ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 9/1 ojú ìwé 25-29
  • Ijumọsọrọpọ Ninu Iṣẹ-ojiṣẹ Kristẹni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ijumọsọrọpọ Ninu Iṣẹ-ojiṣẹ Kristẹni
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ijumọsọrọpọ Ti A Ko Fẹnusọ
  • Ibanironupọ Ṣekoko si Ijumọsọrọpọ
  • Awọn Animọ Ti A Nilo fun Ijumọsọrọpọ Ti O Gbeṣẹ
  • Ifẹ—Aranṣe Kan Ninu Ijumọsọrọpọ
  • Jijumọsọrọpọ Laaarin Idile ati Ninu Ijọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Jehofa ati Kristi Awọn Olubanisọrọpọ Ti Wọn Gba Ipo Iwaju Julọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Jẹ́ Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Tí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Ń Wọni Lọ́kàn!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Ǹjẹ́ O Máa Ń Bá Ọlọ́run Sọ̀rọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 9/1 ojú ìwé 25-29

Ijumọsọrọpọ Ninu Iṣẹ-ojiṣẹ Kristẹni

“Nitori naa ẹ lọ ki ẹ si maa sọ awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede di ọmọ-ẹhin.”—MATIU 28:19, NW.

1. Aṣẹ wo ti Kristi fifunni ni o tumọsi aini lati jumọsọrọpọ?

AṢẸ ti Jesu fifunni, ti a fayọ loke yii, gbe ipenija siwaju wa ti jijumọsọrọpọ pẹlu awọn eniyan ninu iṣẹ-ojiṣẹ wa gẹgẹ bi a ti nlọ lati ile de ile, ṣe awọn ipadabẹwo, ti a si nṣajọpin ninu awọn iha miiran ti iwaasu Ijọba. Eyi ti a fi kun un ninu iṣẹ-aṣẹ naa ni ẹru-iṣẹ lati sọ otitọ nipa Jehofa Ọlọrun, Jesu Kristi, ati Ijọba Mesaya ninu eyi ti Jesu nṣakoso nisinsinyi di mímọ̀.—Matiu 25:31-33.

2. Lati jumọsọrọpọ lọna gbigbeṣẹ, ki ni a nilo?

2 Bawo ni a ṣe le jumọsọrọpọ lọna gbigbeṣẹ? Lakọọkọ, a gbọdọ gbagbọ ninu isọfunni naa ti a ńtàtaré rẹ̀. Ni ede miiran, a gbọdọ ni igbagbọ lilagbara pe Jehofa ni Ọlọrun tootọ kanṣoṣo naa, pe Bibeli jẹ Ọrọ Ọlọrun nitootọ, ati pe Ijọba Ọlọrun ni ireti kanṣoṣo fun araye. Ni ọna yẹn, ohun ti a fi kọni yoo wá lati inu ọkan-aya, awa yoo si maa kọbiara si imọran Pọọlu si Timoti pe: “Ṣaapọn lati fi araarẹ han niwaju Ọlọrun ni ẹni ti o yege, aṣiṣẹ ti ko nilati tiju, ti o npin ọrọ otitọ bi o ti yẹ.”—2 Timoti 2:15.

Ijumọsọrọpọ Ti A Ko Fẹnusọ

3-5. (a) Bawo ni a ṣe le jumọsọrọpọ lai tilẹ sọ ọrọ kankan? (b) Awọn iriri wo ni o ti eyi lẹhin?

3 Ijumọsọrọpọ saba maa ńwémọ́ awọn ọ̀rọ̀. Ṣugbọn, nitootọ, a njumọsọrọpọ pẹlu awọn eniyan ani ṣaaju ki a to sọrọ si wọn paapaa. Bawo? Nipa iwa wa ati nipa ọna ti a gba wọṣọ ti a si mura. Ni ọpọlọpọ ọdun sẹhin akẹkọọyege ojihin-iṣẹ Ọlọrun ti Watchtower Bible School of Gilead kan nrinrin-ajo nipasẹ ọkọ oju omi lọ si ilẹ okeere ti a yàn án sí. Lẹhin ọjọ melookan loju okun, ajeji kan beere lọwọ rẹ̀ idi ti o fi yatọ si gbogbo awọn miiran ninu ọkọ. Ojihin-iṣẹ Ọlọrun naa nta atare ohun kan ti o yẹ fun afiyesi—pe oun ní ọpa idiwọn ti o yatọ ati pe oun ṣee sunmọ—kiki nipa irisi ati ọna ihuwa rẹ̀ nikan. Eyi pese anfaani rere kan fun ojihin-iṣẹ Ọlọrun naa lati funni ni ijẹrii.

4 Lẹhin naa, arabinrin kan ti o duro ni opopona ti o nfi iwe ikẹkọọ Bibeli lọ awọn ti nkọja rẹrin musẹ lọna bi ọrẹ si obinrin kan ti o rin sunmọ ọn. Obinrin yii bẹrẹ si sọkalẹ lọ lori atẹgun si ibudo ọkọ oju irin abẹlẹ kan. Lẹhin naa o yi ọkan rẹ̀ pada, o rin pada lọ si ọdọ arabinrin naa, o si beere fun ikẹkọọ Bibeli inú ile. Ki ni o wú u lori? Bi o tilẹ jẹ pe a ko fi iwe ikẹkọọ Bibeli lọ̀ ọ́, Ẹlẹrii naa ti nṣe iṣẹ opopona ti rẹrin musẹ lọna bi ọrẹ sii.

5 Apẹẹrẹ kẹta: “Awujọ awọn ọdọ Ẹlẹrii kan jẹun ni ile ounjẹ kan ẹnu si yà wọn nigba ti ajeji kan wa sidii tabili wọn ti o si sanwo fun ounjẹ wọn. Eeṣe ti o fi ṣe iyẹn? Oun ni a ti wu lori nipa ọna ihuwa wọn. Laisọ ọrọ kankan si ajeji naa, awọn Kristẹni ọdọ wọnyi ti ta àtaré isọfunni pe wọn jẹ olubẹru Ọlọrun lẹnikọọkan. Ni kedere, nipa ihuwasi, irisi, ati ẹmi ọrẹ ti a nfihan, awa njumọsọrọpọ ani ṣaaju ki a to sọ ọrọ kan paapaa.—Fiwe 1 Peteru 3:1, 2.

Ibanironupọ Ṣekoko si Ijumọsọrọpọ

6. Ṣakawe bi ibanironupọ ṣe ṣeyebiye tó fun ijumọsọrọpọ.

6 Lati ni ijumọsọrọpọ ọlọrọ ẹnu pẹlu awọn eniyan nipa ihinrere naa, awa gbọdọ muratan, kii ṣe lati sọrọ lọna ìgbawèrèmẹ́sìn, ṣugbọn lati ronu pẹlu wọn. A ka leralera pe Pọọlu ronu pẹlu awọn wọnni ti oun gbiyanju lati fi ihinrere naa tó leti. (Iṣe 17:2, 17; 18:19) Bawo ni awa ṣe le tẹle apẹẹrẹ rẹ̀? O dara, awọn ipò ayé ti nburu sii ti le mu ki awọn kan ṣiyemeji nipa wiwa Ọlọrun Olodumare ati onifẹẹ kan ti o bikita fun araye. Bi o ti wu ki o ri, awa le ronu pẹlu wọn, pe Ọlọrun ni akoko fun ohun gbogbo. (Oniwaasu 3:1-8) Nipa bayii, Galatia 4:4 wi pe nigba ti akoko ti Ọlọrun ṣeto dé, o ran Ọmọkunrin rẹ̀ wa sori ilẹ-aye. Eyi jẹ ẹgbẹẹgbẹrun ọdun lẹhin ti oun kọkọ ṣeleri lati ṣe bẹẹ. Lọna ti o farajọra, nigba ti akoko ti Ọlọrun ṣeto bá dé, oun yoo fi opin si iwa buburu. Ju bẹẹ lọ, Ọrọ Ọlọrun fihan pe Ọlọrun ni idi ti o yẹ fun afiyesi fun fifaye gba iwa buburu lati maa baa lọ fun igba pipẹ. (Fiwe Ẹkisodu 9:16.) Rironu ni ọna oju iwoye yii, ati titi ironu yẹn lẹhin pẹlu awọn apẹẹrẹ ati ẹri alagbara ti o ba Iwe mimọ mu, yoo ran awọn olootọ ọkan lọwọ lati mọ daju pe iwa buburu ti o gbodekan ni a ko le lo gẹgẹ bi koko ijiyan pe Jehofa ko sí tabi pe ko bikita.—Roomu 9:14-18.

7, 8. Bawo ni iwoyeronu ṣe le ràn wá lọwọ lati jumọsọrọpọ pẹlu awọn Juu Arinkinkin mọ ilana isin ti a mu ba ode oni mu?

7 Ki a sọ pe nigba ti o nlọ lati ile de ile, onile kan sọ fun ọ pe: “Juu ni mi. Emi ko nifẹẹ si iṣẹ yin.” Bawo ni iwọ ṣe le tẹsiwaju? Arakunrin kan rohin aṣeyọrisi rere rẹ̀ ni lilo ọna iyọsini yii: ‘O da mi loju pe iwọ yoo gbà pẹlu mi pe Mose jẹ ọ̀kan lara awọn wolii titobi julọ ti Ọlọrun tii lò rí. Ati pe njẹ o mọ pe o sọ gẹgẹ bi a ti kọ ọ́ silẹ ninu Deutaronomi 31:29 pe: “Nitori mo mọ pe lẹhin iku mi ẹyin yoo . . . yipada kuro ni ọna ti mo palaṣẹ fun yin; ibi yoo si báa yin”? Mose jẹ wolii tootọ, nitori naa awọn ọrọ rẹ̀ nilati jasi ootọ. O ha le jẹ pe wọn jasi ootọ nigba ti Ọlọrun rán Mesaya si awọn Juu ati pe idi niyii ti awọn Juu ko fi gbà á? O le ti jẹ bi ọran ti ri niyẹn. Nisinsinyi bi eyi ba ri bẹẹ ti wọn sì ṣe aṣiṣe, iyẹn ha jẹ idi ti iwọ ati emi fi nilati ṣe aṣiṣe kan naa bi?

8 Ranti, pẹlu pe, awọn Juu ti jiya pupọ lati ọwọ Kristẹndọmu, paapaa ninu ọrundun yii. Nitori naa iwọ lè fẹ́ lati sọ fun onile naa pe awa kò kó ipa kankan ninu iyẹn. Fun apẹẹrẹ, iwọ le fẹ lati sọ pe: ‘Njẹ iwọ mọ pe nigba ti Hitler wa lori àléfà ijọba, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tako ṣíṣá ti o ṣá awọn Juu tì? Wọn tun kọ̀ lati sọ pe “Igbala ni ti Hitler” [“Heil Hitler”] ati lati sin ninu ẹgbẹ ọmọ ogun rẹ̀.’a

9, 10. Bawo ni a ṣe le lo ibanironupọ lati ran ẹnikan ti o gbagbọ ninu ina ọrun apaadi lọwọ?

9 Ninu sisapa lati jumọsọrọpọ pẹlu ẹnikan ti o gbagbọ ninu ọrun apaadi, iwọ le ba a ronu pe bi ẹnikan ba nilati jiya titi ayeraye ninu ọrun apaadi, oun nilati ni aileku ọkan. Onigbagbọ ninu ọrun apaadi yoo gba laijanpata. Lẹhin naa iwọ le mẹnukan akọsilẹ iṣẹda Adamu ati Efa ki o si finurere beere bi o ba tii ṣakiyesi ninu akọsilẹ yẹn rí bi a ba mẹnukan iru aileku ọkan eyikeyii bẹẹ. Ni titẹsiwaju pẹlu ibanironu rẹ, iwọ lẹhin naa le pe afiyesi rẹ si Jẹnẹsisi 2:7, nibi ti Bibeli ti sọ fun wa pe Adamu di ọkàn kan. Si ṣakiyesi ohun ti Ọlọrun sọ pe yoo jẹ iyọrisi ẹṣẹ Adamu: “Ni oogun oju rẹ ni iwọ yoo maa jẹun, titi iwọ yoo fi pada si ilẹ; nitori inu rẹ̀ ni a ti mu ọ wá, erupẹ ṣa ni iwọ, iwọ yoo si pada di erupẹ.” (Jẹnẹsisi 3:19) Fun idi yii, Adamu ọkàn naa pada si inu erupẹ.

10 Iwọ tun le pe afiyesi si otitọ naa pe ko si ibi kankan ninu akọsilẹ Jẹnẹsisi ti Ọlọrun ti mẹnukan ijiya ayeraye ninu ọrun apaadi. Nigba ti Ọlọrun kilọ fun Adamu lati maṣe jẹ ninu eso ti a kà leewọ naa, o wi pe: “Ni ọjọ ti iwọ ba jẹ ninu rẹ̀ kiku ni iwọ yoo ku.” (Jẹnẹsisi 2:17) A ko mẹnukan ọrun apaadi kankan. Bi iyọrisi ẹṣẹ tootọ fun Adamu ko ba nilati jẹ, ‘pipada si erupẹ,’ iku, bikoṣe iye ayeraye, nitori idajọ ododo Ọlọrun ko ha ti ni ṣalaye eyi ni kedere bi? Fun idi yii, ibanironupọ oniṣọọra ati oninuure le ran olootọ ọkan kan lọwọ lati ri awọn aiṣedeedee igbagbọ rẹ̀. Njẹ ki awa maṣe gbojufo ijẹpataki wiwa ọna ibanironupọ lae bi a ti nṣajọpin otitọ Ọrọ Ọlọrun pẹlu awọn ẹlomiran.—Fiwe 2 Timoti 2:24-26; 1 Johanu 4:8, 16.

Awọn Animọ Ti A Nilo fun Ijumọsọrọpọ Ti O Gbeṣẹ

11-13. Awọn animọ Kristẹni wo ni o le ran wa lọwọ lati jumọsọrọpọ lọna gbigbeṣẹ?

11 Nisinsinyi, awọn animọ wo ni a gbọdọ mu dagba ki a ba le sọ awọn otitọ Ijọba lọna ti o gbeṣẹ julọ? O dara, ki ni apẹẹrẹ Jesu sọ fun wa? Ni Matiu 11:28-30, a ka ọrọ rẹ̀ pe: “Ẹ wa sọdọ mi gbogbo ẹyin ti ńṣíṣẹ̀ẹ́ ti a si di ẹru wiwuwo le lori, emi yoo si fi isinmi fun yin. Ẹ gba ajaga mi si ọrun yin, ki ẹ si maa kọ ẹkọ lọdọ mi; nitori oninu tutu ati onirẹlẹ ọkan ni emi; ẹyin yoo si ri isinmi fun ọkan yin. Nitori ajaga mi rọrun, ẹru mi si fuyẹ.” Nibẹ ni a ti ri ọkan lara awọn kọkọrọ aṣeyọri si rere tí Jesu ní ninu ijumọsọrọpọ. Oun jẹ oninu tutu ati onirẹlẹ ọkan. Awọn eniyan ọlọkan rere ri i pé ó jẹ́ atunilara. Apọsiteli Pọọlu tun fi apẹẹrẹ rere kan lelẹ, nitori, gẹgẹ bi o ti sọ fun awọn alagba lati Efesu, lati ọjọ akọkọ ti o ti de ọdọ wọn, oun ńṣẹrú fun Oluwa “pẹlu irẹlẹ ero-inu gigajulọ.”—Iṣe 20:19, NW.

12 Nipa fifi ẹmi irẹlẹ ati irẹlẹ ero inu han nigba gbogbo, awọn miiran yoo ri i pe awa pẹlu jẹ atunilara, yoo si rọrun fun wa lati jumọsọrọpọ pẹlu wọn. Iṣarasihuwa eyikeyii miiran ṣeeṣe ki o gbe idena kan dide laaarin wa ati awọn wọnni ti a ngbiyanju lati ba jumọsọrọpọ. Nitootọ, “ọgbọ́n wà pẹlu onirẹlẹ.”—Owe 11:2.

13 Ki a baa le fi isọfunni tóni leti lọna gbigbeṣẹ, awa tun nilati jẹ onisuuru ati ọlọgbọn ẹwẹ. Apọsiteli Pọọlu dajudaju jẹ ọlọgbọn ẹwẹ nigba ti o jẹrii fun awọn ọmọran ti wọn pejọ ni iwaju rẹ lori Oke Mars. O sọ ihinrere naa ni ọna kan ti wọn le loye. (Iṣe 17:18, 22-31) Bi awa ba fẹ lati jumọsọrọpọ lọna aṣeyọri si rere pẹlu awọn ti nfetisilẹ si wa, awa gbọdọ kọbiara si imọran tí apọsiteli Pọọlu fi fun awọn ara Kolose nigba ti o wi pe: “Ẹ jẹ ki ibanisọrọpọ yin jẹ oloore ọfẹ nigba gbogbo, kí ó má jẹ eyi ti o tẹ́ lae; ẹ kẹkọọ bi o ti dara julọ lati sọrọ pẹlu ẹnikọọkan ti ẹ ba bá pade.” (Kolose 4:6, The New English Bible) Ọrọ sisọ wa nilati dùn-úngbọ́ nigba gbogbo. Iru ọrọ sisọ bẹẹ yoo ni itẹsi lati ṣi ero inu awọn olufetisilẹ wa, nigba ti o jẹ pe ọrọ alailọgbọn yoo mu ki wọn sé ọkan wọn.

14. Bawo ni ifarabalẹ, iyọsini olubanisọrọpọ ṣe le ran wa lọwọ lati jumọsọrọpọ pẹlu awọn ẹlomiran?

14 A fẹ farahan bi ẹni ti o fara balẹ nigba gbogbo. Eyi yoo ṣeranlọwọ lati mu ki ọkan awọn olufetisilẹ wa balẹ. Jijẹ ẹni ti o fara balẹ tumọ si ṣiṣai ṣaniyan pupọ ju lati danikan sọ gbogbo ọrọ. Kaka bẹẹ, pẹlu iṣarasihuwa alaikanju ati awọn ibeere lọna bi ọrẹ, a fun awọn olufetisilẹ wa ni anfaani lati ṣalaye araawọn. Ni pataki nigba ti a ba njẹrii laijẹ bi aṣa o ba ọgbọn mu lati fun awọn ẹlomiran ni iṣiri lati sọrọ. Gẹgẹ bi apẹẹrẹ, Ẹlẹrii kan rii pe oun jokoo lẹgbẹ alufaa Roman Katoliki kan ninu ọkọ ofuurufu nigba kan rí. Fun ohun ti o ju wakati kan lọ, Ẹlẹrii naa ṣaa nfibeere ọlọgbọn ẹwẹ wá alufaa naa lẹnuwo, ti alufaa naa si sọ ọpọjulọ ọrọ naa ni fifesi. Ṣugbọn nigba ti wọn fi maa pinya, alufaa naa ti gba awọn itẹjade Bibeli melookan. Iru iyọsini onisuuru bẹẹ yoo ran wa lọwọ lati lo animọ ṣiṣekoko miiran, tii ṣe ifọran rora ẹni.

15, 16. Bawo ni ifọran rora ẹni ṣe le ran wa lọwọ lati jumọsọrọpọ?

15 Ifọran rora ẹni tumọ si fifi araawa si ipo awọn ẹlomiran ki a sọ ọ lọna bẹẹ. Apọsiteli Pọọlu mọriri aini naa fun ifọran rora ẹni wo ni kikun, gẹgẹ bi a ti le ri i lati inu ohun ti o kọ si awọn ara Kọrinti: “Nitori bi mo ti jẹ ominira kuro lọdọ gbogbo eniyan, mo sọ araami di ẹru gbogbo wọn, ki emi ki o le jere pupọ sii. Ati fun awọn Juu mo dabii Juu, ki emi ki o le jere awọn Juu; fun awọn ti nbẹ labẹ ofin, bi ẹni ti nbẹ labẹ ofin, ki emi ki o le jere awọn ti nbẹ labẹ ofin; fun awọn alailofin bi alailofin (emi kii ṣe alailofin si Ọlọrun, ṣugbọn emi nbẹ labẹ ofin si Kristi) ki emi ki o le jere awọn alailofin. Fun awọn alailera mo di alailera, ki emi ki o le jere alailera: mo di ohun gbogbo fun gbogbo eniyan, ki emi ki o le gba diẹ là bi o ti wu ki o ri.”—1 Kọrinti 9:19-22.

16 Lati ṣafarawe apọsiteli Pọọlu ni awọn ọna wọnyi, a nilati jẹ ọlọgbọn ẹwẹ, amoye, ati alakiyesi. Ifọran rora ẹni yoo ran wa lọwọ lati ba awọn olufetisilẹ wa sọrọ otitọ ni ibamu pẹlu ọna ironu ati imọlara wọn. Itẹjade naa Reasoning From the Scriptures fun wa ni iranlọwọ ni agbegbe yii. Maa mu un dani ninu iṣẹ-ojiṣẹ nigba gbogbo.

Ifẹ—Aranṣe Kan Ninu Ijumọsọrọpọ

17. Laaarin gbogbo awọn animọ Kristẹni, ewo ni o niye lori julọ ninu bibani sọrọ nipa otitọ lọna gbigbeṣẹ, bawo si ni a ṣe fihan?

17 Ẹmi irẹlẹ, irẹlẹ ero-inu, suuru, ati ifọran rora ẹni ṣekoko fun ijumọsọrọpọ gbigbeṣẹ ninu fifunni ni isọfunni. Bi o ti wu ki o ri, ju gbogbo rẹ̀ lọ, ifẹ ainimọtara ẹni nikan yoo ràn wá lọwọ lati jẹ alaṣeyọri si rere ninu dide inu ọkan-aya awọn ẹlomiran. Jesu nimọlara aanu fun awọn eniyan nitori pe wọ́n “jẹ wọ́n kan eegun wọn si ti tu wọn kaakiri gẹgẹ bi agutan laisi oluṣọ agutan.” Ifẹ ni o sún Jesu lati wi pe: “Ẹ wa sọdọ mi gbogbo ẹyin ti ńṣíṣẹ̀ẹ́, ti a si di ẹru wiwuwo le lori, emi yoo si fi isinmi fun yin.” (Matiu 9:36, NW; 11:28) O jẹ nitori pe a nifẹẹ wọn ni awa pẹlu ṣe nfẹ lati tu awọn eniyan lara ki a si ran wọn lọwọ lati bọ soju ọna iye. Tiwa ni ihin-iṣẹ ifẹ, nitori naa ẹ jẹ ki a maa baa lọ ni sisọ ọ tifẹtifẹ. Ifẹ yii fi araarẹ han nipa ẹrin musẹ lọna bi ọrẹ, nipa inurere ati wiwa jẹẹjẹẹ, nipa didaraya ati ẹmi ọyaya.

18. Bawo ni a ṣe le ṣafarawe Pọọlu, gẹgẹ bi oun ti ṣafarawe Ọga naa?

18 Ni ọna yii apọsiteli Pọọlu jẹ alafarawe Ọga rẹ̀, Jesu Kristi lọna rere. Eeṣe ti oun fi jẹ alaṣeyọri si rere tobẹẹ ninu dida ijọ kan silẹ lẹhin omiran? Ṣe nitori itara rẹ ni? Bẹẹni. Ṣugbọn pẹlu nitori ifẹ ti o fihan. Ṣakiyesi awọn ọrọ ifẹni rẹ̀ nipa ijọ titun ti o wa ni Tẹsalonika pe: “Awa nṣe pẹlẹ lọdọ yin gẹgẹ bi abiyamọ, ti ntọju awọn ọmọ oun tikaraarẹ: bẹẹ gẹgẹ bi awa ti ni ifẹ inurere si yin, inu wa dun jọjọ lati fun yin kii ṣe ihinrere Ọlọrun nikan, ṣugbọn ẹmi awa tikaraawa pẹlu, nitori ti ẹyin jẹ ẹni ọ̀wọ́n fun wa.” Ṣiṣafarawe Pọọlu yoo ràn wá lọwọ ninu awọn isapa wa lati jumọsọrọpọ.—1 Tẹsalonika 2:7, 8.

19. Eeṣe ti a ko fi nilati jẹ ki ipinlẹ ti wọn ko ti fetisilẹ mu wa rẹwẹsi?

19 Bi awa ba ti ṣe ohun ti a le ṣe lati jumọsọrọpọ ti a si kuna lati ri abajade ti a nfẹ, o ha yẹ ki a rẹwẹsi bi? Bẹẹkọ rara. Awọn Akẹkọọ Bibeli (gẹgẹ bi a ti npe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tẹlẹ) saba maa nsọ pe ki a baa le tẹwọgba otitọ, awọn eniyan nilo animọ mẹta. Wọn nilati jẹ alailabosi, onirẹlẹ, ati ẹni ti ebi tẹmi npa. Awa ko le reti pe ki awọn eniyan alailootọ ọkan, awọn alabosi, fi ojurere dahun pada si otitọ; bẹẹ si ni awa ko le reti pe ki awọn eniyan onirera ati agberaga fetisilẹ si ihinrere. Siwaju sii, ani bi ẹnikan ba tilẹ ni iwọn ailabosi ati ẹmi irẹlẹ gan an, o ṣeeṣe ki oun ma tẹwọgba otitọ bi ebi tẹmi ko ba pa a.

20. Eeṣe ti a fi le sọ ni gbogbo igba pe awọn isapa wa ko jasi asan?

20 Laiṣiyemeji ọpọlọpọ ti iwọ yoo pade ni ipinlẹ rẹ yoo ṣalaini ọkan lara awọn animọ mẹta yii. Wolii Jeremaya ni iriri kan naa. (Jeremaya 1:17-19; fiwe Matiu 5:3.) Sibẹ, awọn isapa wa kii ṣe lasan. Eeṣe? Nitori pe a npolongo orukọ ati Ijọba Jehofa. Nipa wiwaasu wa ati nipa wiwa nibẹ wa gan an, a nkilọ fun awọn oluṣe buburu. (Esekiẹli 33:33) Ki a ma si ṣe gbagbe lae pe nipa awọn isapa wa lati ba awọn ẹlomiran sọrọ otitọ, a janfaani funraawa. (1 Timoti 4:16) A npa igbagbọ wa mọ́ ni lilagbara ati ireti Ijọba wa mọ́ ni didan yanranyanran. Ju bẹẹ lọ, a di iwatitọ wa mu a si tipa bayii ṣajọpin ninu yiya orukọ Jehofa Ọlọrun si mimọ, ni mimu ki ọkan rẹ̀ layọ.—Owe 27:11.

21. Ki ni a le sọ ni akopọ?

21 Lakoopọ: Ijumọsọrọpọ jẹ fifi isọfunni tóni leti lọna gbigbeṣẹ. Ọna ijumọsọrọpọ ṣe koko, ọpọlọpọ ipalara ni o si nyọrisi nigba ti ijumọsọrọpọ kan ba wo lulẹ. A ti ri i pe Jehofa Ọlọrun ati Jesu Kristi jẹ awọn olubanisọrọpọ ti wọn gba ipo iwaju julọ ati pe Jesu Kristi paṣẹ ọ̀nà ijumọsọrọpọ kan fun ọjọ wa. A tun ti ṣakiyesi pe nipa imura ati iwa wa, a njumọsọrọpọ, ni fifi awọn iṣẹ ranṣẹ si awọn ẹlomiran. A ti kẹkọọ pe bibanironupọ kó ipa pataki kan ninu gbigbiyanju lati jumọsọrọpọ pẹlu awọn eniyan ati pe lati jumọsọrọpọ lọna gbigbeṣẹ, a nilati jẹ oniwọntunwọnsi ati onirẹlẹ, ki a fi ifọran rora ẹni han, ki a lo suuru, ati, ju gbogbo rẹ̀ lọ, ki a sún wa ṣiṣẹ nipasẹ ọkan-aya ti o kun fun ifẹ. Bi a ba mu awọn animọ wọnyi dagba ti a si tẹle awọn apẹẹrẹ Bibeli, awa yoo jẹ Kristẹni olubanisọrọpọ alaṣeyọri si rere.—Roomu 12:8-11.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fun idamọran pupọ sii lori bi o ṣe le jumọsọrọpọ pẹlu awọn Juu onigbagbọ ati awọn miiran, wo Reasoning From the Scriptures, oju-iwe 21 si 24.

Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?

◻ Ni ọna wo ni ijumọsọrọpọ gba bẹrẹ ṣaaju ki a to sọ ọrọ kan?

◻ Ki ni awọn apẹẹrẹ diẹ ti ijumọsọrọpọ nipa ibanironupọ gbigbeṣẹ?

◻ Awọn animọ wo ni o fun Jesu Kristi ati Pọọlu lagbara lati jumọsọrọpọ lọna gbigbeṣẹ?

◻ Eeṣe ti a ko fi nilati rẹwẹsi bi a ko ba tete ri abayọri?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́