ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/09 ojú ìwé 6-7
  • Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ni Wá Nígbà Gbogbo

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ni Wá Nígbà Gbogbo
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • O Lè Jẹ́rìí Láìjẹ́-bí-Àṣà!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò Lọ́nà Àìjẹ́-Bí-Àṣà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Jésù Wàásù fún Obìnrin Ará Samáríà Kan
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Máa Yin Jèhófà Nípa Wíwàásù Lọ́nà Àìjẹ́ bí Àṣà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
km 11/09 ojú ìwé 6-7

Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ni Wá Nígbà Gbogbo

1. Kí la lè rí kọ́ látinú àkọsílẹ̀ nípa bí Jésù ṣe jẹ́rìí fún obìnrin kan létí kànga?

1 Jésù ti rìnrìn àjò fún ọ̀pọ̀ wákàtí. Ó ti rẹ̀ ẹ́, òùngbẹ sì ń gbẹ ẹ́. Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ ra oúnjẹ, ó jókòó létí kànga kan lóde ìlú Samáríà láti sinmi. Kì í ṣe torí àtilọ wàásù ni Jésù ṣe lọ sí Samáríà; ó kàn ń kọjá lọ sí Gálílì ni, kó lè máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lọ níbẹ̀. Síbẹ̀, ó lo àǹfààní yẹn láti wàásù fún obìnrin kan tó ń fa omi nínú kànga. (Jòh. 4:5-14) Kí nìdí tí Jésù fi ṣe bẹ́ẹ̀? Jésù ò fìgbà kan ṣíwọ́ jíjẹ́ “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé àti olóòótọ” fún Jèhófà. (Ìṣí. 3:14) Àwa náà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa jíjẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà gbogbo.—1 Pét. 2:21.

2. Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ láti jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà?

2 Múra Sílẹ̀: A lè múra sílẹ̀ láti jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà tá a bá ń mú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ dání nígbà tá a bá ń jáde. Ọ̀pọ̀ akéde máa ń mú ìwé àṣàrò kúkúrú dání, wọ́n sì máa ń fún àwọn tó ń tajà ní ṣọ́ọ̀bù tàbí ní ọjà, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nílé epo àtàwọn míì tí wọ́n lè bá pàdé. (Oníw. 11:6) Arábìnrin kan tó sábà máa ń rìnrìn àjò máa ń rí i pé òun mú Bíbélì kékeré tó ṣeé kì bọ àpò àti ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni sínú àpamọ́wọ́ rẹ̀, ó sì máa ń gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú àwọn tó bá jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

3. Báwo la ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò?

3 Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò: Tá a bá fẹ́ wàásù láìjẹ́ bí àṣà, kò yẹ ká bẹ̀rẹ̀ nípa fífa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́. Jésù kò bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ pẹ̀lú obìnrin tó bá pàdé létí kànga yẹn nípa sísọ fún un pé òun ni Mèsáyà náà. Ńṣe ni Jésù ní kó fún òun lómi mu, bí àwọn méjèèjì ṣe bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nìyẹn. (Jòh. 4:7-9) Arábìnrin kan rí i pé lílo irú ọ̀nà yìí máa ń jẹ́ kí òun lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nígbà tí ẹnì kan bá bi òun bóyá òun gbádùn ayẹyẹ kan. Dípò tí ì bá fi sọ fún onítọ̀hún pé ìdí tí òun kì í fi í ṣe ayẹyẹ yẹn ni pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni òun, ó ní, ńṣe lòun máa ń sọ pé, “Mo ti pinnu pé mi ò ní máa ṣe ayẹyẹ yìí ní tèmi.” Ẹni tó bá bi í ní ìbéèrè yìí sábà máa ń fẹ́ mọ ìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀, èyí sì máa ń fún arábìnrin náà láǹfààní láti jẹ́rìí.

4. Kí nìdí tí Mátíù 28:18-20 fi fún ẹ ní ìṣírí?

4 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù ti parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ tó fìtara ṣe lórí ilẹ̀ ayé, ó ṣì ń wù ú gan-an pé ká máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà lọ́nà tí òun gbà ṣe é. (Mát. 28:18-20) Torí náà, bíi ti Jésù, Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa, àwa náà jẹ́ Ẹlẹ́rìí tó ti múra tán láti polongo ìgbàgbọ́ wa ní gbangba lọ́jọ́kọ́jọ́.—Héb. 10:23.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́