o rò pé àwọn ìràwọ̀ máa ń nípa kankan lórí ìgbésí ayé wa? [Jẹ́ kó fèsì.] Ó dùn mọ́ wa nínú pé Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àgbájọ ìràwọ̀ sódíákì. [Ka 2 Ọba 23:5.] Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa wíwo ìràwọ̀.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 18 hàn án.
Ji! July–September
Ka Sáàmù 37:9-11. Kó o wá béèrè pé, “Báwo lo ṣe rò pé ayé máa rí bí ohun tá a kà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí bá nímùúṣẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ̀rọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ tó ń múnú ẹni dùn yìí, ó sì tún jẹ́ ká mọ ìdí tí ìwà búburú fi pọ̀ ní ayé lóde òní.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 19 hàn án.
Ilé Ìṣọ́ July 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ̀ pé Olódùmarè ní orúkọ. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Bíbélì sọ orúkọ Ọlọ́run fún wa? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Aísáyà 42:8a.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan, ó sì jẹ́ ká mọ àǹfààní tó wà nínú lílo orúkọ Ọlọ́run.”
Ji! July–September
“Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń mu sìgá ló máa ń fẹ́ jáwọ́ nínú àṣà náà, àmọ́ ó máa ń ṣòro fún wọn. Ǹjẹ́ o mọ ẹnì kan tó ń fẹ́ láti jáwọ́ nínú sìgá mímu? [Jẹ́ kó fèsì.] Ohun tó mú káwọn kan lè jáwọ́ ni pé wọ́n ti wá ìrànlọ́wọ́ àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́. [Ka Oníwàásù 4:12a.] Àwọn àbá mélòó kan tó lè ṣèrànwọ́ fún ẹni tó bá fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu wà nínú ìwé ìròyìn yìí.”