Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ July 21
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 21
Orin 73 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 10 ìpínrọ̀ 8 sí 17 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Léfítíkù 25-27 (10 min.)
No. 1: Léfítíkù 26:1-17 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ǹjẹ́ Ìgbàgbọ́ Nínú Jésù Nìkan Tó Láti Gbani Là?—td 35D (5 min.)
No. 3: Ìdí Tó Fi Nira Láti Máa Ṣe Rere—lr orí 26 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Wọ́n Mọrírì Ìwà Rere Wa àti Bí A Kì Í Ṣe Lọ́wọ́ sí Ogun. Ìjíròrò tó dá lórí Ìwé Ọdọọdún 2014, ojú ìwé 120 àti 149. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
10 min: Ǹjẹ́ O Lè Ṣe Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Ní Oṣù August? Àsọyé. Fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn akéde méjì tàbí mẹ́ta tí wọ́n wéwèé láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù August bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n níṣòro àìlera tàbí pé ọwọ́ wọn máa ń dí. Àwọn ìyípadà wo ni wọ́n máa ṣe kí wọ́n lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́? Ní kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn sọ ètò tó wà nílẹ̀ fún ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá lóṣù August.
10 min: “Báwo Ni Mo Ṣe Rí Lójú Jèhófà?” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 65 àti Àdúrà