Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Inú wa dùn láti sọ fún yín pé ìròyìn iṣẹ́ ìsìn wa gbé pẹ́ẹ́lí ju ti ìgbàkígbà rí lọ ní oṣù January 2010. Iye ìwé tá a fi sóde jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìléláàádọ́fà àti ẹgbẹ̀ta dín méjì [112,598], iye ìwé ìròyìn jẹ́ àádọ́ta ọ̀kẹ́, ẹgbẹ̀rún lọ́nà òjìlélẹ́gbẹ̀rin lé mẹ́ta àti ẹgbẹ̀ta lé méjì [1,843,602], nígbà tí iye àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé tó ròyìn jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta dín kan [30,449].