Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù Rẹ
1 Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa láti tẹ̀ lé nínú ọ̀nà tá a gbà ń ṣiṣẹ́ ìwàásù. Lọ́pọ̀ ìgbà àti lónírúurú ọ̀nà ni Jésù gbà fi hàn bí ìfẹ́ tóun ní sí Ọlọ́run àtàwọn èèyàn ṣe jinlẹ̀ tó. Ó jẹ́ káwọn ọlọ́kàn tútù mọ òtítọ́ ó sì finúure hàn sáwọn tójú ń pọ́n àtàwọn tí wọ́n ń ni lára.—Mát. 9:35.
2 Ẹ̀kọ́ Tí Jésù Fi Kọ́ni àti Àpẹẹrẹ Tó Fi Lélẹ̀: Jésù ò jẹ́ kí ọ̀ràn òṣèlú tàbí àwọn iṣẹ́ ìfẹ́dàáfẹ́re gba òun lọ́kàn. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò jẹ́ kí lílépa àwọn nǹkan míì tó lè dà bí àṣeyọrí pín ọkàn òun níyà tàbí kó wá gbé wọn sọ́kàn débi táwọn nǹkan yẹn á fi dí i lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run ní kó ṣe. (Lúùkù 8:1) Iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ló gbájú mọ́ torí ó mọ̀ pé ìyẹn nìkan ni ojútùú kan ṣoṣo sí ìṣòro aráyé. Iṣẹ́ pàtàkì ló wà níwájú Jésù láti ṣe, àkókò tó ní ò sì pọ̀. Ìdí nìyẹn, nígbà táwọn èèyàn ìlú Kápánáúmù sọ pé kó tẹsẹ̀ ró díẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn, ohun tó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni pé: “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí ibòmíràn, . . . kí èmi lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú, nítorí fún ète yìí ni mo ṣe jáde lọ.”—Máàkù 1:38.
3 Jésù rán àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ jáde ní méjì méjì lẹ́yìn tó ti fún wọn láwọn ìtọ́ni kan nípa ohun tí wọ́n ní láti ṣe, ó ní: “Ẹ máa wàásù, pé, ‘Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’” (Mát. 10:7) Ohun tó fi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni pé Ìjọba Ọlọ́run ló gbọ́dọ̀ gbawájú nígbèésí ayé wọn. (Mát. 6:33) Jésù mú kí ohun tó fẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ ìdágbére tó bá wọn sọ kó tó gòkè re ọ̀run. Ó ní: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.”—Mát. 28:19.
4 Ìdí Tí Ìjọba Ọlọ́run Fi Ṣe Kókó: Gbogbo ohun tí ìjíròrò Jésù máa ń dá lé kì í ju Ìjọba Ọlọ́run lọ, ó sì rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ òun. Kò sí bí ìsapá ẹ̀dá ṣe lè pọ̀ tó, kò lè yanjú ìṣòro aráyé. (Jer. 10:23) Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ tó sì máa gba aráyé lọ́wọ́ ìṣòro tó ń dojú kọ wọ́n. (Mát. 6:9, 10) Kíkọ́ àwọn èèyàn tó “ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora nítorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí” lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run á ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé aláyọ̀ tó nítumọ̀ nísinsìnyí, wọ́n á sì lè di ìrètí tó ṣeé gbọ́kàn lé nípa ọjọ́ ọ̀la mú gírígírí.—Ìsík. 9:4.
5 Títí di báyìí, Jésù ò tíì jáwọ́ láti máa kó ipa tó jọjú nínú wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ó sì mú un dá wa lójú pé òun ò ní padà lẹ́yìn wa. (Mát. 28:20) Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe bá àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ fún wa mu? (1 Pét. 2:21) Níwọ̀nba àkókò díẹ̀ tó kù nínú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ǹjẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe nínú ọ̀nà tá a gbà ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù láti rí i pé a ò ṣe ohun tó yàtọ̀ sí àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ fún wa!