Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 12
Orin 52
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù February sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ February 15 àti Jí! January-March. (Lo àbá kẹta fún Jí! January-March) Nínú ọ̀kan lára àṣefihàn náà, fi hàn báwọn ará ṣe lè fún ẹni tí ò fẹ́ gbọ́rọ̀ wọn lésì, tó wá sọ pé, “Èmi kò nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn.”—Wo ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ewé 9.
15 min: “Ìṣúra Tó Wà Níkàáwọ́ Wa.”a Bí àkókò bá ṣe wà sí, fi ìrírí kan tàbí méjì kún un.
20 min: Múra Sílẹ̀ Láti Pín Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Kingdom News No. 37. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Jíròrò bá a ṣe máa ṣe ìpínkiri náà gẹ́gẹ́ bá a ṣe jíròrò rẹ̀ nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù January. Gba gbogbo àwọn ará níyànjú láti fi gbogbo ara kópa nínú pípín in fún gbogbo èèyàn. Gba àwọn tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn ń ṣe dáadáa níyànjú pé kí wọ́n gbà á rò bóyá irú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ́ẹ̀ yẹ lẹ́ni tó lè bá wa lọ́wọ́ sí ìpínkiri náà gẹ́gẹ́ bí akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Àwọn òbí lè gbé àwọn ọmọ wọn yẹ̀ wò bóyá wọ́n ti yẹ lẹ́ni tó lè di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi kí wọ́n bàa lè lọ́wọ́ sí ìpínkiri yìí. Ní ṣókí, mẹ́nu ba àwọn kókó tó wà nínú ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, lójú ìwé 79 sí 81.
Orin 104 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 19
Orin 198
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
20 min: “Àpẹẹrẹ Olùkọ́ Ńlá Náà Ni Kó O Máa Tẹ̀ Lé Bó O Bá Ń Lo Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni.”b Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 6, ní kí akéde kan ṣe àṣefihàn ṣókí. Kó lo àpótí tó wà nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, níparí orí 6 láti fi ṣe àtúnyẹ̀wò orí náà pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀.
20 min: “Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù Rẹ.”c Bí àkókò bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀ kí wọ́n sì ṣàlàyé rẹ̀.
Orin 220 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 26
Orin 29
15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ March 1 àti Jí! January–March. (Lo àbá kẹrin fún Jí! January–March.) Nínú ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà, fi hàn bí akéde kan ṣe ń wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù táwọn oníṣòwò pọ̀ sí. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù February sílẹ̀.
15 min: “Má Ṣe Gbàgbé Àwọn Aláìṣiṣẹ́mọ́.”d Fi àlàyé kún un látinú Ilé Ìṣọ́ May 1, 2004 ojú ìwé 21 àti 22, ìpínrọ̀ 13 sí 16.
15 min: Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ọ̀nà Tá A Gbà Ń Wàásù Ìhìn Rere Wà Létòlétò. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, láti àkòrí kékeré tó wà lójú ìwé 102 títí dé ìparí orí yẹn.
Orin 18 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 5
Orin 32
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Fún gbogbo àwọn tó wá sípàdé ní àkànṣe ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi, kó o sì ṣàlàyé àwọn ètò tí ìjọ ti ṣe fún pípín ìwé ìkésíni náà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ. Rọ gbogbo àwọn ará láti lọ́wọ́ sí pípín ìwé ìkésíni náà. Ṣe àṣefihàn kan tó máa jẹ́ káwọn ará rí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà lo ìwé ìkésíni náà.
35 min: “Ẹ Polongo Àwọn Ìtayọlọ́lá Jèhófà Kárí Ayé.”e Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó bójú tó iṣẹ́ yìí. Láàárín ìjíròrò yìí, sọ àkókò àti ibi tí ìjọ yín ti máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún yìí, sọ ètò tẹ́ ẹ ti ṣe láti ní àfikún ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá àti iye àwọn tẹ́ ẹ̀ ń retí látinú ìjọ yín pé kí wọ́n yọ̀ọ̀da ara wọn láti gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù April. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá jíròrò ìpínrọ̀ 3, ní kí akéde kan ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè pe olùfìfẹ́hàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi.
Orin 147 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.