ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lmd ẹ̀kọ́ 1
  • Sọ Ohun Táwọn Èèyàn Nífẹ̀ẹ́ Sí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sọ Ohun Táwọn Èèyàn Nífẹ̀ẹ́ Sí
  • Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Jésù Ṣe
  • Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
  • Máa Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ẹ Wẹ́rẹ́
    Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bá A Ṣe Lè Sọ Ìjíròrò Lásán Di Ìwàásù
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Bí A Ṣe Lè Mú Ọ̀nà Tí A Gbà Ń Fọ̀rọ̀ Wérọ̀ Sunwọ̀n Sí I
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò Lọ́nà Àìjẹ́-Bí-Àṣà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
Àwọn Míì
Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
lmd ẹ̀kọ́ 1

BÁ A ṢE LÈ BẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ WA

Jésù ń bá obìnrin kan sọ̀rọ̀ níbi kànga.

Jòh. 4:6-9

Ẹ̀KỌ́ 1

Sọ Ohun Táwọn Èèyàn Nífẹ̀ẹ́ Sí

Ìlànà: “Ìfẹ́ . . . kì í wá ire tirẹ̀ nìkan.”—1 Kọ́r. 13:4, 5.

Ohun Tí Jésù Ṣe

Jésù ń bá obìnrin kan sọ̀rọ̀ níbi kànga.

FÍDÍÒ: Jésù àti Obìnrin Tó Wà Níbi Kànga

1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Jòhánù 4:6-9. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  1. Kí ni Jésù kíyè sí nípa obìnrin náà kó tó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀?

  2. Jésù sọ pé: “Fún mi lómi mu.” Kí nìdí tí ọ̀nà tí Jésù gbà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ yìí fi dáa?

Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?

2. Tó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tó kan àwọn èèyàn àti ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí lo fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ, ó máa jẹ́ kí wọ́n fetí sí ẹ.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù

3. Múra láti sọ ọ̀rọ̀ míì. Má ṣe ronú pé ọ̀rọ̀ tó o ti ní lọ́kàn láti sọ náà lo gbọ́dọ̀ sọ. Ohun táwọn èèyàn ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ni kó o fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ. Bi ara ẹ pé:

  1. ‘Kí ni wọ́n ń sọ nínú ìròyìn?’

  2. ‘Kí làwọn ará àdúgbò, ará ibiṣẹ́ tàbí àwọn ọmọ iléèwé mi ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀?’

4. Máa lákìíyèsí. Bi ara ẹ pé:

  1. a. ‘Kí lẹni náà ń ṣe lọ́wọ́? Kí ló ṣeé ṣe kó máa ronú nípa ẹ̀?’

  2. b. ‘Kí ni aṣọ tó wọ̀, ìrísí ẹ̀, tàbí bí ilé ẹ̀ ṣe rí jẹ́ kí n mọ̀ nípa ẹ̀sìn tó ń ṣe tàbí àṣà ìbílẹ̀ ẹ̀?’

  3. d. ‘Ṣó yẹ kí n bá ẹni náà sọ̀rọ̀ lásìkò yìí?’

5. Máa fetí sílẹ̀.

  1. Má sọ̀rọ̀ jù.

  2. Jẹ́ kí ẹni náà sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀. Bi í ní ìbéèrè nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀.

TÚN WO

Mát. 7:12; 1 Kọ́r. 9:20-23; Fílí. 2:4; Jém. 1:19

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́