Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò Lọ́nà Àìjẹ́-Bí-Àṣà
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì: Tá a bá ń wàásù láti ilé délé, a kì í sábà bá ọ̀pọ̀ èèyàn nílé. Àmọ́, ó ṣeé ṣe ká pàdé wọn nígbà tá a bá wọ ọkọ̀ èrò, tá a bá wà nílé ìwòsàn, ní àkókò ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ tàbí ní ilé ìwé àti láwọn ibòmíì. Ìfẹ́ Jèhófà ni pé kí gbogbo èèyàn láǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (1 Tím. 2:3, 4) Àmọ́, ká tó lè wàásù, a gbọ́dọ̀ máa lo ìdánúṣe láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò.
Gbìyànjú Èyí Lóṣù Yìí:
Gbìyànjú láti bá ó kéré tán, ẹnìkan jíròrò lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.