Bí A Ṣe Lè Mú Ọ̀nà Tí A Gbà Ń Fọ̀rọ̀ Wérọ̀ Sunwọ̀n Sí I
ǸJẸ́ ó sábà máa ń rọ̀ ọ́ lọ́rùn láti bá àwọn ẹlòmíràn fọ̀rọ̀ wérọ̀? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé bí wọ́n bá tiẹ̀ ti ń rò ó lásán pé àwọn yóò báni fọ̀rọ̀ wérọ̀ làyà wọn á ti máa já, àgàgà bí onítọ̀hún bá jẹ́ ẹni tí wọn ò mọ̀ rí. Irú àwọn bẹ́ẹ̀ lè máa tijú. Wọ́n lè máa rò ó pé: ‘Kí ni màá tiẹ̀ sọ ná? Báwo ni mo ṣe fẹ́ dá ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yẹn sílẹ̀? Kí ni màá sọ tí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yẹn á fi máa bá a lọ?’ Àwọn èèyàn tí kì í bẹ̀rù, tí wọ́n jẹ́ ọlọ́yàyà ní tiwọn lè kúkú fẹ́ dá gbogbo ọ̀rọ̀ sọ. Ó lè jẹ́ pé wọn kò mọ bí a ti ń fani wọnú ìfọ̀rọ̀wérọ̀, wọ́n sì lè má mọ béèyàn ṣe ń dẹ́nu dúró láti gbọ́rọ̀ ẹnu ẹlòmíràn. Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo wa la ní láti máa fi bí a ṣe ń fọ̀rọ̀ wérọ̀ kọ́ra, à báà jẹ́ ẹni tó ń tijú tàbí ọlọ́yàyà.
Bẹ̀rẹ̀ Nílé
Tó o bá fẹ́ mú ọ̀nà tó o gbà ń fọ̀rọ̀ wérọ̀ sunwọ̀n sí i, o ò ṣe bẹ̀rẹ̀ nínú ilé rẹ? Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó ń gbéni ró lè mú kí ìdílé túbọ̀ láyọ̀.
Pàtàkì ohun tó ń mú kí irú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ bẹ́ẹ̀ lè wáyé ni ṣíṣaájò ará ilé ẹni dáadáa. (Diu. 6:6, 7; Òwe 4:1-4) Bí a bá lẹ́mìí aájò, a óò báni jíròrò, a ó sì fetí sílẹ̀ bí onítọ̀hún bá fẹ́ sọ̀rọ̀. Kókó pàtàkì mìíràn ni pé kéèyàn ní nǹkan tó dáa tó fẹ́ sọ. Bí àwa fúnra wa bá ṣètò láti máa ka Bíbélì kí a sì máa kẹ́kọ̀ọ́ déédéé, a óò ní ohun púpọ̀ tá a lè fi bá àwọn èèyàn fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀. Bí a bá lo ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, ó lè mú kí ìjíròrò dùn ún ṣe. Bóyá a ní ìrírí alárinrin lóde ẹ̀rí lọ́jọ́ ọ̀hún. A lè ka nǹkan kan tó kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ tàbí tó pani lẹ́rìn-ín. Ó yẹ ká sọ ọ́ di àṣà wa láti máa sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nígbà tí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó gbéni ró bá wáyé nínú ìdílé. Ìyẹn á tún ràn wá lọ́wọ́ láti lè máa bá àwọn èèyàn tí kì í ṣe ará ilé wa fọ̀rọ̀ wérọ̀ pẹ̀lú.
Bíbá Ẹni Tí A Kò Mọ̀ Rí Fọ̀rọ̀ Wérọ̀
Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í yá lára láti bẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú ẹni tí wọn kò mọ̀ rí. Ṣùgbọ́n nítorí pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ràn Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wa, a máa ń sapá gidigidi láti kọ́ bí a ṣe máa ń báni fọ̀rọ̀ wérọ̀ kí a lè sọ òtítọ́ Bíbélì fún àwọn ẹlòmíràn. Kí ló lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ ṣe dáadáa sí i lórí kókó yìí?
Ní Fílípì 2:4, a mẹ́nu ba ìlànà kan tó wúlò. Ibẹ̀ gbà wá níyànjú pé kí á má ṣe máa mójú tó “kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara [wa] nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” Rò ó lọ́nà báyìí ná: Tó ò bá tíì bá onítọ̀hún pàdé rí, ẹni àjèjì ló máa kà ọ́ sí. Báwo ni wàá ṣe fọkàn rẹ̀ balẹ̀? Ẹ̀rín músẹ́ àti kíkí i bí ọ̀rẹ́ á ṣèrànwọ́. Ṣùgbọ́n ó tún ku àwọn ohun mìíràn láti gbé yẹ̀ wò.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe lo já lu ohun tó ń rò lọ́kàn. Tó o bá sì wá fẹ́ kó dá sí ohun tó wà lọ́kàn tìrẹ, láìbìkítà nípa ohun tó wà lọ́kàn tirẹ̀, ṣe inú rẹ̀ á dùn sí i? Kí ni Jésù ṣe nígbà tó bá obìnrin kan pàdé létí kànga ní Samáríà? Omi tí obìnrin yẹn fẹ́ pọn ló wà lọ́kàn rẹ̀. Orí ìyẹn sì ni Jésù gbé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ̀ kà, kò sì pẹ́ tó fi sọ ọ́ di ìjíròrò alárinrin lórí nǹkan tẹ̀mí.—Jòh. 4:7-26.
Bí ìwọ náà bá lákìíyèsí, wàá lè fòye mọ ohun tó ṣeé ṣe kí àwọn èèyàn máa rò lọ́kàn. Ṣé ẹni yẹn jọ ẹni tínú ẹ̀ dùn ni tàbí ẹni tínú ẹ̀ bà jẹ́? Ṣé àgbàlagbà ni, bóyá tára ẹ̀ kò le? Ǹjẹ́ o rí ẹ̀rí pé àwọn ọmọdé wà nílé yẹn? Ṣé ó jọ pé ẹni yẹn rí jájẹ tàbí ẹni tí nǹkan ò dán mọ́rán fún ni? Àwọn ohun ọ̀ṣọ́ inú ilé yẹn ha fi hàn pé ó fẹ́ràn ẹ̀sìn bí? Bí ìyẹn bá hàn nínú ọ̀nà tó o gbà kí wọn, ẹni yẹn lè wò ọ́ bí ẹni tọ́rọ̀ àwọn jọ wọra.
Bí onílé kò bá sì yọjú sí ọ, bóyá tó tilẹ̀kùn mọ́rí tó wá ń bá ọ sọ̀rọ̀ látinú ilé, kí ló lè wá sí ọ lọ́kàn? Ìyẹn ni pé ó ṣeé ṣe kí ẹni yẹn máa bẹ̀rù. Ǹjẹ́ o lè wá lo ohun tó o rí yẹn láti fi bẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ níta tó o wà?
Láwọn ibì kan, o lè mú kéèyàn bá ọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ nípa sísọ irú ẹni tó o jẹ́ fún un, ìyẹn ibi tó o ti wá àti iṣẹ́ tí ò ń ṣe, ìdí tí o fi wá sí ẹnu ọ̀nà rẹ̀, ìdí tí o fi gba Ọlọ́run gbọ́, ìdí tí o fi bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àti bí Bíbélì ti ṣe ràn ọ́ lọ́wọ́. (Ìṣe 26:4-23) Àmọ́ ṣá o, ó gba kéèyàn wojú ilẹ̀ dáadáa kéèyàn sì mọ ibi tóun fẹ́ bọ́rọ̀ lọ kó tó dáwọ́ lé irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Èyí lè wá sún ẹni yẹn láti sọ nǹkan kan fún ọ nípa ara rẹ̀ àti ohun tó rò nípa àwọn nǹkan tó o sọ.
Àwọn ẹ̀yà kan láájò àlejò dáadáa. Ó lè jẹ́ pé bó o ṣe ń débẹ̀ ni wọ́n á ti ní kó o wọlé jókòó. Bí o bá jókòó, tó o sì wá béèrè àlàáfíà àwọn ará ilé gẹ́gẹ́ bí ìṣe ọmọlúwàbí, tí o sì dúró gbọ́ èsì wọn, onílé náà lè fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí o wá bá a sọ pẹ̀lú. Àwọn mìíràn tiẹ̀ fẹ́ràn àlejò gan-an débi pé, ẹ lè kọ́kọ́ kira yín lọ bí ilẹ̀ bí ẹní ná. Wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ rí i pé ọ̀rọ̀ ìwọ àti àwọn wọ̀ dáadáa. Ìyẹn lè mú kí ẹ lè jọ sọ ọ̀rọ̀ tó ṣàǹfààní gan-an nípa tẹ̀mí.
Ká ní pé ibi tí àwọn èèyàn tó ń sọ onírúurú èdè tó yàtọ̀ sí tìrẹ ti pọ̀ gan-an lò ń gbé ńkọ́? Báwo ni yóò ṣe ṣeé ṣe fún ọ láti bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀? Bó bá tiẹ̀ jẹ́ bí wọ́n ṣe ń kíni ní àwọn èdè kan lára èdè wọ̀nyẹn lo kọ́ láti máa sọ táátààtá, àwọn wọ̀nyẹn á rí i pé o fẹ́ràn àwọn. Ìyẹn lè mú kó ṣeé ṣe fún yín láti jọ sọ̀rọ̀ síwájú sí i.
Bí A Ṣe Lè Máa Bá Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Lọ
Tó o bá ń fẹ́ kí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yín máa bá a lọ, o ní láti nífẹ̀ẹ́ sí èrò ọkàn ẹni tẹ́ ẹ jọ ń sọ̀rọ̀. Gbà á níyànjú láti sọ èrò tirẹ̀ tó bá fẹ́. Tí o bá bi í láwọn ìbéèrè tó bọ́gbọ́n mu, ó ṣeé ṣe kó sọ̀rọ̀. Àwọn ìbéèrè tí ń fi èrò ẹni hàn ló ti dáa jù nítorí wọn kì í sábà jẹ́ kí èsì onílé mọ sí bẹ́ẹ̀ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tó o bá ti mẹ́nu kan nǹkan kan tó ṣẹlẹ̀ ládùúgbò, o lè wá béèrè pé: “Kí lo rò pé ó fa ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí?” tàbí “Kí lo rò pé ó lè yanjú ẹ̀?”
Tó o bá bi ẹnì kan ní ìbéèrè, tẹ́tí sí èsì onítọ̀hún dáadáa. O lè sọ̀rọ̀, o lè mi orí, tàbí kó o fara ṣàpèjúwe láti fi hàn pé ò ń gbọ́ ẹni yẹn lágbọ̀ọ́yé. Má ṣe já lu ọ̀rọ̀ rẹ̀ o. Gbé ohun tó bá sọ yẹ̀ wò láìlo ẹ̀tanú. “Yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.” (Ják. 1:19) Nígbà tó o bá sì máa fèsì, fi hàn pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ yé ọ dáadáa.
Àmọ́ ṣá, mọ̀ dájú pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa fèsì àwọn ìbéèrè rẹ o. Ó lè jẹ́ ìfaraṣàpèjúwe tàbí ẹ̀rín múṣẹ́ nìkan ni ẹlòmíràn máa fi dáhùn. Àwọn mìíràn tiẹ̀ lè má sọ ju bẹ́ẹ̀ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ. Má ṣe jẹ́ kí ìyẹn dà ọ́ láàmú. Ṣe sùúrù. Má gbìyànjú láti tọwọ́ bọ onílé lọ́fun. Bónítọ̀hún bá fẹ́ gbọ́rọ̀ rẹ, lo àǹfààní yẹn láti fi bá a sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró látinú Ìwé Mímọ́. Láìpẹ́, onítọ̀hún lè wá kà ọ́ sí ọ̀rẹ́. Bóyá nígbà yẹn ó lè yá a lára láti máa sọ èrò ọkàn rẹ̀ fún ọ.
Bí o ṣe ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ máa fi apá kan múra wọn sílẹ̀ de ìpadàbẹ̀wò rẹ lọ́jọ́ iwájú. Bí ẹnì kan bá bi ọ́ ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè, dáhùn àwọn kan lára rẹ̀ kí o wá fi ọ̀kan tàbí méjì lára rẹ̀ sílẹ̀ dìgbà mìíràn tí ẹ tún máa jọ fọ̀rọ̀ wérọ̀. Sọ fún un pé wàá ṣe ìwádìí nípa ìbéèrè rẹ̀, wàá sì padà wá sọ ohun tí o bá rí fún un. Bí kò bá sì wá béèrè ìbéèrè kankan, nígbà tí o bá ń parí ọ̀rọ̀ rẹ o lè bi í ní ìbéèrè kan tó o rò pé inú rẹ̀ á dùn láti dáhùn. Sọ pé ẹ máa jíròrò rẹ̀ nígbà tó o bá tún padà wá. O lè rí ìsọfúnni púpọ̀ nínú ìwé Reasoning From the Scriptures, ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, àti àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó jẹ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́.
Tó O Bá Wà Pẹ̀lú Àwọn Onígbàgbọ́ Ẹlẹgbẹ́ Rẹ
Tí ìwọ àti ẹlòmíràn tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi tìrẹ tí o kò mọ̀ rí bá pàdé fún ìgbà àkọ́kọ́, ǹjẹ́ o máa ń lo ìdánúṣe tìrẹ láti mọ̀ nípa ẹni yẹn dáadáa? Àbí o kàn máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́ ni? Ó yẹ kí ìfẹ́ ará sún wa láti fẹ́ mọ̀ wọ́n dáadáa. (Jòh. 13:35) Ọ̀nà wo lo lè gbà bẹ̀rẹ̀? O kàn lè sọ orúkọ rẹ kó o sì béèrè orúkọ onítọ̀hún. Bíbi í léèrè nípa bó ṣe dẹni tó rí òtítọ́ lè fa ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó lárinrin, tí yóò jẹ́ kí ẹ lè mọra dáadáa. Kódà bí ohun tó o sọ kò bá fi bẹ́ẹ̀ já gaara, ìsapá rẹ á jẹ́ kí onítọ̀hún mọ̀ pé o ka òun sí, ìyẹn gan-an ló sì ṣe pàtàkì.
Kí ló lè túbọ̀ mú kí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó jíire wáyé láàárín ìwọ àti ará ìjọ yín? Fi tọkàntọkàn fẹ́ láti mọ̀ nípa onítọ̀hún àti ìdílé rẹ̀. Ṣé ìpàdé ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ni? Sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ tó o rí kọ́. Èyí lè ṣàǹfààní fún ẹ̀yin méjèèjì. O lè mẹ́nu kan kókó kan tó wù ọ́ nínú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! ti lọ́ọ́lọ́ọ́. Kì í ṣe lọ́nà àtifi ṣe fọ́rífọ́rí o, tàbí bíi pé o fi ń dán ìmọ̀ wò. Ẹ̀mí pé o rí ohun kan tó dùn mọ́ ọ gan-an tó o fẹ́ kí wọ́n mọ̀ ni kó o fi ṣe é. Ẹ lè sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún ọ̀kan nínú yín láti ṣe ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run kí ẹ sì jọ wo ọ̀nà téèyàn lè gbà ṣe é. Ẹ sì tún lè sọ ìrírí yín lóde ẹ̀rí fúnra yín.
Dájúdájú, ìfẹ́ tá a ní sí àwọn èèyàn sábà má ń mú ká sọ̀rọ̀ nípa wọn, ìyẹn nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn. A tún lè dẹ́rìn-ín pani pàápàá. Ǹjẹ́ ohun tí a óò sọ á gbéni ró? Bí a bá fi ìmọ̀ràn inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ́kàn, tó sì jẹ́ pé ìfẹ́ bíi ti Ọlọ́run ló ń darí wa, ó dájú pé ọ̀rọ̀ wa yóò gbéni ró.—Òwe 16:27, 28; Éfé. 4:25, 29; 5:3, 4; Ják. 1:26.
Ká tó jáde lọ sóde ẹ̀rí, a máa ń múra sílẹ̀. Bákan náà, èé ṣe tá ò wá ìsọfúnni pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ sílẹ̀ tí àwa àti àwọn ọ̀rẹ́ wa lè jọ fi tàkúrọ̀ sọ? Tí o bá ka ohun kan tó dùn mọ́ ọ, tàbí tí o gbọ́ ohun kan tó dùn mọ́ ọ, fi àwọn kókó inú rẹ̀ tí o lè fẹ́ sọ fún àwọn mìíràn sọ́kàn. Láìpẹ́, wàá ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun tí o lè máa fi sọ̀rọ̀ lọ́wọ́. Ṣíṣe èyí á jẹ́ kí o ní ohun púpọ̀ láti sọ̀rọ̀ lé lórí yàtọ̀ sí kìkì àwọn nǹkan tí a máa ń ṣe déédéé lójoojúmọ́ ayé. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ǹjẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ fi ẹ̀rí hàn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣeyebíye gidigidi sí ọ!—Sm. 139:17.