Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ Ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ Lè Dé Inú Ọkàn
1 A lè túmọ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ sí “ṣíṣe pàṣípààrọ̀ èrò nípa ọ̀rọ̀ sísọ.” Bíbẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ lórí kókó ọ̀rọ̀ kan tí ó kan àwọn ẹlòmíràn lè fa ọkàn-ìfẹ́ wọn mọ́ra, ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà dé inú ọkàn wọn. Ìrírí ti fi hàn pè ó gbéṣẹ́ gan-an láti mú àwọn ènìyàn wọnú ìjíròrò ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́, tí ó sì tuni lára, ju láti wàásù fún wọn lọ.
2 Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ Ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́: Pé a lè jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn kò túmọ̀ sí pé a ní láti gbé àwọn èrò àti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kalẹ̀ lọ́nà tí ń wúni lórí. Ó wulẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú mímú kí ẹnì kejì bá wa sọ̀rọ̀ ni. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí a bá ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú aládùúgbò wa tí ó múlé gbè wá, kì í le gbagidi ṣùgbọ́n ó ń tuni lára. A kì í ronú nípa ọ̀rọ̀ tí a óò sọ tẹ̀ lé e ṣùgbọ́n, a ń dáhùn padà látọkànwá sí èrò tí ó sọ jáde. Fífi ojúlówó ìfẹ́ ọkàn hàn nínú ohun tí ó sọ lè fún un níṣìírí láti máa bá ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ nìṣó pẹ̀lú wa. Ohun kan náà ni ó yẹ kí ó jẹ́ òtítọ́ nígbà tí a bá ń jẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn.
3 A lè lo àwọn àkòrí bí ìwà ọ̀daràn, àwọn ìṣòro èwe, ìṣẹ̀lẹ̀ àdúgbò, àwọn ipò ayé, tàbí ojú ọjọ́ pàápàá láti bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́. Àwọn kókó ọ̀rọ̀ tí ó kan àwọn ènìyàn ní tààràtà máa ń gbéṣẹ́ gan-an ní ríru ọkàn-ìfẹ́ wọn sókè. Gbàrà tí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ bá ti bẹ̀rẹ̀, a lè fẹ̀sọ̀ yí i sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà.
4 Níní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ títuni lára kò túmọ̀ sí pé ìmúra sílẹ̀ ṣáájú kò ṣe pàtàkì. Ó ṣe pàtàkì. Ṣùgbọ́n, kò sí ìdí láti ṣètòlẹ́sẹẹsẹ èrò líle gbagidi tàbí láti kọ́ ìwàásù sórí, tí yóò yọrí sí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí kò ṣeé tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún tàbí tí kò bá àyíká ipò tí ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ mu. (Fi wé Kọ́ríńtì Kìíní 9:20-23.) Ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti múra sílẹ̀ ni láti yan ẹṣin ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ kan tàbí méjì, pẹ̀lú ète mímú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ dá lé wọn lórí. Ṣíṣàyẹ̀wò àwọn kókó ẹ̀kọ́ tí ó wà nínú ìwé Reasoning yóò ṣèrànwọ́ láti ṣe èyí.
5 Àwọn Ànímọ́ Tí Ó Ṣe Pàtàkì fún Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ Ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́: Nígbà tí a bá ń jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, a ní láti fi ọ̀yàyà àti òtítọ́ inú hàn. Ẹ̀rín músẹ́ àti inú dídùn yóò ṣèrànwọ́ láti gbé àwọn ànímọ́ wọ̀nyí yọ. A ní ìhìn iṣẹ́ tí ó dára jù lọ nínú ayé; ó ń fa àwọn aláìlábòsí ọkàn-àyà mọ́ra gan-an. Bí wọ́n bá ronú pé ìfẹ́ ọkàn olótìítọ́ inú láti ṣàjọpín ìhìn rere pẹ̀lú wọn ni ó sún wa láti ní ọkàn-ìfẹ́ nínú wọn, nígbà náà ó lè sún wọn láti fetí sílẹ̀.—2 Kọr. 2:17.
6 Jíjùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ yẹ kí ó jẹ́ ìrírí tí ń gbádùn mọ́ni. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ onínúure, kí a sì gbọ́n féfé ní sísọ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà. (Gal. 5:22; Kol. 4:6) Sakun láti fi ẹni náà sílẹ̀ pẹ̀lú èrò àtẹ̀mọ́nilọ́kàn tí ó dára. Lọ́nà yìí, bí a kò tilẹ̀ ṣàṣeyọrí nígbà àkọ́kọ́ láti dé inú ọkàn rẹ̀, ó túbọ̀ lè fetí sílẹ̀ ní ìgbà míràn tí Ẹlẹ́rìí kan bá jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
7 Bíbẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ kì í ṣe àbájáde kíkọ́ ìwàásù dídíjú. Ó wulẹ̀ jẹ́ ríru ọkàn-ìfẹ́ sókè nínú kókó ọ̀rọ̀ kan tí ó kan ẹnì kan. Níwọ̀n bí a bá ti múra sílẹ̀ ṣáájú, a óò ṣe tán nígbà náà láti mú àwọn ènìyàn wọnú ìjíròrò ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́. Ẹ jẹ́ kí a sakun láti dé inú ọkàn àwọn tí a ń bá pàdé, nípa ṣíṣàjọpín ìròyìn tí ó dára jù lọ tí a lè gbọ́, ti àwọn ìbùkún Ìjọba àìnípẹ̀kun náà, pẹ̀lú wọn.—2 Pet. 3:13.