ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lmd ẹ̀kọ́ 2
  • Máa Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ẹ Wẹ́rẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ẹ Wẹ́rẹ́
  • Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Fílípì Ṣe
  • Kí La Rí Kọ́ Lára Fílípì?
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Fílípì
  • Fílípì—Ajíhìnrere Tó Nítara
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò Lọ́nà Àìjẹ́-Bí-Àṣà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Sọ Ohun Táwọn Èèyàn Nífẹ̀ẹ́ Sí
    Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Fílípì Kéde “Ìhìn Rere Nípa Jésù”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
Àwọn Míì
Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
lmd ẹ̀kọ́ 2

BÁ A ṢE LÈ BẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ WA

Ọkùnrin ará Etiópíà kan wà nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin, ó ń ka àkájọ ìwé kan, Fílípì ajínhìnrere sì ń bá a sọ̀rọ̀.

Ìṣe 8:30, 31

Ẹ̀KỌ́ 2

Máa Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ẹ Wẹ́rẹ́

Ìlànà: “Ọ̀rọ̀ tó bá . . . bọ́ sí àkókò mà dára o!”—Òwe 15:23.

Ohun Tí Fílípì Ṣe

Ọkùnrin ará Etiópíà kan wà nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin, ó ń ka àkájọ ìwé kan, Fílípì ajínhìnrere sì ń bá a sọ̀rọ̀.

FÍDÍÒ: Fílípì Wàásù fún Ìwẹ̀fà Ará Etiópíà

1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Ìṣe 8:30, 31. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  1. Báwo ni Fílípì ṣe bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀?

  2. Kí nìdí tó fi dáa gan-an bí Fílípì ṣe bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ wẹ́rẹ́, tó sì kọ́ ọkùnrin náà ní ohun tí kò mọ̀?

Kí La Rí Kọ́ Lára Fílípì?

2. Tó o bá ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ wẹ́rẹ́, ó ṣeé ṣe kí èyí mú kára tu àwọn èèyàn, kó wù wọ́n láti gbọ́rọ̀ ẹ, kí wọ́n sì bá ẹ sọ̀rọ̀.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Fílípì

3. Máa lákìíyèsí. Tó o bá ń kíyè sí bí ojú ẹnì kan ṣe rí àti ìṣesí ẹ̀, ó lè jẹ́ kó o mọ nǹkan tó pọ̀ nípa ẹni náà. Bí àpẹẹrẹ, wàá mọ̀ bóyá ó wu ẹni náà láti bá ẹ sọ̀rọ̀. Tó o bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò látinú Bíbélì, o lè béèrè pé, “Ṣó o tiẹ̀ mọ̀ pé . . . ?” Tó o bá kíyè sí pé kò wu ẹnì kan láti bá ẹ sọ̀rọ̀, má bá a sọ̀rọ̀ tipátipá.

4. Máa ní sùúrù. Má ṣe rò pé dandan ni kó o sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Dúró dìgbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, kí ọ̀rọ̀ náà lè wọlé wẹ́rẹ́. Nígbà míì, ó lè gba pé kó o ní sùúrù dìgbà míì tó o tún máa bá ẹni náà sọ̀rọ̀.

5. Múra láti yí ọ̀rọ̀ ẹ pa dà. Ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ lè sọ ohun kan tó ò retí. Torí náà, múra láti sọ ohun kan látinú Bíbélì tó máa ṣe ẹni náà láǹfààní, tó bá tiẹ̀ gba pé kó o sọ ohun tó yàtọ̀ sí èyí tó o ti ní lọ́kàn.

TÚN WO

Oníw. 3:1, 7; 1 Kọ́r. 9:22; 2 Kọ́r. 2:17; Kól. 4:6

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́