Fílípì—Ajíhìnrere Tó Nítara
ÌWÉ Mímọ́ kún fún ìtàn àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí ìgbàgbọ́ wọn ṣeé fara wé. Gbé ọ̀ràn Fílípì, Kristẹni tó jẹ́ míṣọ́nnárì ní ọ̀rúndún kìíní, yẹ̀ wò. Òun kì í ṣe àpọ́sítélì, síbẹ̀ a lò ó gan-an láti tan ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà kálẹ̀. Abájọ tí Fílípì fi di ẹni táa wá mọ̀ sí “ajíhìnrere.” (Ìṣe 21:8) Èé ṣe táa fi fún Fílípì ní àpèlé yẹn? Kí la sì lè rí kọ́ lára rẹ̀?
Fílípì fara hàn nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì kété lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Nígbà yẹn, àwọn Júù tí ń sọ èdè Gíríìkì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàròyé nípa àwọn Júù tí ń sọ èdè Hébérù, ní sísọ pé wọ́n ti gbójú fo àwọn opó àwọn nínú ọ̀ràn oúnjẹ tí wọ́n ń pín lójoojúmọ́. Láti lè yanjú ọ̀ràn náà, àwọn àpọ́sítélì yan “ọkùnrin méje tí a jẹ́rìí gbè.” Fílípì wà lára àwọn táa yàn wọ̀nyí.—Ìṣe 6:1-6.
Àwọn ọkùnrin méje wọ̀nyí jẹ́ àwọn “tí a jẹ́rìí gbè.” Ìtumọ̀ ti James Moffat sọ pé wọ́n “ní orúkọ rere.” Dájúdájú, ìgbà táa ti yàn wọ́n la ti mọ̀ pé ọkùnrin tẹ̀mí tó lè ronú jinlẹ̀ ni wọ́n. Bẹ́ẹ̀ náà làwọn tí ń sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó Kristẹni lónìí. A kì í fi ìwàǹwára yan irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀. (1 Tímótì 5:22) Wọ́n gbọ́dọ̀ ní “ẹ̀rí tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn lóde,” àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn sì ní láti mọ̀ wọ́n sí ẹni tó ń fòye báni lò, tó ní èrò inú tó yè kooro.—1 Tímótì 3:2, 3, 7; Fílípì 4:5.
Ó ṣe kedere pé, Fílípì bójú tó iṣẹ́ táa yàn fún un ní Jerúsálẹ́mù dáadáa. Ṣùgbọ́n, láìpẹ́, inúnibíni gbígbóná janjan bẹ́ sílẹ̀, ó sì fọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ká. Bíi ti àwọn yòókù, Fílípì fi ìlú náà sílẹ̀, ṣùgbọ́n iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ kò tíì parí. Kò pẹ́ tí ọwọ́ rẹ̀ fi dí fún iṣẹ́ ìwàásù ní ìpínlẹ̀ tuntun kan—Samáríà.—Ìṣe 8:1-5.
Ṣíṣí Àwọn Ìpínlẹ̀ Tuntun Sílẹ̀
Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun yóò wàásù “ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Nípa wíwàásù ní Samáríà, Fílípì ń nípìn-ín nínú mímú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ṣẹ. Ní gbogbo gbòò àwọn Júù kò ka àwọn ará Samáríà séèyàn rárá. Ṣùgbọ́n Fílípì kò ní èrò òdì nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí, jíjẹ́ ẹni tí kì í ṣe ojúsàájú sì jẹ́ ìbùkún fún un. Àní, ọ̀pọ̀ ará Samáríà lo ṣèrìbọmi, títí kan onídán tẹ́lẹ̀ rí kan, tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Símónì.—Ìṣe 8:6-13.
Nígbà tó yá, áńgẹ́lì Jèhófà darí Fílípì láti gba ọ̀nà aṣálẹ̀ tó gba Jerúsálẹ́mù lọ sí Gásà. Ibẹ̀ ni Fílípì ti rí kẹ̀kẹ́ ẹṣin kan tó gbé ìjòyè kan tó jẹ́ ará Etiopíà tí ń ka ọ̀rọ̀ láti inú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà sókè ketekete. Bí kẹ̀kẹ́ ẹ̀ṣin náà ti ń lọ ni Fílípì ń sáré tẹ̀ lé e, bẹ́ẹ̀ ló bá bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ará Etiópíà yìí jẹ́ aláwọ̀ṣe, tó sì ní ìmọ̀ díẹ̀ nípa Ọlọ́run àti Ìwé Mímọ́, ó fi ìrẹ̀lẹ̀ gbà pé òun ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ láti lóye ohun tí òun ń kà. Nítorí náà, ó ní kí Fílípì gòkè sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin òun, kó sì jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ òun. Lẹ́yìn tí Fílípì jẹ́rìí fún un, wọ́n dé ibi tí àgbájọpọ̀ omi wà. Ni ará Etiópíà náà bá béèrè pé, “Kí ni ó dí mi lọ́wọ́ dídi ẹni tí a batisí?” Kíá ni Fílípì batisí rẹ̀, tayọ̀tayọ̀ sì ni ará Etiópíà náà fi ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ. Ó ṣeé ṣe kí ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn yìí ti tan ìhìn rere kálẹ̀ ní ìlú rẹ̀.—Ìṣe 8:26-39.
Kí la lè rí kọ́ lára iṣẹ́ òjíṣẹ́ Fílípì tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ará Samáríà àti ìjòyè tó jẹ́ ará Etiópíà? Ẹ má ṣe jẹ́ ká ní in lọ́kàn láé pé àwọn ará orílẹ̀-èdè kan, ẹ̀yà kan, tàbí àwọn tó wà ní ipò kan kò ní fẹ́ gbọ́ ìhìn rere náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ polongo ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà fún “ènìyàn gbogbo.” (1 Kọ́ríńtì 9:19-23) Báa bá yọ̀ǹda ara wa láti wàásù fún ènìyàn gbogbo, Jèhófà lè lò wá nínú iṣẹ́ ‘sísọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn’ kí òpin ètò àwọn nǹkan burúkú yìí tó dé.—Mátíù 28:19, 20.
Àwọn Àǹfààní Mìíràn Tí Fílípì Ní
Lẹ́yìn tó ti wàásù fun ìjòyè tó jẹ́ ará Etiópíà, Fílípì jẹ́rìí ní Áṣídódì, “ó sì la ìpínlẹ̀ náà já, ó sì ń bá a nìṣó ní pípolongo ìhìn rere fún gbogbo àwọn ìlú ńlá títí ó fi dé Kesaréà.” (Ìṣe 8:40) Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn Kèfèrí tó ń gbé ní àwọn ìlú ńlá méjì wọ̀nyí pọ̀ gan-an. Nígbà tí Fílípì ń lọ sí Kesaréà, ó ṣeé ṣe kó ti wàásù ní àwọn ibi tí àwọn Júù pọ̀ sí, irú bíi Lídà àti Jópà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdí nìyẹn tí a fi wá rí àwọn ọmọ ẹ̀yìn lágbègbè yẹn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.—Ìṣe 9:32-43.
Nǹkan bí ogún ọdún lẹ́yìn ìgbà náà la mẹ́nu kan orúkọ Fílípì gbẹ̀yìn. Ní òpin ìrìn àjò míṣọ́nnárì kẹta tí Pọ́ọ̀lù rìn, ó fẹsẹ̀ kàn yà ní Tólémáísì. Alábàákẹ́gbẹ́ Pọ́ọ̀lù lẹ́nu ìrìn àjò, ìyẹn Lúùkù, sọ pé: “Ní ọjọ́ kejì, a mú ọ̀nà wa pọ̀n, a sì dé Kesaréà, a sì wọ ilé Fílípì ajíhìnrere.” Nígbà tó fi máa di àsìkò yìí, Fílípì ti ní “ọmọbìnrin mẹ́rin, wúńdíá, tí wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀.”—Ìṣe 21:8, 9.
Ó hàn gbangba pé, Fílípì ti ń gbé ní Kesaréà. Ṣùgbọ́n ẹ̀mí míṣọ́nnárì tó ní ṣì wà lára rẹ̀, nítorí Lúùkù pè é ní “ajíhìnrere.” Ọ̀rọ̀ yìí sábà máa ń tọ́ka sí ẹnì kan tó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀ láti lọ wàásù ìhìn rere ní àwọn àgbègbè tí iṣẹ́ náà kò tí ì dé. Òtítọ́ náà pé Fílípì ní ọmọbìnrin mẹ́rin tí ń sọ tẹ́lẹ̀ fi hàn pé wọ́n mú ìtara baba wọn.
Ó yẹ kí àwọn Kristẹni òbí lóde ìwòyí rántí pé àwọn ọmọ wọn ni ọmọ ẹ̀yìn wọn tó ṣe pàtàkì jù lọ. Àní bó bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ yóò ní láti fi àwọn àǹfààní kan tó jẹ́ ti ètò ìjọba Ọlọ́run sílẹ̀ nítorí ẹrù ìdílé, bíi ti Fílípì wọ́n ṣì lè jẹ́ ìránṣẹ́ tí ń fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run, kí wọ́n sì jẹ́ òbí àwòfiṣàpẹẹrẹ.—Éfésù 6:4.
Ìbẹ̀wò tí Pọ́ọ̀lù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ṣe sí ìdílé Fílípì fún ìdílé náà láǹfààní ńláǹlà láti fi aájò àlejò hàn. Tọ̀túntòsì wọn á mà ti gbádùn ìṣírí tó ga o! Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àkókò yìí ni Lúùkù ṣàkójọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìgbòkègbodò Fílípì, tó wá fi kún Ìṣe orí kẹfà àti ìkẹjọ nígbẹ̀yìngbẹ́yín.
Jèhófà Ọlọ́run lo Fílìpì dáadáa láti mú ire Ìjọba náà tẹ̀ síwájú. Ìtara Fílípì mú kó ṣeé ṣe fún un láti tan ìhìn rere náà kálẹ̀ ní àwọn ìpínlẹ̀ tuntun, ó sì jẹ́ kí ilé rẹ̀ jẹ́ ibi tí wọn kì í ti í fi nǹkan tẹ̀mí ṣeré. Ìwọ yóò ha fẹ́ gbádùn irú àǹfààní àti ìbùkún bẹ́ẹ̀ bí? Nígbà náà, yóò dára bóo bá lè fara wé àwọn ànímọ́ tí Fílípì ajíhìnrere fi hàn.