ÀFIKÚN B
Ìgbà Wo Ló Yẹ Ká Dá Ìjíròrò Náà Dúró?
Tẹ́nì kan tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ bá bi wá ní ìbéèrè kan tàbí tó fẹ́ ká ṣàlàyé ohun kan tí kò yé e dáadáa, inú wa máa ń dùn láti ràn án lọ́wọ́. Àwọn “tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun” la máa ń fẹ́ wàásù fún.—Ìṣe 13:48.
Àmọ́, kí ló yẹ ká ṣe tínú bá ń bí ẹnì kan, tó kàn ń jiyàn tàbí tí kò fẹ́ bá wa sọ̀rọ̀? Ńṣe ló yẹ ká rọra dá ìjíròrò náà dúró. (Òwe 17:14) Gbìyànjú láti ṣe dáadáa sẹ́ni náà kó lè gbọ́rọ̀ wa nígbà míì.—1 Pét. 2:12.