Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ July 14
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 14
Orin 1 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 10 ìpínrọ̀ 1 sí 7 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Léfítíkù 21-24 (10 min.)
No. 1: Léfítíkù 23:1-14 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Ká Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Jésù Ká Tó Lè Ní Ìgbàlà—td 35B (5 min.)
No. 3: Ǹjẹ́ Àwọn Tó Ń Ṣe Ohun Búburú Lè Yí Pa Dà?—lr orí 25 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Múra Sílẹ̀ fún Ìpolongo Àkànṣe Tó Máa Wáyé ní Oṣù August. Pín ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan ìwé àṣàrò kúkúrú tuntun náà, Ibo La Ti Lè Rí Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Pàtàkì Nípa Ìgbésí Ayé? fún àwọn tí kò bá ní. Lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé 4 láti ṣe àṣefihàn méjì. Kọ́kọ́ ṣe àṣefihàn bí a ó ṣe fi ìwé àṣàrò kúkúrú náà lọ onílé. Lẹ́yìn náà, ṣe àṣefihàn bí a ó ṣe lò ó tí onílé bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa. Fún gbogbo àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n kópa ní kíkún nínú ìpolongo náà.
5 min: Jàǹfààní Látinú Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́. Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ ìgbà tí wọ́n máa ń ka ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́, kí wọ́n sì sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní látinú lílo ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́.
15 min: “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò Lọ́nà Àìjẹ́-Bí-Àṣà.” Ìjíròrò. Ṣe àṣefihàn kan.
Orin 107 àti Àdúrà