Jehofa ati Kristi Awọn Olubanisọrọpọ Ti Wọn Gba Ipo Iwaju Julọ
“Oluwa Ọba-alaṣẹ Jehofa ki yoo ṣe ohun kan ayafi bi o ba ṣipaya ọran aṣiri rẹ̀ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ awọn wolii.”—AMOSI 3:7, NW.
1. Awọn ọna ijumọsọrọpọ wo ni a nlo lonii?
LONII ijumọsọrọpọ jẹ iṣẹ aje ọlọpọ million owo dollar. Gbogbo awọn iwe ti a ntẹ, gbogbo awọn iwe irohin ojoojumọ ati gbogbo iwe irohin ti a ntẹ deedee, gbogbo awọn itolẹsẹẹsẹ ori redio ati tẹlifiṣọn ti a ngbe safẹfẹ, ati pẹlu gbogbo awọn aworan ara ogiri ati eré orí ìtàgé, jẹ isapa nitori ijumọsọrọpọ. Ohun kan naa ni o jẹ ootọ nipa gbogbo awọn lẹta ti a nkọ ti a nfi ranṣẹ ati gbogbo ikesini ori fóònù pẹlu. Gbogbo wọn jẹ isapa nitori ijumọsọrọpọ.
2. Ki ni diẹ lara awọn apẹẹrẹ itẹsiwaju ti awọn eniyan ti ní ninu apa ẹka ijumọsọrọpọ ti o jẹmọ lilo ọgbọn imọ ẹrọ?
2 Awọn itẹsiwaju ti eniyan ti ni ninu apa ẹka ijumọsọrọpọ ti o jẹmọ lilo ọgbọn imọ ẹrọ jẹ amuniṣekayeefi. Fun apẹẹrẹ, awọn waya tẹlifoonu ti a fi jígí ṣe ti a mọ si fiber-optic, ti won dara lọpọlọpọ ju awọn waya ti a fi bàbà ṣe, lè gbé ọpọlọpọ ẹgbẹẹgbẹrun lọna mẹwaa mẹwaa awọn ijumọsọrọpọ ori tẹlifoonu lẹẹkanṣoṣo. Lẹhin naa awọn satelite ijumọsọrọpọ wà, eyi ti o nyi aye po ninu ofuurufu ti o si ni ohun eelo fun ṣiṣe àtagbà awọn ihin-iṣẹ tẹlifoonu, wáyà, redio, ati tẹlifiṣọn. Ọkan lara iru satelite bẹẹ le bojuto 30,000 ihin-iṣẹ tẹlifoonu lẹẹkan naa!
3. Ki ni nṣẹlẹ nigba ti alafo ijumọsọrọpọ bá wà?
3 Ṣugbọn laika gbogbo ọna ijumọsọrọpọ wọnyi sí, ọpọ ibanujẹ wà ninu aye nitori aisi ijumọsọrọpọ laaarin awọn enikọọkan. Nipa bayii, a sọ fun wa pe “ọgbun kan ti o tubọ njin sii wa—‘alafo ijumọsọrọpọ’ ti npọ sii—laaarin awọn oluṣakoso ati awọn ti a nṣakoso.” Ki si ni ohun ti a npe ni alafo ijumọsọrọpọ naa bikoṣe ikuna awọn obi ati awọn ọmọ wọn lati jumọsọrọpọ pẹlu araawọn lọna ti o yọrisi rere? Awọn agbani nimọran igbeyawo rohin pe iṣoro titobi julọ ninu igbeyawo jẹ ikuna ijumọsọrọpọ laaarin ọkọ ati aya. Aisi ijumọsọrọpọ ti o tọ́ tilẹ le fa iku paapaa. Ni ibẹrẹ 1990, awọn eniyan 73 sọ ẹmi wọn nù ninu ijamba ọkọ ofuurufu kan, okunfa ti o han gbangba kan jẹ ikuna ijumọsọrọpọ laaarin atukọ ati adari ti o wà lori ilẹ. Akori iwaju iwe irohin ojoojumọ kan polongo pe: “Idena ijumọsọrọpọ yọrisi ijamba.”
4. (a) Ki ni “ijumọsọrọpọ” tumọsi? (b) Ki ni gongo ijumọsọrọpọ Kristẹni?
4 Ki ni ijumọsọrọpọ laaarin awọn Kristẹni? Ni ibamu pẹlu iwe atumọ ede kan, “ijumọsọrọpọ” tumọ si “lati ta àtaré isọfunni, ironu, tabi imọlara debi pe a gba isọfunni naa lọna ti o tẹnilọrun tabi ti o yé ni.” Iwe atumọ ede miiran tumọ rẹ gẹgẹ bi “ọna kan fun sisọ awọn ero jade lọna gbigbeṣẹ.” Ṣakiyesi “sisọ awọn ero jade lọna gbigbeṣẹ.” Ijumọsọrọpọ laaarin awọn Kristẹni ni pataki nilati gbeṣẹ nitori pe o ni gẹgẹ bi gongo rẹ dide inu ọkan-aya awọn eniyan pẹlu otitọ lati inu Ọrọ Ọlọrun ki o ba le jẹ pe, gẹgẹ bi a ti reti, wọn yoo gbegbeesẹ lori ohun ti wọn kẹkọọ. Lọna ti o tayọ, a sun un ṣiṣẹ nipasẹ ainimọtara ẹni nikan, nipasẹ ifẹ.
Jehofa Gẹgẹ bi Olubanisọrọpọ
5. Ki ni ọkan lara awọn ọna ti Jehofa Ọlọrun kọkọ gba jumọsọrọpọ pẹlu eniyan?
5 Laisi iyemeji Jehofa Ọlọrun ni Olubanisọrọpọ titobi julọ. Nitori pe oun dá wa ni aworan ati irisi rẹ̀, o ṣeeṣe fun un lati jumọsọrọpọ pẹlu wa, o si ṣeeṣe fun wa lati jumọsọrọpọ pẹlu awọn ẹlomiran nipa rẹ̀. Lati igba iṣẹda eniyan, Jehofa ti jumọsọrọpọ pẹlu awọn ẹda rẹ ori ilẹ-aye nipa araarẹ. Ọna kan ti o gba ṣe eyi ti jẹ nipasẹ iṣẹda rẹ̀ ti a le fojuri. Nipa bayii, onisaamu naa sọ fun wa pe: “Awọn ọ̀run nsọrọ ogo Ọlọrun; ati ofuurufu nfi iṣẹ ọwọ rẹ han. Ọjọ de ọjọ nfọhun, ati oru de oru nfi imọ han.” (Saamu 19:1, 2) Roomu 1:20 (NW) si fi tó wa leti pe “awọn animọ airi” ti Ọlọrun “ni a rí ni kedere lati igba iṣẹda wá.” “Rí ni kedere” tọkasi ijumọsọrọpọ ti o gbeṣẹ!”
6. Ki ni Jehofa ba awọn ẹda rẹ̀ ori ilẹ-aye sọ nigba ti wọn wa ninu ọgba Edeni?
6 Awọn wọnni ti wọn ko nigbagbọ ninu Ọlọrun ati iṣipaya atọrunwa rẹ̀ yoo fẹ ki a gbagbọ pe eniyan ni a fi silẹ fun awọn orisun isọfunni tirẹ funraarẹ lati ṣawari idi ti oun fi wà laaye. Ṣugbọn Ọrọ Ọlọrun mu un ṣe kedere pe Ọlọrun ti jumọsọrọpọ pẹlu eniyan lati ibẹrẹ. Nipa bayii, Ọlọrun fun ọkunrin ati obinrin akọkọ ni aṣẹ ìmúrú ọmọ jade: “Ẹ maa bí sii, ki ẹ si maa rẹ̀, ki ẹ sì gbilẹ, ki ẹ si ṣe ikawọ rẹ̀; ki ẹ si maa jọba . . . lori ohun alaaye gbogbo ti nrako lori ilẹ.” Ọlọrun tun yọnda fun wọn lati jẹ ajẹyo ninu awọn eso ọgba naa—pẹlu ayafi kanṣoṣo. Lẹhin naa, nigba ti Adamu ati Efa ṣaigbọran, Jehofa sọrọ nipa ileri akọkọ ti Mesaya, ni fifun araye ni itanṣan ireti kan: “Emi yoo si fi ọta saarin iwọ ati obinrin naa, ati saarin iru-ọmọ rẹ ati iru-ọmọ rẹ̀: oun yoo fọ́ ọ ni ori, iwọ yoo si pa á ni gigisẹ.”—Jẹnẹsisi 1:28; 2:16, 17; 3:15.
7. Ki ni iwe Jẹnẹsisi ṣipaya nipa ijumọsọrọpọ Jehofa pẹlu awọn iranṣẹ rẹ̀?
7 Nigba ti Keeni ọmọkunrin Adamu kun fun ilara apaniyan, Jehofa Ọlọrun jumọsọrọpọ pẹlu rẹ, ni sisọ nitootọ pe: ‘Kiyesara! O fẹ kó sinu ijọgbọn!’ Ṣugbọn Keeni kọ̀ lati kọbiara si ikilọ yẹn o si pa arakunrin rẹ̀. (Jẹnẹsisi 4:6-8) Lẹhin naa, nigba ti aye kun fun iwa ipa ati iwa buburu, Jehofa bá Noa ọkunrin olododo naa sọrọ nipa ete rẹ̀ lati nu ilẹ-aye mọ́ kuro lọwọ gbogbo ohun ti nsọ ọ di ẹlẹgbin. (Jẹnẹsisi 6:13–7:5) Lẹhin Ikun omi naa, nigba ti Noa ati idile rẹ̀ jade wa lati inu aaki, Jehofa bá wọn sọrọpọ nipa ìjẹ́mímọ́ iwalaaye ati ẹjẹ, ati nipasẹ oṣumare o fun wọn ni idaniloju pe oun ki yoo pa gbogbo ohun alaaye run lẹẹkansii mọ nipa ikun omi. Nǹkan bi ọgọrun un ọdun diẹ lẹhin naa, Jehofa ba Aburahamu sọrọ nipa ete Rẹ̀ lati jẹ ki gbogbo idile araye bukun araawọn nipasẹ Iru-ọmọ Aburahamu. (Jẹnẹsisi 9:1-17; 12:1-3; 22:11, 12, 16-18) Nigba ti Ọlọrun si paṣẹ pe oun yoo pa awọn oniwa palapala takọtabo lọna odi ti Sodomu ati Gomora run, o fi tifẹtifẹ sọ otitọ yẹn fun Aburahamu, ni wiwi pe: “Emi yoo ha pa ohun ti emi yoo ṣe mọ fun Aburahamu?”—Jẹnẹsisi 18:17.
8. Ni awọn ọna mẹrin wo ni Jehofa ti gba jumọsọrọpọ pẹlu awọn iranṣẹ rẹ̀ lori ilẹ-aye?
8 Ni bibẹrẹ pẹlu Mose, Jehofa lo ọgọọrọ awọn wolii lati jumọsọrọpọ pẹlu Isirẹli. (Heberu 1:1) Nigba miiran o lo ọrọ apekọ, gẹgẹ bii nigba ti o sọ fun Mose pe: “Iwọ kọwe ọrọ wọnyi.” (Ẹkisodu 34:27) Ni eyi ti o tubọ ṣe lemọlemọ Jehofa jumọsọrọpọ pẹlu awọn agbọrọsọ rẹ̀ nipasẹ awọn iran, gẹgẹ bi oun ti ṣe tẹlẹ pẹlu Aburahamu.a Jehofa tun lo awọn àlá lati jumọsọrọpọ pẹlu awọn eniyan, kii si ṣe pẹlu awọn iranṣẹ rẹ̀ nikan ṣugbọn pẹlu awọn wọnni ti wọn ni ibalo pẹlu awọn iranṣẹ rẹ̀. Fun apẹẹrẹ, Jehofa mu ki awọn ẹlẹwọn ẹlẹgbẹ Josẹfu meji lá awọn àlá, eyi ti Josẹfu tumọ fun wọn. Jehofa tun mu ki Farao ati Nebukadinesari lá awọn àlá, eyi ti awọn iranṣẹ rẹ̀ Josẹfu ati Daniẹli tumọ fun wọn. (Jẹnẹsisi 40:8–41:32; Daniẹli, ori 2 ati 4) Ni afikun, ni ọpọlọpọ igba Jehofa lo awọn angẹli oniṣẹ lati jumọsọrọpọ pẹlu awọn iranṣẹ rẹ̀.—Ẹkisodu 3:2; Onidaajọ 6:11; Matiu 1:20; Luuku 1:26.
9. Ki ni o sun Jehofa lati jumọsọrọpọ pẹlu awọn eniyan rẹ̀ Isirẹli, gẹgẹ bi a ti ri i nipa awọn ọrọ rẹ̀ wo?
9 Gbogbo iru ijumọsọrọpọ bẹẹ lati ọdọ Jehofa nipasẹ awọn wolii rẹ fi ifẹ rẹ fun awọn eniyan rẹ Isirẹli han. Gẹgẹ bi apẹẹrẹ kan, o sọ nipasẹ wolii rẹ Esekiẹli pe: “Emi ko ni inu didun ni iku eniyan buburu, ṣugbọn ki eniyan buburu yipada kuro ninu ọna rẹ̀ ki ó si yè: Ẹ yipada, ẹ yipada kuro ninu ọna buburu yin; nitori ki ni ẹyin yoo ṣe ku ile Isirẹli?” (Esekiẹli 33:11) Jehofa jẹ Olubanisọrọpọ onipamọra ati onisuuru pẹlu awọn eniyan rẹ̀ ọlọtẹ igbaani, gẹgẹ bi a ti le ri i lati inu 2 Kironika 36:15, 16: “Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun awọn baba wọn si ranṣẹ si wọn lati ọwọ awọn onṣẹ rẹ̀, ó ndide ni kutukutu, ó si nranṣẹ, nitori ti ó ni ìyọ́nú si awọn eniyan rẹ̀, ati si ibugbe rẹ̀. Ṣugbọn wọn . . . kẹgan ọrọ rẹ̀, wọn si fi awọn wolii rẹ̀ ṣẹsin, titi . . . ti ko fi si atunṣe.”
10. Bawo ni Jehofa ṣe njumọsọrọpọ pẹlu awọn eniyan lonii, ati dé àyè wo ni oun jẹ Ọlọrun ijumọsọrọpọ?
10 Lonii, a ni Ọrọ onimiisi ti Ọlọrun, Bibeli Mimọ nipasẹ eyi ti Jehofa sọ nipa araarẹ, awọn ete rẹ, ati ifẹ-inu rẹ fun wa. (2 Timoti 3:16, 17) Nitootọ, gẹgẹ bi Olubanisọrọpọ Gigajulọ, Jehofa, polongo pe: “Oluwa Ọba-alaṣẹ Jehofa ki yoo ṣe ohun kan ayafi bi o ba ṣipaya ọran aṣiri rẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ awọn wolii.” (Amosi 3:7, NW) O mu ohun ti o pete lati ṣe di mimọ fun awọn iranṣẹ rẹ.
Ọmọkunrin Ọlọrun Gẹgẹ bi Olubanisọrọpọ
11. Ta ni ohun eelo ijumọsọrọpọ Jehofa pẹlu eniyan ti o gba ipo iwaju julọ, eesitiṣe ti orukọ oye rẹ̀ “Ọrọ naa” fi ba a mu?
11 Ninu gbogbo awọn aṣoju ti Jehofa lò lati sọ ifẹ-inu Rẹ̀, ẹni ti o gba ipo iwaju julọ ni Ọrọ naa, Logos, ẹni ti o di Jesu Kristi. Ki ni pipe ti a npe e ni Ọrọ, tabi Logos fihan? Pe o jẹ Olori Agbọrọsọ Jehofa. Ki si ni agbọrọsọ kan jẹ́? Ẹni ti o nta àtaré ohun ti ẹlomiran ní lati sọ. Nitori naa Logos di olusọ ọrọ Jehofa Ọlọrun fun iṣẹda ọlọgbọnloye Rẹ̀ ti ori ilẹ-aye. Ipa yẹn ṣe pataki gan an debi pe oun ni a pe ni Ọrọ.—Johanu 1:1, 2, 14.
12. (a) Fun ete wo ni Jesu ṣe wa si ori ilẹ-aye? (b) Ki ni o jẹrii sii pe o fi otitọ mu ete yẹn ṣẹ?
12 Jesu funraarẹ sọ fun Pọntu Pilatu pe pataki ete rẹ̀ ti wíwá si ilẹ-aye ni lati sọ otitọ naa fun araye: “Nitori eyi ni a ṣe bi mi, ati nitori idi eyi ni mo si ṣe wa si aye, ki emi ki o le jẹrii si otitọ.” (Johanu 18:37) Akọsilẹ inu awọn Ihinrere si sọ bi oun ti ṣe iṣẹ yẹn daradara tó. Iwaasu rẹ̀ ori Oke ni a mọ dunju gẹgẹ bi iwaasu giga julọ ti ẹnikan tii waasu rẹ̀ rí. Ẹ wo bi oun ti sọrọ daradara tó nipasẹ iwaasu yẹn! “Iyọrisi rẹ̀ ni pe háà ṣe awọn ogunlọgọ eniyan [ti wọn gbọ iwaasu naa] si ọ̀nà ikọnilẹkọọ rẹ̀.” (Matiu 7:28, NW) Nipa akoko miiran, a ka pe: “Ọpọ ijọ eniyan si fi ayọ gbọ ọ̀rọ̀ rẹ̀.” (Maaku 12:37) Nigba ti a ran awọn onṣẹ kan bayii lati faṣẹ ọba mu Jesu, wọn pada wa lọwọ ofo. Eeṣe? Wọn da awọn Farisi lohun pe: “Ko si ẹni ti o tii sọrọ bi ọkunrin yii rí.”—Johanu 7:46.
A Ran Awọn Ọmọ-ẹhin Kristi Niṣẹ Pẹlu Aṣẹ Lati Jẹ Olubanisọrọpọ
13. Ki ni o fihan pe Jesu ko fẹ lati danikan jẹ olubanisọrọpọ?
13 Laifẹ lati danikan jẹ olubanisọrọpọ, Jesu kọkọ ran awọn apọsiteli 12 niṣẹ pẹlu aṣẹ ati lẹhin naa 70 ajihinrere lati jade lọ gẹgẹ bi awọn olubanisọrọ ihinrere Ijọba naa. (Luuku 9:1; 10:1) Lẹhin naa kete ṣaaju ki ó tó goke re ọrun, o faṣẹ fun awọn ọmọ-ẹhin niṣẹ pẹlu aṣẹ lati ṣe iṣẹ akanṣe kan. Iṣẹ wo? Gẹgẹ bi a ti ka ni Matiu 28:19, 20, o fun wọn ni itọni lati jẹ olubanisọrọpọ; wọn si nilati kọ́ awọn ẹlomiran ni afikun lati di olubanisọrọpọ pẹlu.
14. Bawo ni awọn Kristẹni ijimiji ti wọn jẹ olubanisọrọpọ ṣe gbeṣẹ tó?
14 Awọn ọmọ-ẹhin naa ha jẹ olubanisọrọpọ ti wọn gbeṣẹ bi? Dajudaju bẹẹni! Gẹgẹ bi iyọrisi iwaasu wọn ni ọjọ Pẹntikọsi 33 C.E., 3,000 ọkàn ni a fikun ijọ Kristẹni ti a ṣẹṣẹ dá silẹ naa. Laipẹ iye naa pọ sii de 5,000 eniyan. (Iṣe 2:41; 4:4) Abajọ ti awọn ọta wọn ti wọn jẹ Juu fi fẹsun kikun gbogbo Jerusalẹmu pẹlu ẹkọ wọn kàn wọ́n ti wọn si rahun lẹhin naa pe wọn ti soju ilẹ-aye ti a ngbe dé pẹlu iwaasu wọn!—Iṣe 5:28; 17:6.
15. Ohun eelo wo ni Jehofa ti lo ni akoko ode oni lati jumọsọrọpọ pẹlu eniyan?
15 Ki ni nipa akoko ode oni? Gẹgẹ bi a ṣe sọtẹlẹ ni Matiu 24:3, 45-47, Ọga naa, Jesu Kristi, ti yan “ẹru oluṣotitọ ati ọlọgbọn inu,” tí awọn Kristẹni ẹni ami ororo papọ jẹ́, lati bojuto gbogbo ohun-ìní rẹ lori ilẹ-aye lakooko wiwa nihin in rẹ yii. Ẹru oluṣotitọ ati ọlọgbọn inu yẹn ni Ẹgbẹ Oluṣakoso ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣoju fun lonii, eyi ti ó ni Watch Tower Bible and Tract Society gẹgẹ bi alukoro aṣoju rẹ̀. Lọna ti o bamu rẹgi julọ, ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn inu yẹn ni a tun ti pe ni ọna ijumọsọrọpọ Ọlọrun. Oun, ẹ̀wẹ̀, fun wa niṣiiri lati jẹ olubanisọrọpọ rere. Nitootọ, itẹjade Zion’s Watch Tower and Herald of Christ’s Presence akọkọ gan an fun awọn onkawe rẹ̀ nimọran pe: “Bi iwọ ba ni aladuugbo tabi ọrẹ kan ti iwọ ronu pe yoo nifẹẹ ninu tabi janfaani nipasẹ awọn isọfunni [iwe irohin yii], o le pe e si afiyesi wọn; ni titipa bayii waasu Ọrọ naa ki o si ṣe rere si gbogbo eniyan gẹgẹ bi iwọ ti ni anfaani rẹ̀.”
16. Ki ni o fihan pe ohun pupọ sii ni a nilo ju wiwulẹ ka Bibeli lọ fun Ọlọrun lati jumọsọrọpọ pẹlu awọn iranṣẹ rẹ̀ ti ori ilẹ-aye lọna gbigbeṣẹ?
16 Bi o ti wu ki o ri, wiwulẹ ni Ọrọ Ọlọrun larọọwọto ati kika Bibeli funra ẹni nikan kò tó lati jere imọ pipeye ti nmu ẹnikan bọ́ soju ọna iye. Ranti onṣẹ agbala ọba ara Etiopia naa ẹni ti nka asọtẹlẹ Aisaya ṣugbọn ti ko loye ohun ti o nka. Filipi onihinrere ṣalaye asọtẹlẹ naa fun un, lẹhin eyi ti oun ṣetan lati di ẹni ti a baptisi gẹgẹ bi ọmọ-ẹhin Kristi. (Iṣe 8:27–38) Otitọ naa pe ohun pupọ sii ni a nilo ju wiwulẹ ka Bibeli funra ẹni ni a le ri ninu Efesu 4:11-13 (NW), nibi ti Pọọlu ti fihan pe kii ṣe kiki pe Kristi funni ni awọn kan gẹgẹ bi apọsiteli ati wolii ti a misi nikan ni ṣugbọn o tun funni ni “awọn kan bi ajihinrere, awọn kan bi oluṣọ agutan ati olukọ, pẹlu ireti itunṣebọsipo awọn ẹni mimọ, fun iṣẹ ojiṣẹ, fun ìgbéró ara Kristi, titi gbogbo wa yoo fi dé iṣọkanṣoṣo ninu igbagbọ ati ninu imọ pipeye ti Ọmọkunrin Ọlọrun, ti a o fi di gende ọkunrin.”
17. Ki ni awọn ami idanimọ ti a le fi dá aṣoju ti Jehofa nlo lonii lati sọ awọn ete rẹ̀ fun araye mọ̀?
17 Bawo ni a ṣe le dá awọn wọnni ti Jehofa Ọlọrun ati Jesu Kristi nlo lati ran awọn eniyan ti wọn yoo di Kristẹni lọwọ lati de ipo gende ọkunrin kan mọ̀? Gẹgẹ bi Jesu ti wi, ọkan lara awọn ami idanimọ naa yoo jẹ pe awọn wọnyi nifẹẹ araawọn gẹgẹ bi Jesu ti nifẹẹ awọn ọmọ ẹhin rẹ̀. (Johanu 13:34, 35) Ami idanimọ miiran: Wọn ki yoo jẹ apakan aye, ani gẹgẹ bi Jesu kii tii ṣe apákan aye. (Johanu 15:19; 17:16) Sibẹ ami miiran yoo jẹ pe wọn yoo mọ Ọrọ Ọlọrun dunju gẹgẹ bi otitọ, gẹgẹ bi Jesu ti ṣe, ni wiwa itilẹhin aṣẹ rẹ̀. (Matiu 22:29; Johanu 17:17) Fifi orukọ Ọlọrun si iwaju, gẹgẹ bi Jesu ti ṣe yoo jẹ ami miiran. (Matiu 6:9; Johanu 17:6) Ami kan sii yoo jẹ titẹle apẹẹrẹ Jesu ninu wiwaasu Ijọba Ọlọrun. (Matiu 4:17; 24:14) Awujọ kanṣoṣo ni o wà ti o de oju ila awọn ohun abeere fun wọnyi, awọn ni a mọ si olubanisọrọpọ jakejado orilẹ-ede ti a mọ gẹgẹ bi awọn Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jehofa.
18. Awọn agbegbe mẹta wo fun ijumọsọrọpọ ni awọn ọrọ-ẹkọ siwaju sii yoo jiroro?
18 Bi o ti wu ki o ri, ijumọsọrọpọ tumọ si ẹru iṣẹ siha ọdọ awọn ẹlomiran. Pẹlu ta ni awọn Kristẹni lẹru iṣẹ lati jumọsọrọpọ? Ni ipilẹ, awọn apa mẹta ni wọn wà ninu eyi ti awọn Kristẹni gbọdọ daniyan pẹlu mimu ọna ijumọsọrọpọ wà ni ṣiṣi silẹ: agbo idile, ijọ Kristẹni, ati iṣẹ-ojiṣẹ pápá Kristẹni. Awọn ọrọ-ẹkọ ti wọn tẹle yoo bojuto awọn apa wọnyi ninu koko ọrọ wa.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Jẹnẹsisi 15:1; 46:2; Numeri 8:4; 2 Samuẹli 7:17; 2 Kironika 9:29; Aisaya 1:1; Esekiẹli 11:24; Daniẹli 2:19; Obadaya 1; Nahumu 1:1; Iṣe 16:9; Iṣipaya 9:17.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Ipalara wo ni o le jẹyọ lati inu aisi ijumọsọrọpọ?
◻ Awọn wo ni olubanisọrọpọ meji ti wọn gba ipo iwaju julọ?
◻ Oniruuru ọna wo ni Ọlọrun ti lo lati jumọsọrọpọ pẹlu eniyan?
◻ Bawo ni Jesu ṣe tayọ gẹgẹ bi olubanisọrọpọ kan?
◻ Bawo ni awọn Kristẹni ijimiji ṣe ṣaṣeyọri si rere tó ninu ijumọsọrọpọ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Bii Baba rẹ̀ ọrun, Jesu jẹ olubanisọrọpọ oníyọ̀ọ́nú