ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/02 ojú ìwé 8
  • Jẹ́ Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Tí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Ń Wọni Lọ́kàn!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Tí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Ń Wọni Lọ́kàn!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jehofa ati Kristi Awọn Olubanisọrọpọ Ti Wọn Gba Ipo Iwaju Julọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ijumọsọrọpọ Ninu Iṣẹ-ojiṣẹ Kristẹni
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Jijumọsọrọpọ Laaarin Idile ati Ninu Ijọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Dídán Mọ́rán—Àṣírí Ìgbéyàwó Aláṣeyọrí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 8/02 ojú ìwé 8

Jẹ́ Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Tí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Ń Wọni Lọ́kàn!

1 Ká tó lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tá a gbé lé wa lọ́wọ́, ó di dandan ká bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ lè jẹ́ ìṣòro, kódà láàárín àwọn ọ̀rẹ́ pàápàá. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti sọ ìhìn rere náà fún àwọn àjèjì lọ́nà tó máa fi wọ̀ wọ́n lọ́kàn?

2 Jẹ́ Kí Onílé Mọ̀ Pé O Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Òun: Gbìyànjú láti fi ara rẹ sípò àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Nítorí bí ayé ṣe rí lónìí, a lè lóye ìdí táwọn kan fi máa ń fura sí àwọn àjèjì tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa bẹ̀rù wọn. Èyí lè máà jẹ́ kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ rọrùn. Báwo lo ṣe lè ṣẹ́pá ìbẹ̀rù táwọn tó ò ń bá pàdé kọ́kọ́ máa ń ní? Ká tiẹ̀ tó ó sọ ohunkóhun rárá, ìmúra wa tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì ń sọ púpọ̀ fún àwọn onílé nípa irú ẹni tá a jẹ́. Mímúra tá a bá múra lọ́nà tó bójú mu àti ìwà ọmọlúwàbí wa máa ń ṣèrànwọ́ láti mú ìbẹ̀rù kúrò.—1 Tím. 2:9, 10.

3 Ohun mìíràn tó tún lè ṣèrànwọ́ fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ni fífara balẹ̀ àti híhùwà bí ọ̀rẹ́. Èyí máa ń mú kára tu àwọn mìíràn ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ fẹ́ láti tẹ́tí sílẹ̀. Ìmúrasílẹ̀ tó dára pọn dandan ká tó lè ṣe èyí. Nígbà tá a bá ti mọ ohun tá a fẹ́ sọ lọ́kàn wa dáadáa, ara wa máa ń túbọ̀ balẹ̀. Ìṣepẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wa sì lè mú kí àwọn mìíràn nífẹ̀ẹ́ láti gbọ́ ohun tá a fẹ́ sọ fún wọn. Ohun tí obìnrin kan sọ rèé nípa ìbẹ̀wò tí Ẹlẹ́rìí kan ṣe sọ́dọ̀ rẹ̀: “Ohun tí mo máa ń rántí nípa ẹ̀rín músẹ́ rẹ̀ ni ìbàlẹ̀ ọkàn tó ní. Ara mi ti wà lọ́nà láti gbọ́ ohunkóhun tó fẹ́ sọ.” Èyí ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún obìnrin náà láti tẹ́tí sílẹ̀ gbọ́ ìhìn rere náà.

4 Àwọn Ànímọ́ Tó Ń Fani Mọ́ra: Ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ kí ire àwọn ẹlòmíràn jẹ wá lọ́kàn gan-an. (Fílí. 2:4) Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe èyí ni pé kó máà jẹ́ àwa nìkan la ó máa sọ̀rọ̀ láìjẹ́ kí onílé sọ sí i. Ó ṣe tán, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ kan fífetísílẹ̀. Nígbà tá a bá rọ àwọn olùgbọ́ wa láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, tá a sì fi tọkàntọkàn tẹ́tí sílẹ̀ sí wọn, wọ́n á rí i pé a bìkítà nípa wọn. Nítorí náà, nígbà tí àwọn olùgbọ́ rẹ bá ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, má máa kánjú wá bó o ṣe máa ráyè padà sórí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ tó o ti múra sílẹ̀. O lè rí i bí ohun tó bọ́gbọ́n mu láti yìn wọ́n dáadáa, sì gbìyànjú láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ dá lórí ohun tí wọ́n bá sọ. Bí ọ̀rọ̀ wọn bá fi hàn pé ohun kan ń dà wọ́n láàmú, yí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ padà lọ́nà tó fi máa bá ohun tó ń dà wọ́n lọ́kàn rú yẹn mu.

5 Àìjọra-ẹni-lójú àti jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní èrò inú máa ń jẹ́ kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ lọ bó ṣe yẹ. (Òwe 11:2; Ìṣe 20:19) Nítorí pé Jésù jẹ́ “onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà” làwọn èèyàn ṣe máa ń fà sún mọ́ ọn. (Mát. 11:29) Ní ìdàkejì sí ìyẹn, ńṣe ni fífi ara ẹni hàn bí ẹni tó jọra rẹ̀ lójú máa ń mú káwọn èèyàn yẹra fúnni. Nípa bẹ́ẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dá wa lójú hán-ún pé òtítọ́ lohun tá à ń wàásù rẹ̀, kò ní dáa ká máa sọ̀rọ̀ bíi pé a kì í gbọ́ ti àwọn ẹlòmíràn mọ́ tiwa.

6 Ká wá ní ọ̀rọ̀ ẹni yẹn fi hàn pé ohun tó gbà gbọ́ kò bá ohun tí Bíbélì fi kọ́ni mu ńkọ́? Ṣé ó yẹ ká tún èrò rẹ̀ ṣe? Bẹ́ẹ̀ ni, tó bá tó àkókò, àmọ́ a ò ní gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ tá a bá a pàdé yẹn. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń ṣàǹfààní láti jẹ́ kí ohun tá a máa bá olùgbọ́ wa sọ dá lórí àwọn ohun tá a jọ gbà pé ó tọ̀nà, ká tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá máa sọ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó lè ṣòro fún un láti gbà gbọ́. Èyí ń béèrè sùúrù àti ọgbọ́n. Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dára gan-an lélẹ̀ nípa kókó yìí nígbà tó ń jẹ́rìí fún àwọn adájọ́ tó wà ní ilé ẹjọ́ Áréópágù.—Ìṣe 17:18, 22-31.

7 Lékè gbogbo rẹ̀, ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan á ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ asọ̀rọ̀ tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọni lọ́kàn. Bíi ti Jésù, àánú àwọn èèyàn tí a ti ‘bó láwọ, tí a sì fọ́n ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn’ gbọ́dọ̀ máa ṣe wá. (Mát. 9:36) Èyí ló máa sún wa láti lọ sọ ìhìn rere náà fún wọn, a ó sì lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa rìn ní ọ̀nà ìyè. Ìhìn ìfẹ́ là ń jẹ́, nítorí náà ẹ́ jẹ́ ká máa sọ ọ́ lọ́nà tó fi ìfẹ́ hàn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń fara wé Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi—tí wọ́n jẹ́ Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó gbéṣẹ́ jù lọ láyé àtọ̀run.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́