Jijumọsọrọpọ Laaarin Idile ati Ninu Ijọ
“Ẹ jẹ ki asọjade ọrọ yin maa jẹ́ pẹlu oore ọ̀fẹ́ nigba gbogbo, ti a fi iyọ dun.”—KOLOSE 4:6, NW.
1. Ki ni Adamu sọ nigba ti Ọlọrun fi Efa han an?
“ẸNI KAN kii jẹ erekuṣu . . . Olukuluku eniyan jẹ abala àgbáálá ilẹ.” Bẹẹ ni ọmọwe ọkunrin alakiyesi kan kọwe ni awọn ọgọrun un ọdun melookan sẹhin. Ni sisọ iyẹn, oun wulẹ ńgbe ohun ti Ẹlẹdaa sọ nipa Adamu lẹhin pe: “Kò dara ki ọkunrin naa ki o nikan maa gbe.” Adamu ni ẹbun ọrọ sisọ ati ede, nitori pe oun ti sọ gbogbo awọn ẹranko ni orukọ. Ṣugbọn Adamu ko ni ẹda eniyan kankan miiran ti oun le jumọsọrọpọ pẹlu rẹ̀. Abajọ ti o fi jẹ pe nigba ti Ọlọrun fi Efa òrékelẹ́wà hàn án gẹgẹ bi aya rẹ̀, ó polongo pe: “Eyi yii ni egungun ninu egungun mi, ati ẹran-ara ninu ẹran-ara mi”! Nipa bayii, bi idile eniyan akọkọ ti ni ibẹrẹ rẹ̀, Adamu bẹrẹ sii ni ijumọsọrọpọ pẹlu ẹda ẹlẹgbẹ rẹ̀.—Jẹnẹsisi 2:18, 23.
2. Ipalara wo ni o le jẹyọ lati inu wiwo tẹlifiṣọn ni àwòjù?
2 Agbo idile jẹ ibi ti o dara julọ fun ijumọsọrọpọ. Nitootọ, aṣeyọri si rere igbesi-aye idile gan an sinmi lori rẹ. Bi o ti wu ki o ri, lati jumọsọrọpọ gba akoko ati isapa. Lonii, ọkan lara awọn ole akoko ti o gbówọ́ julọ ni tẹlifiṣọn. Ó lè jẹ́ ohun eelo fun ipalara ó kere tan ni ọna meji. Lakọọkọ, o le jẹ́ afanimọra gan an debi pe awọn mẹmba idile di olukẹra wọn bajẹ pẹlu rẹ̀, ni yiyọrisi ọ̀dá ijumọsọrọpọ. Ni ọwọ keji ẹwẹ, tẹlifiṣọn le ṣiṣẹ gẹgẹ bi ọna atiyọ kan nigba ti edekoyede tabi imọlara ibanujẹ bá wà. Dipo yiyanju awọn iṣoro, awọn olujọṣegbeyawo kan ti yàn lati fọwọ́lẹ́rán ki wọn si maa wo tẹlifiṣọn. Nitori naa apoti tẹlifiṣọn le dakun aini ijumọsọrọpọ daadaa, eyi ti a sọ pe ó jẹ́ ohun akọkọ ti ńtú idile ká. Awọn wọnni ti wọn ni iṣoro ti pipa tẹlifiṣọn wíwò mọ́ sabẹ akoso le ronu nipa wíwá ibi pa á tì sí.—Matiu 5:29; 18:9.
3. Bawo ni awọn kan ṣe janfaani nipa dídín tẹlifiṣọn wiwo kù?
3 Nitootọ, awọn irohin arunisoke ni a ti ri gba nipa awọn ibukun ti njẹyọ nigba ti a ba din ìlò tẹlifiṣọn kù tabi ti a bá wá ibi pa á tì sí. Idile kan kọwe pe: “A nba araawa sọrọ pupọ sii . . . , a tubọ nṣe iwadii Bibeli sii . . . A nta ayo papọ . . . Gbogbo ẹka iṣẹ-isin pápá wa ti pọ sii.” Idile miiran sọ lẹhin ti wọn ti kógbá tẹlifiṣọn wọn nilẹ pe: “Kii ṣe pe a ntọju owo nikan ni [wọn ti ṣe asansilẹ-owo fun cable T.V.] ṣugbọn a ti tubọ sunmọra pẹkipẹki bi idile kan a si ti ri ọpọlọpọ awọn ohun yiyẹ miiran lati ṣe pẹlu akoko wa. Ko sú wa rárá.”
Wíwò, Sisọrọ, ati Fifetisilẹ
4. Bawo ni awọn tọkọtaya alarede ṣe le jumọ sọ imọriri wọn fun araawọn?
4 Oriṣiriṣi ọna ijumọsọrọpọ ni o wà laaarin idile. Awọn kan jẹ eyi ti a ko fẹnusọ. Nigba ti awọn meji ba wulẹ wo araawọn, o jẹ ọna ijumọsọrọpọ kan. Wiwa papọ le tàtaré oye imọlara pe a bikita nipa ẹni. Tọkọtaya nilati yẹra fun fifi araawọn silẹ fun awọn saa akoko gigun ayafi bi idi ti ko ṣee yẹsilẹ bá wà. Awọn tọkọtaya alarede le mú imọlara ayọ dagba ninu araawọn nipa gbigbadun ibakẹgbẹ timọtimọ ti wọn ni laaarin ide igbeyawo naa. Nipa ọna ifẹni sibẹ ti o si kun fun ọwọ ti wọn ngba huwa si araawọn, yala ni gbangba tabi nikọkọ, fifi iyi títọ́ han ninu aṣọ wiwọ ati ọna ihuwa, wọn le ta àtaré imọriri jijinlẹ si araawọn pẹlu idakẹjẹẹ. Ọlọgbọn Ọba Solomoni sọ ọ lọ́rọ̀, ni wiwi pe: “Jẹ ki orisun rẹ ki o ni ibukun: ki iwọ ki o si maa yọ tiwọ ti aya igba ewe rẹ.”—Owe 5:18.
5, 6. Eeṣe ti awọn ọkọ fi gbọdọ mọ̀ nipa ijẹpataki jijumọsọrọpọ pẹlu awọn aya wọn?
5 Ijumọsọrọpọ tun beere fun ibanisọrọpọ, ifọrọwerọ—ni biba ara ẹni sọrọ, kii ṣe sisọrọ kòbákùngbé si ara ẹni. Nigba ti o jẹ pe awọn obinrin kan san ju awọn ọkunrin lọ ninu sisọ imọlara wọn jade, ko si awawi kankan fun awọn ọkọ lati jẹ alailagbaja ọrọ sisọ. Awọn Kristẹni ọkọ nilati mọ pe aini ijumọsọrọpọ jẹ olori iṣoro ninu ọpọlọpọ igbeyawo, ati nitori naa wọn nilati ṣiṣẹ kára ni pipa ọna ijumọsọrọpọ mọ ni ṣiṣi silẹ. Nitootọ, wọn yoo ṣe eyi, bi awọn pẹlu awọn aya wọn, ba kọbiara si imọran rere tí apọsiteli Pọọlu fifunni ni Efesu 5:25-33. Fun ọkọ kan lati nifẹẹ aya rẹ̀ gẹgẹ bi ara oun tikaraarẹ, oun nilati daniyan nipa wiwa alaafia ati ayọ rẹ̀, kii ṣe kiki tirẹ funraarẹ nikan. Lati ṣaṣepari iyẹn, ijumọsọrọpọ jẹ koṣeemani.
6 Ọkọ kan ko nilati ni ẹmi-ironu naa pe aya rẹ nilati fura tabi mefo pe oun mọriri rẹ̀. O nilati mu ifẹ rẹ̀ fún un dá a loju. Oun le fi imọriri rẹ̀ han ni ọpọlọpọ ọna—nipa awọn ọrọ ifẹ ati awọn ẹbun airotẹlẹ, ati nipa fifi awọn ọran ti o le nipa lori rẹ̀ tó o leti ni kikun. Ipenija ti sisọ imọriri jade fun awọn isapa aya rẹ̀ wa pẹlu, ibaa ṣe ninu ọna ti ó gbà ṣe araarẹ loge, iṣẹ aṣekara rẹ̀ nititori idile naa, tabi ninu itilẹhin ti ó nfi tinutinu ṣe fun awọn igbokegbodo nipa tẹmi. Ni afikun, fun ọkọ kan lati kọbiara si imọran apọsiteli Peteru ni 1 Peteru 3:7, lati ‘ba a gbé gẹgẹ bi imọ,’ oun gbọdọ ni igbatẹniro, eyi ti a fihan nipa jijumọsọrọpọ pẹlu rẹ̀ ninu gbogbo ọran ti o kan tọtuntosi, ni bibu ọla fún un gẹgẹ bi ohun eelo ti ko lagbara.—Owe 31:28, 29.
7. Iṣẹ aigbọdọmaṣe wo ni aya ni lati jumọsọrọpọ pẹlu ọkọ rẹ?
7 Bakan naa, fun aya kan lati kọbiara si imọran nipa itẹriba ni Efesu 5:22-24, o nilati daniyan fun pipa ọna ijumọsọrọpọ mọ ni ṣiṣi silẹ pẹlu ọkọ rẹ̀. Oun nilati fi “ọwọ jijinlẹ” fun ọkọ rẹ̀, nipa ọrọ rẹ̀ ati nipa iwa rẹ̀. Oun ko nilati gbegbeesẹ laifọranlọ ọ tabi ṣá ifẹ ọkan rẹ̀ tì. (Efesu 5:33) Nigba gbogbo, ọrọ aṣiri nilati wa laaarin rẹ̀ ati ọkọ rẹ̀.—Fiwe Owe 15:22.
8. Lati pa ila ijumọsọrọpọ mọ ni ṣiṣi silẹ, ki ni awọn aya gbọdọ muratan lati ṣe?
8 Siwaju sii, aya kan nilati ṣora fun fifarada ijiya nikọkọ gẹgẹ bi ifihan ìkáàánú ara ẹni. Bi edekoyede kan ba wà, jẹ ki o wá akoko ti o yẹ lati mu un wa si afiyesi. Bẹẹni, kẹkọọ lara Ẹsiteri Ayaba. Oun ni ọran iku ati iye kan lati mu wa si afiyesi ọkọ rẹ̀. Igbegbeesẹ lọgan rẹ̀ pẹlu ọgbọn ati ijafafa tumọ si igbala fun awọn Juu. O dọwọ awa funraawa ati awọn alabaaṣegbeyawo wa lati jumọsọrọpọ bi a ba ti mu wa binu tabi ti a nmu wa binu. Ọgbọn ẹwẹ ati ẹmi awada oniwa bi Ọlọrun le mu ki ijumọsọrọpọ rọrun sii.—Ẹsiteri 4:15–5:8.
9. Ipa wo ni fifetisilẹ kó ninu ijumọsọrọpọ?
9 Ohun ti lilo ọrọ lati mu ki ila ijumọsọrọpọ wà ni ṣiṣi silẹ ní ninu ni aigbọdọmaṣe ẹnikọọkan lati fetisilẹ si ohun ti ẹlomiran ní lati sọ—ati lati ṣe isapa lati ṣakiyesi ohun ti a nilọkan laisọ. Iyẹn beere fun fifiyesilẹ si ẹni ti nsọrọ. Kii ṣe kiki pe ẹnikan nilati foye mọ ero ohun ti a sọ niti gidi ṣugbọn ẹnikan tun nilati fiyesi imọlara ti ọrọ naa gbeyọ, ọna ti a gba sọ ohun kan. O saba maa njẹ pe o ku diẹ ki a to fun ọkọ kan ni agbegbe yii. Awọn aya le jiya nitori pe awọn ọkọ kuna lati fetisilẹ. Awọn aya ni iha ọdọ tiwọn sì nilati fetisilẹ daradara ki wọn lè yẹra fun sisare de ipari ero. “Ọlọgbọn yoo gbọ́, yoo si maa pọ sii ni ẹkọ.”—Owe 1:5.
Ijumọsọrọpọ Laaarin Awọn Obi ati Ọmọ
10. Lati ri iyọrisi didara julọ ninu jijumọsọrọpọ pẹlu awọn ọmọ wọn, ki ni awọn obi gbọdọ muratan lati ṣe?
10 Ipo kan tun wà nibi ti awọn obi ati awọn ọmọ wọn ti ní iṣoro ninu ijumọsọrọpọ. Lati “tọ́ ọmọde ni ọna ti yoo tọ̀” beere fun gbigbe ọna ijumọsọrọpọ kalẹ. Ṣiṣe bẹẹ yoo ṣeranlọwọ lati mu un daju pe ‘nigba ti o ba dagba tan, ki yoo kuro ninu rẹ̀.’ (Owe 22:6) Otitọ naa pe awọn obi kan padanu ọmọ wọn sinu aye niiṣe nigbamiran pẹlu alafo ijumọsọrọpọ ti o jẹyọ lakooko ọdọlangba. Iṣẹ aigbọdọmaṣe awọn obi lati jumọsọrọpọ lemọlemọ pẹlu awọn ọmọ wọn ni a tẹnumọ ni Deutaronomi 6:6, 7: “Ati ọrọ wọnyi, ti mo palaṣẹ fun ọ ni oni, ki o maa wà ni aya rẹ: ki iwọ ki o si maa fi wọn kọ́ awọn ọmọ rẹ gidigidi, ki iwọ ki o si maa fi wọn ṣe ọrọ sọ nigba ti iwọ ba jokoo ninu ile rẹ, ati nigba ti iwọ ba nrin ni ọna, ati nigba ti iwọ ba dubulẹ, ati nigba ti iwọ ba dide.” Bẹẹni, awọn obi gbọdọ lo akoko pẹlu awọn ọmọ wọn! Wọn gbọdọ muratan lati ṣe awọn irubọ nititori awọn ọmọ wọn.
11. Ki ni diẹ lara awọn ohun ti awọn obi nilati ba awọn ọmọ wọn sọ?
11 Ẹyin obi, ẹ sọ fun awọn ọmọ yin pe Jehofa nifẹẹ wọn ati pe ẹyin pẹlu nifẹẹ wọn. (Owe 4:1-4) Ẹ jẹ ki wọn ri imuratan yin lati fi idẹrun ati faaji rubọ fun idagba wọn niti ero ori, ero imọlara, ara ìyára, ati tẹmi. Ifọranrora-ẹni ṣe pataki ni ọna yii, iyẹn ni pe agbara lati wo awọn nǹkan nipasẹ ẹyinju awọn ọmọ wọn. Nipa fifi ifẹ ainimọtara ẹni nikan han, ẹyin obi le mu ide iṣọkan lilagbara dagba pẹlu awọn ọmọ yin ki ẹ si fun wọn niṣiiri lati fi ọkàn tán yin dipo fifi awọn ojugba wọn ṣe olùfọkàntán.—Kolose 3:14.
12. Eeṣe ti awọn ọdọ fi nilati jumọsọrọpọ falala pẹlu awọn obi wọn?
12 Ni ọwọ keji ẹwẹ, ẹyin ọdọ, ẹyin ni iṣẹ aigbọdọmaṣe lati jumọsọrọpọ pẹlu awọn obi yin. Mimọriri ohun ti wọn ti ṣe fun yin yoo ran yin lọwọ lati fi wọn ṣe alafinuhan yin. Ẹ nilo iranlọwọ ati itilẹhin wọn, yoo si tubọ rọrun fun wọn lati fifun-un yin bi ẹ ba njumọsọrọpọ falala pẹlu wọn. Bẹẹni, eeṣe ti ẹyin yoo ṣe fi ojugba yin ṣe orisun imọran yin pataki? Awọn wọnyi ti ṣe ohun ti o kere fun yin ni ifiwera pẹlu awọn obi yin. Wọn ko niriiri ninu igbesi-aye ju bi ẹ ti ni, bi wọn kii ba sii ṣe apakan ijọ, wọn ko nifẹẹ ninu ire yin pipẹtiti nitootọ.
Ijumọsọrọpọ Laaarin Ijọ
13, 14. Awọn ilana Bibeli wo ni o wémọ́ ijumọsọrọpọ laaarin awọn Kristẹni?
13 Ipenija miiran ni pipa ila ijumọsọrọpọ mọ ní ṣíṣí silẹ pẹlu awọn ará ninu ijọ. A fi tagbaratagbara rọ̀ wa ki a maṣe ‘kọ ipejọpọ araawa silẹ.’ Fun ete wo ni awa fi npejọ? “Lati rú araawa si ifẹ ati si iṣẹ rere.” Eyi beere fun ijumọsọrọpọ. (Heberu 10:24, 25) Bi ẹnikan ba ṣẹ ọ, iyẹn dajudaju kii ṣe idi fun ṣiṣai lọ si ipade. Pa ila ijumọsọrọpọ mọ ni ṣiṣi silẹ nipa titẹle ilana imọran ti Jesu fun wa gẹgẹ bi a ti ṣakọsilẹ rẹ̀ ni Matiu 18:15-17. Bá ẹni naa ti o nimọlara pe o fa ailayọ rẹ sọrọ.
14 Nigba ti o ba ní iṣoro pẹlu ọ̀kan lara awọn arakunrin rẹ, kọbiara si imọran ti o bá Iwe mimọ mu iru eyi ti a rí ni Kolose 3:13 (NW): “Ẹ maa baa lọ ni fifarada a fun araayin ẹnikinni keji ati didariji araayin ẹnikinni keji lọfẹẹ bi ẹnikẹni ba ni idi fun irahun si ẹnikeji. Ani gẹgẹ bi Jehofa ti dariji yin lọfẹẹ, bẹẹ ni ki ẹyin pẹlu maa ṣe.” Iyẹn tumọsi ijumọsọrọpọ dipo kikọ lati sọrọ si ẹnikan. Bi iwọ ba si wa ṣakiyesi pe o dabii ẹni pe ẹnikan kò ni ọyaya si ọ, kọbiara si imọran ti a ri ni Matiu 5:23, 24. Jumọsọrọpọ, ki o si gbiyanju lati wá alaafia pẹlu arakunrin rẹ̀. Eyi beere fun ifẹ ati irẹlẹ ni iha ọdọ rẹ, ṣugbọn o ku sọwọ rẹ ati arakunrin rẹ lati kọbiara si imọran Jesu.
Imọran ati Iṣiri
15. Eeṣe ti awọn Kristẹni ko fi nilati kuna lati sọ imọran funni nigba ti wọn ba wà ni ipo lati ṣe bẹẹ?
15 Iṣẹ aigbọdọmaṣe lati jumọsọrọpọ ni o tun wémọ́ kikọbiara si imọran Pọọlu ni Galatia 6:1: “Ará, bi a tilẹ mu eniyan ninu iṣubu kan, ki ẹyin tii ṣe ti ẹmi ki o mu iru ẹni bẹẹ bọ sipo ni ẹmi iwatutu; ki iwọ tikaraarẹ maa kiyesara, ki a ma baa dan iwọ naa wo pẹlu.” Ẹmi irẹlẹ nilati mu wa tẹwọgba ẹnikan ti ntọka ibi ti a ti ṣaṣiṣe ninu ọrọ tabi iwa jade fun wa. Niti tootọ, gbogbo wa nilati ni iṣarasihuwa ti Dafidi onisaamu naa ní nigba ti o kọwe pe: “Jẹ ki olododo ki o lù mi; iṣeun ni yoo jasi: jẹ ki o si ba mi wi; ororo daradara ni yoo jasi, ti ki yoo fọ́ mi lori.” (Saamu 141:5) Awọn alagba ni pataki gbọdọ jẹ apẹẹrẹ titayọ ninu irẹlẹ, lai rinkinkin mọ oju-iwoye ara ẹni ṣugbọn kí wọn wà ni imuratan lati tẹwọgba itunṣebọsipo, ni níní in lọkan pe ‘ọgbẹ tí ọrẹ ti o fẹran ẹni dá si ni lara jẹ otitọ.’—Owe 27:6.
16. Iru ijumọsọrọpọ wo ni awọn olubanisọrọ ti wọn jẹ ọdọ nilati fi idunnu gba?
16 O jẹ ipa ọna ọgbọn ati ẹmi irẹlẹ fun awọn ọdọ lati wa imọran ati idari lọ sọdọ awọn Kristẹni ogboṣaṣa, awọn ti o ṣeeṣe ki wọn ni ohun kan ti ngbeniro lati fifunni. Ani awọn alagba paapaa le janfaani ni ọna yii. Fun apẹẹrẹ, alagba kan sọ ninu asọye kan pe awọn ibukun ti a mẹnukan ninu Iṣipaya 7:16, 17, nipa ṣiṣai kebi tabi kóǹgbẹ mọ́, jẹ ohun ti awọn agutan miiran le fojusọna fun ninu aye titun. Bi o ti wu ki o ri, a ti tọka rẹ jade pe lakọọkọ ẹsẹ iwe mimọ yii niiṣe pẹlu akoko isinsinyi. (Wo iwe Revelation—Its Grand Climax At Hand!, oju-iwe 126 si 128.) Alagba kan ninu awujọ nimọlara pe oun nilati mẹnukan ọrọ naa, ṣugbọn ṣaaju ki o to ni anfaani lati ṣe bẹẹ, olubanisọrọ naa funraarẹ ké si i lori foonu o si beere fun amọran eyikeyii lori mimu asọye rẹ̀ sunwọn sii. Bẹẹni, ẹ jẹ ki a mu un rọrun fun awọn wọnni ti wọn yoo fẹ lati ràn wa lọwọ nipa sisọ ifẹ ọkan wa fun imọran. Ẹ maṣe jẹ ki a jẹ ẹni ti o rọrun lati ṣẹ̀ tabi atete binu laiyẹ.
17. Bawo ni ijumọsọrọpọ ṣe le ṣeranwọ lati gbe awọn ará wa ró?
17 Ọba Solomọni sọ ilana kan ti a tun le fisilo ninu ijiroro wa. O wi pe: “Maṣe fawọ ire sẹhin kuro lọdọ ẹni tii ṣe tirẹ, bi o ba wa ni agbara ọwọ rẹ lati ṣe e.” (Owe 3:27) A jẹ awọn arakunrin wa ni gbese ifẹ. Pọọlu wi pe: “Ẹ maṣe jẹ ẹnikẹni ni gbese ohun kan, bikoṣe pe ki a fẹran ọmọnikeji ẹni: nitori ẹni ti o ba fẹran ọmọnikeji rẹ, o kó ofin já.” (Roomu 13:8) Nitori naa jẹ ọlawọ pẹlu awọn ọrọ iṣiri rẹ. Njẹ iranṣẹ isẹ-ojiṣẹ ọdọ kan nsọ asọye rẹ akọkọ? Gboriyin fun. Arabinrin kan ha ti gbiyanju kára tabi ṣe daradara gan an ninu iṣẹ ti a yan fún un ni Ile-ẹkọ Iṣẹ-ojiṣẹ Iṣakoso Ọlọrun? Sọ fun un bi o ti gbadun awọn isapa rẹ̀ tó. Ni gbogbogboo, awọn arakunrin ati arabinrin wa nsakun lati ṣe gbogbo ohun ti wọn le ṣe a o si fun wọn niṣiiri nipa awọn ọrọ onifẹẹ ti imọriri.
18. Nibi ti a ba ti fi idara ẹni loju rekọja ààlà han ki ni yoo jẹ inurere lati ṣe?
18 Ni idakeji, ọdọ olubanisọrọ kan le ni ọpọlọpọ ẹbun, ṣugbọn nitori jijẹ ọdọ, o le fi idara ẹni loju hàn ju bi o ti yẹ lọ. Iru ijumọsọrọpọ wo ni eyi le beere fun? Ki yoo ha jẹ inurere bi alagba ogboṣaṣa kan ba gboriyin fún un fún awọn koko daradara eyikeyii ninu igbekalẹ rẹ̀ ṣugbọn, lakooko kan naa, ki o fi pẹlẹ damọran awọn ọna ti o le gba lati mu ẹmi irẹlẹ dagba ni ọjọ iwaju? Iru ijumọsọrọpọ bẹẹ yoo fi ifẹ ará han yoo si ran ọdọ naa lọwọ lati tete mu iṣarasihuwa buburu kuro, ki wọn to di baraku.
19. Eeṣe ti awọn alagba ati awọn olori idile fi nilati jẹ olubanisọrọpọ?
19 Awọn alagba njumọsọrọpọ pẹlu araawọn ati pẹlu ijọ nipa awọn ohun ti wọn ṣanfaani—amọ ṣa o, ni yiyẹra fun ṣiṣi awọn ọran aṣiiri paya, iru bii awọn wọnni ti wọn tan mọ awọn iṣoro idajọ. Bi o ti wu ki o ri, jijẹ apaṣiiri mọ ju le yọrisi ainigbọkanle ati irẹwẹsi o si le ṣe jàm̀bá fun ẹmi ọyaya ti o wa ninu ijọ—tabi ninu idile kan. Fun apẹẹrẹ, olukuluku eniyan gbadun gbigbọ irohin kan ti ngbeniro. Gan an gẹgẹ bi apọsiteli Pọọlu ti yanhanhan lati ta àtaré awọn ẹbun tẹmi, nitori naa awọn alagba nilati daniyan lati fun awọn ẹlomiran ni isọfunni ti ngbeniro.—Owe 15:30; 25:25; Roomu 1:11, 12.
20. Ẹka ijumọsọrọpọ wo ni ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e yoo da le?
20 Bẹẹni, ijumọsọrọpọ ṣe koko ninu ijọ Kristẹni ati ninu idile Kristẹni. Siwaju sii, o jẹ koseemani ni agbegbe miiran sibẹ. Nibo? Ninu iṣẹ-ojiṣẹ Kristẹni. Ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e, awa yoo gbe awọn ọna lati mu ọgbọn ijumọsọrọpọ wa pọ sii yẹwo ninu igbokegbodo pataki gan an yii.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Bawo ni a ṣe le ṣẹ́pá idiwọ lemọlemọ fun ijumọsọrọpọ idile?
◻ Bawo ni awọn ọkọ ati awọn aya ṣe le dojukọ ipenija ijumọsọrọpọ?
◻ Bawo ni awọn obi ati ọmọ ṣe nilati yẹra fun alafo ijumọsọrọpọ?
◻ Bawo ni ijumọsọrọpọ ninu ijọ ati ninu idile ṣe le ja si eyi ti ngbeniro?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ijumọsọrọpọ rere ngbe ire ati ayọ idile ga