ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 7/15 ojú ìwé 21-23
  • Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Dídán Mọ́rán—Àṣírí Ìgbéyàwó Aláṣeyọrí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Dídán Mọ́rán—Àṣírí Ìgbéyàwó Aláṣeyọrí
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Dídán Mọ́rán Ń Béèrè
  • Àwọn Ohun Tí Ń Dènà Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Dídán Mọ́rán
  • Bí A Ṣe Lè Mú Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Dídán Mọ́rán Dàgbà
  • Jijumọsọrọpọ Laaarin Idile ati Ninu Ijọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ẹ máa bá ara yín sọ̀rọ̀ kẹ́ ẹ lè túbọ̀ ṣera yín lọ́kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Mú Kí Ìgbéyàwó Rẹ Jẹ́ Ìsopọ̀ Wíwàpẹ́títí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àwọn Ohun Tó Lè Mú Kí Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Máa Lọ Déédéé Láàárín Tọkọtaya
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 7/15 ojú ìwé 21-23

Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Dídán Mọ́rán—Àṣírí Ìgbéyàwó Aláṣeyọrí

Ní 1778, Robert Barron ṣe àgádágodo kan tó lójú méjì tó wá di ìpìlẹ̀ fún àwọn àgádágodo tí a ń lò lóde òní. Ọ̀nà tí ó gbà ṣe é ni pé ẹyọ kọ́kọ́rọ́ kan ṣoṣo ni yóò ṣí ojú méjèèjì pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà.

BÁKAN náà, ìgbéyàwó kan tó jẹ́ aláṣeyọrí wà lọ́wọ́ ọkọ àti aya tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan. Ohun kan tó pọndandan tí ọwọ́ ẹni fi lè tẹ ayọ̀ oníyebíye tó wà nínú ìgbéyàwó rere, kí a sì ní ìrírí rẹ̀ ni ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ dídán mọ́rán.

Ohun Tí Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Dídán Mọ́rán Ń Béèrè

Kí ni ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ dídán mọ́rán ń béèrè? Ìwé atúmọ̀ èdè kan túmọ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ bíi “gbígbin èrò, ìmọ̀ràn, tàbí ìsọfúnni síni lọ́kàn tàbí fífèròwérò nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu, ìwé kíkọ, tàbí fífi ara ṣàpèjúwe.” Ohun tí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ wá ní nínú nígbà náà ni ṣíṣàjọpín ìmọ̀ àti èrò. Àti pé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ dídán mọ́rán ní í ṣe pẹ̀lú àwọn nǹkan tí ń gbéni ró, tí ń tuni lára, àwọn ohun tó dára, tó yẹ fún ìyìn, tó sì ń tuni nínú.—Éfésù 4:29, 32; Fílípì 4:8.

Àwọn ohun tí ń mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dán mọ́rán ṣeé ṣe ni níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹni, fífọkàn tánni, àti kí tọ̀tún tòsì gbọ́ra wọn yé. Ìgbà tí a bá fojú àjọṣepọ̀ títí ayé wo ìgbéyàwó tí a sì ti pinnu pátápátá láti mú kí o ṣeé ṣe ni àwọn ànímọ́ wọ̀nyí máa ń yọjú. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí irú àjọṣepọ̀ bẹ́ẹ̀, aláròkọ ní ọ̀rúndún kejìdínlógún nì, Joseph Addison, kọ̀wé pé: “Àwọn ẹni méjì tí wọ́n yan ara wọn láàárín gbogbo èèyàn tó wà láyé, tí wọ́n pinnu láti máa tu ara wọn nínú, kí wọ́n sì máa múnú ara wọn dùn, ti tipa bẹ́ẹ̀ so ara wọn pọ̀ láti máa bára wọn ṣàwàdà, láti máa fi ìwà pẹ̀lẹ́ bá ara wọn lò, kí wọ́n máa fọgbọ́n gbé pọ̀, kí wọ́n máa dárí ji ara wọn, kí wọ́n máa mú sùúrù fúnra wọn, kínú wọn sì máa dùn síra wọn, pàápàá nígbà tọ́ràn bá kan ìkùdíẹ̀-káàtó àti àìpé ẹnì kejì wọn, èyí ni wọn óò máa fẹ́ láti ṣe, títí dé òpin ìgbésí ayé wọn.” Irú ìrẹ́pọ̀ bẹ́ẹ̀ á mà kún fún ayọ̀ o! Àwọn ànímọ́ ṣíṣeyebíye wọ̀nyí lè ṣe ìgbéyàwó rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, nítorí pé wọ́n lè jẹ́ tìrẹ nípasẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dán mọ́rán.

Àwọn Ohun Tí Ń Dènà Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Dídán Mọ́rán

Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tọkọtaya ló ń kó wọnú ìgbéyàwó pẹ̀lú ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára, kódà tí inú wọn máa ń dùn kọjá ààlà. Àmọ́, kì í pẹ́ tí ayọ̀ tí ọ̀pọ̀ ní fi ń lọ, tí ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára tí wọ́n ní yóò sì pòórá. Ìbànújẹ́ kíkorò tí ń máyé súni, ìbínú, ìkóguntini, kódà ìkórìíra tó lé kenkà lè wá dípò ìdánilójú tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀. Ìgbéyàwó náà yóò wá di ọ̀ràn ká ṣáà máa fara dà á “títí ikú yóò fi yà wá.” Láti lè wá mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ dídán mọ́rán tó pọndandan fún ìgbéyàwó rere sunwọ̀n sí i tàbí kó máa bá a lọ, àwọn ìdènà kan wa tí a gbọ́dọ̀ sẹ́pá.

Ohun kan tó dájú pé ó ń dènà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dán mọ́rán ni ìbẹ̀rù nípa irú ọkàn tí ọkọ̀ tàbí aya ẹni fi máa gba àwọn ìsọfúnni kan tàbí bí yóò ṣe hùwà báa bá sọ ohun tó wà lọ́kàn wa jáde. Fún àpẹẹrẹ a lè máa bẹ̀rù pé ọkọ tàbí aya ẹni lè ṣáni tì lẹ́yìn mímọ̀ pé àbùkù kan fẹ́ wà lára wa. Báwo lèèyàn ṣe máa ṣàlàyé fún ẹnì kejì rẹ̀ pé nǹkan kan tí òun fẹ́ ṣe yóò yí ìrísí òun padà gan-an tàbí pé kò ní jẹ́ kí òun lágbára mọ́? Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ aláìlábòsí àti ìpinnu tí a ronú jinlẹ̀ ṣe fún ọjọ́ iwájú pọndandan ní irú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀ jú ti ìgbàkigbà rí lọ. Fífọ̀rọ̀ ẹnu mú un dáni lójú pé a ó máa nífẹ̀ẹ́ ẹni nìṣó àti pé ìkẹ́ni nígbà gbogbo kò ní dẹ́kun yóò fi ìfẹ́ táa ní hàn, èyí tí yóò mú kí a ní ìgbéyàwó tí ń tẹ́ni lọ́rùn nítòótọ́. Ó yẹ kó jẹ́ pé inú ìgbéyàwó ní òwe yìí ti gbéṣẹ́ jù lọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”—Òwe 17:17.

Ìkórìíra tún jẹ́ ìdènà mìíràn fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ dídán mọ́rán. A sábà máa ń sọ ọ́ lọ́nà tó báa mu wẹ́kú pé ìgbéyàwó aláyọ̀ jẹ́ ìsopọ̀ ẹni méjì tí ń dárí jira wọn dáadáa. Láti bá àpèjúwe yẹn mu, àwọn tọkọtaya yóò sa gbogbo ipá wọn láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn wíwúlò ti Pọ́ọ̀lù fúnni pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú.” (Éfésù 4:26) Fífi ìmọ̀ràn yìí sílò dípò mímú ìbínú àti ìkórìíra dàgbà ń béèrè pé kí a fi ìrẹ̀lẹ̀ jùmọ̀ sọ̀rọ̀. Àwọn tọkọtaya tí ìgbéyàwó wọ́n dára kì í fìgbà gbogbo gba ìbínú, ṣíṣaáwọ̀, àti dídi kùnrùngbùn láyè. (Òwe 30:33) Wọ́n ń wá ọ̀nà láti fara wé Ọlọ́run, tí kì í dini sínú. (Jeremáyà 3:12) Ní tòótọ́, wọ́n ń dárí ji ara wọn láti ọkàn wá.—Mátíù 18:35.

Ohun tó jẹ́ olórí ìdènà fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ èyíkéyìí ni dídì kunkun. Èyí lè jẹ́ fífajúro, mímí kanlẹ̀ hìn-ìn, fífi ohun téèyàn mọ̀ pó dáa ní ṣíṣe sílẹ̀ láìṣe, àti kí ẹni kan máa bá ẹnì kejì rẹ̀ yodì. Ọkọ tàbí aya tó bá ń hùwà lọ́nà yìí ń fi hàn pé inú òun kò dùn. Àmọ́, sísọ ìmọ̀lára ẹni jáde láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, kí a sì sọ ọ́ lọ́nà tó dùn mọ́ni ń ṣe púpọ̀ nínú mímú kí ìgbéyàwó sunwọ̀n sí i ju kí ẹnì kan máa dì kunkun, kó sì máa fajúro.

Àìfetísílẹ̀ dáadáa tàbí kí a má fetí sílẹ̀ rárá nígbà tí ọkọ tàbí aya ẹni bá ń sọ̀rọ̀ tún jẹ́ ìdènà kàn tí a ní láti sẹ́pá kí a baà lè ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dán mọ́rán nínú ìgbéyàwó. Bóyá ó rẹ̀ wá púpọ̀ tàbí kó kàn jẹ́ pé ṣe ni ọwọ́ wa kódí jù tí a kò fi rí àyè fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí ọkọ wa tàbí aya wa ń sọ dáadáa. Àríyànjiyàn lè wá ṣẹlẹ̀ lórí ètò kan tí ẹni kan rò pé ọkọ tàbí aya òun ti lóye rẹ̀ dáradára àmọ́, tí ẹnì kejì wáá kọ̀ délẹ̀ pé ṣe ni òun ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbọ́ nípa rẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́. Láìsí àní-àní, àìsí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ dídán mọ́rán ló ń fa irú ìṣòro bẹ́ẹ̀.

Bí A Ṣe Lè Mú Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Dídán Mọ́rán Dàgbà

Ó mà ṣe pàtàkì láti wá àkókò fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ onífẹ̀ẹ́, tó dán mọ́rán o! Àwọn kan máa ń lo àkókò tó pọ̀ gan-an nídìí tẹlifíṣọ̀n tí wọ́n a máa wo ìgbésí ayé àwọn ẹlòmíràn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọn kò ní fi bẹ́ẹ̀ ní àkókò fún ìgbésí ayé tara wọn. Nítorí náà, pípa tẹlifíṣọ̀n sábà máa ń jẹ́ ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ tó pọndandan fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dán mọ́rán.

Bó ti wù kó rí, bí àkókò tó tọ́ láti sọ̀rọ̀ ṣe wà, bẹ́ẹ̀ náà ni àkókò àtidákẹ́ tún wà pẹ̀lú. Ọkùnrin ọlọ́gbọ́n náà sọ pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, . . . ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀.” Ní tòótọ́, àwọn ọ̀rọ̀ yíyẹ tún wà láti sọ. Òwe náà sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tí ó sì bọ́ sí àkókò mà dára o!” (Oníwàásù 3:1, 7; Òwe 15:23) Nítorí náà, pinnu ìgbà tó dára jù lọ láti sọ kókó ọ̀rọ̀ rẹ tàbí láti sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ jáde. Bi ara rẹ̀ léèrè pé: ‘Ṣé ó ti rẹ ọkọ mi tàbí aya mi ni tàbí ara rẹ̀ silẹ̀, tí ọkàn rẹ̀ sì tú ká báyìí? Ṣé kókó tí mo fẹ́ sọ kò lè mú kí ó gbaná jẹ? Àwọn ọ̀rọ̀ wo ni mo lò lọ́jọ́sí nígbà táa sọ̀rọ̀ yìí kẹ́yìn, tí kò bá ọkọ tàbí aya mi lára mú?’

Ó dáa kí a rántí pé àwọn ènìyàn máa ń fi ìṣarasíhùwà tó dára jù lọ hàn nígbà tí wọ́n bá rí i pé fífọwọ́sowọ́pọ̀ àti fífara mọ́ ohun kan tí a béèrè fún yóò ṣàǹfààní fún wọn. Bí àwọn èdè àìyédè kan bá ti wà láàárín tọkọtaya, ohun kan lè sún ọ̀kan nínú wọn sọ pé, “Nǹkankan ti ń dà mí láàmú, ìsinsìnyí gan-an la sì máa wá nǹkan ṣe sí i!” Ó dajú pé, bí ipò nǹkan bá ṣe rí ni yóò pinnu irú ọ̀rọ̀ tó yẹ ká lò, ṣùgbọ́n ì bá dára jù kí a sọ ọ́ lọ́nà yìí pé, “Onítèmi, mo ti ń ronú lórí ọ̀rọ̀ táa jíròrò rẹ̀ yẹn àti báa ṣe le wá nǹkan ṣe sí i.” Ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ wo ní ọkọ tàbí aya rẹ yóò nífẹ̀ẹ́ sí jù?

Dájúdájú, bí a ṣe sọ nǹkan ṣe pàtàkì púpọ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn.” (Kólósè 4:6) Gbìyànjú láti jẹ́ kí ohùn tí o fi ń sọ̀rọ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ tí o ń sọ jẹ́ èyí tó kún fún oore ọ̀fẹ́. Ní in lọ́kàn pé, “àwọn àsọjáde dídùnmọ́ni jẹ́ afárá oyin, ó dùn mọ́ ọkàn, ó sì ń mú àwọn egungun lára dá.”—Òwe 16:24.

Fún àwọn tọkọtaya kan, jíjùmọ̀ ṣiṣẹ́ lórí ohun ìdáwọ́lé kan nínú ilé lè jẹ́ ọ̀nà kan tó dára jù lọ láti máa jùmọ̀ sọ̀rọ̀. Irú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ bẹ́ẹ̀ lè mú kí àjọṣe sunwọ̀n sí i, kó sì tún fún wọn ní àkókò láti máa ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dán mọ́rán. Fún àwọn tọkọtaya mìíràn, àkókò tí àwọn méjèèjì nìkan jọ wà papọ̀, tí ọwọ́ wọn sì dilẹ̀ ló jẹ́ àkókò tó sàn jù, tó sì tún rọrùn jù fún wọn láti ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dán mọ́rán.

Ẹ̀kọ́ púpọ̀ la tún lè kọ́ nípa ṣíṣàkíyèsí bí àwọn tọkọtaya tí àjọṣepọ̀ wọn dára ṣe ń jùmọ̀ sọ̀rọ̀. Kí ló mú kí ọ̀rọ̀ wọn rí bẹ́ẹ̀? Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, ó ní láti jẹ́ pé ìsapá ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, sùúrù, àti ìgbatẹnirò onífẹ̀ẹ́ ló yọrí sí irú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ tó tún yọrí sí ọ̀nà oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí wọ́n fi ń bára wọn sọ̀rọ̀. Ó ni láti jẹ́ pé àwọn pàápàá ti kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀kọ́, nítorí pé ìgbéyàwó rere kì í ṣàdédé wà. Wo bó ti ṣe pàtàkì tó nígbà náà láti gbé ojú ìwòye ọkọ tàbí aya rẹ yẹ̀ wò, kí o má ṣe fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn àìní rẹ̀, kí o sì ṣẹ́pá àwọn ipò tí kò fara rọ nípa sísọ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n. (Òwe 16:23) Bí o bá ti ṣègbéyàwó, ṣiṣẹ́ lórí bí o ṣe lè di ẹni tí ìbágbé rẹ̀ gbádùn, tó sì rọrùn láti bẹ̀. Ó dájú pé ìyẹn yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ púpọ̀ láti jẹ́ kí ìgbéyàwó rẹ jẹ́ èyí tó dára.

Jèhófà fẹ́ kí àwọn ènìyàn gbádùn ìgbéyàwó tó láyọ̀ tó sì wà pẹ́ títí. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18, 21) Àmọ́, àṣírí náà wà lọ́wọ́ àwọn méjèèjì tí wọ́n gbéra wọn níyàwó. Bí ìgbéyàwó yóò bá yọrí sí rere, àwọn ẹni méjì tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn gbọ́dọ̀ ṣe tán láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti mọ ọ̀nà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dán mọ́rán lámọ̀dunjú.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Pípa tẹlifíṣọ̀n túbọ̀ ń fi àyè sílẹ̀ fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ dídán mọ́rán ń ṣèrànwọ́ láti pọkàn pọ̀ nínú ìfẹ́ pípẹ́ títí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́