Àwọn Ohun Tó Lè Mú Kí Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Máa Lọ Déédéé Láàárín Tọkọtaya
‘KÒ YẸ kí n sọ ohun tí mo sọ yẹn.’ ‘Mi ò ṣàlàyé ara mi dáadáa rárá.’ Ǹjẹ́ ó ti ṣe ọ́ bẹ́ẹ̀ rí lẹ́yìn tó o bá ọkọ tàbí aya rẹ sọ̀rọ̀? Ó yẹ kéèyàn mọ bá a ṣe ń báni sọ̀rọ̀. Èyí rọrùn fáwọn kan, àmọ́ ìṣòro ni fáwọn míì. Tó o bá tiẹ̀ wà lára àwọn tó ṣòro fún, o ṣì lè mọ béèyàn ṣe ń báni sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ọ̀rọ̀ rẹ á fi tuni lára, tí ọ̀rọ̀ rẹ á sì yéni.
Láwọn ibì kan, àṣà ìbílẹ̀ ló ń pinnu ìwà táwọn kan máa ń hù sí ọkọ tàbí aya wọn. Wọ́n á máa sọ pé ‘ọkùnrin tó bá tọ́kùnrin kì í sọ̀rọ̀ púpọ̀.’ Ojú ẹni tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ṣeé tẹ̀ lé sì ni wọ́n fi ń wo ọkùnrin tó bá ń rojọ́ jù. Lóòótọ́, Bíbélì sọ pé: “Kí olúkúlùkù ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.” (Jákọ́bù 1:19) Síbẹ̀, àtọkùnrin àtobìnrin ni ìmọ̀ràn yìí wà fún, ó sì fi hàn pé kì í ṣe kéèyàn kàn ti lanu sọ̀rọ̀ ni ìjùmọ̀sọ̀rọ̀. Ẹni méjì lè máa bára wọn sọ̀rọ̀ fún ọ̀pọ̀ àkókò, àmọ́ tí wọn ò bá tẹ́tí sí ara wọn ńkọ́? Kò dájú pé wọ́n á gbọ́ ara wọn yé. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí jẹ́ ká rí i pé ohun pàtàkì kan tó máa jẹ́ kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ lọ déédéé ni pé kéèyàn mọ bí wọ́n ṣe ń fetí sílẹ̀.
Àwọn Tó Ń Fi Ìṣesí Bára Wọn Sọ̀rọ̀
Àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan ò gba àwọn obìnrin láyè láti máa dá sí ọ̀rọ̀ láwùjọ. Wọ́n sì gbà pé kò yẹ kí ọkọ tiẹ̀ dá sí ọ̀rọ̀ ìdílé rárá. Nírú àgbègbè bẹ́ẹ̀, òye ni tọkọtaya sábà máa ń lò láti fi mọ ohun tí ẹnì kìíní kejì ń fẹ́. Àwọn aya kan ti mọ bí wọ́n ṣe ń fòye mọ ohun tí ọkọ wọn ń fẹ́, tí wọ́n á sì ṣe é láìjáfara. Nírú àwọn ibi bẹ́ẹ̀, ìṣesí làwọn tọkọtaya fi ń bára wọn sọ̀rọ̀. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ńṣe ni irú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń pọ̀n sọ́nà kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aya lè gbìyànjú láti mọ ohun tí ọkọ ń rò tàbí tó ń fẹ́, kò sẹ́ni tó retí pé kí ọkọ fòye mọ ohun tí aya ń fẹ́.
Òótọ́ ni pé nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan, àwọn ọkùnrin máa ń kíyè sí àwọn aya wọn láti mọ ohun tí wọ́n nílò, wọ́n á sì ṣe é. Síbẹ̀, nírú àwọn àdúgbò bẹ́ẹ̀ pàápàá, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dára jùyẹn lọ á ṣe ọ̀pọ̀ ìdílé láǹfààní.
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Ṣe Pàtàkì
Báwọn èèyàn bá ń bára wọn sọ̀rọ̀ láìfi nǹkan kan pa mọ́, àìgbọ́ra-ẹni-yé àti aáwọ̀ ò ní sí láàárín wọn. Nígbà kan lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì, ẹ̀yà Rúbẹ́nì, ẹ̀yà Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè tí wọ́n ń gbé ní ìlà oòrùn Odò Jọ́dánì mọ “pẹpẹ kan tí ó tóbi lọ́nà tí ó fara hàn gbangba-gbàǹgbà” sẹ́bàá Odò Jọ́dánì. Àmọ́ àwọn ẹ̀yà yòókù tó wà ní ìwọ̀ oòrùn Odò Jọ́dánì gba ohun tí wọ́n ṣe yìí sódì. Wọ́n rò pé àwọn ẹ̀yà méjì àtààbọ̀ náà ti pẹ̀yìn dà sí Jèhófà, pé wọ́n ti di ọlọ̀tẹ̀, ni wọ́n bá múra ogun. Ṣùgbọ́n kí wọ́n tó lọ, wọ́n rán àwọn kan lọ bá àwọn ẹ̀yà tó wà ní ìlà oòrùn yìí. Ohun tí wọ́n ṣe yìí mà bọ́gbọ́n mu o! Wọ́n wá rí i pé kì í ṣe torí àtimáa rúbọ sí òrìṣà làwọn arákùnrin wọn ṣe mọ pẹpẹ náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lẹ̀rù ń bà wọ́n pé káwọn ẹ̀yà yòókù má lọ sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin kò ní ìpín kankan nínú Jèhófà.” Wọ́n fẹ́ fi pẹpẹ náà ṣe ẹ̀rí pé olùjọsìn Jèhófà làwọn náà. (Jóṣúà 22:10-29) Wọ́n pe pẹpẹ náà ní Ẹ̀rí, bóyá nítorí ó jẹ́ ẹ̀rí pé wọ́n gbà pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.—Jóṣúà 22:34.
Àlàyé tí wọ́n ṣe jẹ́ kó dá àwọn ẹ̀yà yòókù lójú pé òótọ́ ni wọ́n ń sọ, ìyẹn ló mú káwọn yẹn yí èrò wọn padà tí wọn ò wá bá wọn jà mọ́. Láìsí àní-àní, òótọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá ara wọn sọ ni ò jẹ́ kí ogun bẹ́ sílẹ̀. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn, nígbà tí Ísírẹ́lì ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run tó dà bí ọkọ fún wọn, ó sọ fún wọn pé òun yóò fi tàánútàánú ‘bá ọkàn wọn sọ̀rọ̀.’ (Hóséà 2:14) Àpẹẹrẹ yìí mà dára fún àwọn tọkọtaya o! Gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa wọ ọkọ tàbí aya rẹ lọ́kàn kó lè mọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ. Èyí ṣe pàtàkì gan-an, pàápàá tó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ẹlẹgẹ́ lẹ fẹ́ sọ. Obìnrin akọ̀ròyìn kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó ń jẹ́ Pattie Mihalik sọ pé: “Àwọn kan máa ń sọ pé ọ̀rọ̀ sísọ kì í náni ní nǹkan kan rárá, àmọ́ ọ̀rọ̀ ṣeyebíye débi pé kò ṣeé fowó rà lọ́jà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ ló máa ń nira fún àwọn kan láti sọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn, síbẹ̀ àǹfààní ibẹ̀ pọ̀ gan-an ju kéèyàn fi owó sí báńkì lọ.”
Ẹ Rí I Pé Ẹ̀ Ń Bá Ara Yín Sọ̀rọ̀ Dáadáa
Àwọn kan lè sọ pé, ‘Àti ìbẹ̀rẹ̀ ni nǹkan ti wọ́ nínú ìgbéyàwó wa.’ Àwọn ẹlòmíì lè sọ pé, ‘Kò sóhun tó lè dá ìgbéyàwó wa dúró kó má tù ú.’ Wọ́n lè máa rò pé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ àwọn ò lè dán mọ́rán sí i lẹ́yìn ìgbéyàwó. Àmọ́, ronú nípa àwọn tó jẹ́ pé nínú àṣà ìbílẹ̀ wọn, àwọn mọ̀lẹ́bí ló ń yan ọkọ tàbí aya fún wọn. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló jẹ́ pé, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dán mọ́rán máa ń wà láàárín wọn bí wọ́n ṣe ń bára wọn gbé.
Níbì kan ní Ìlà Oòrùn Ayé, ńṣe ni wọ́n bá ọkùnrin kan fẹ́ ìyàwó rẹ̀. Ìránṣẹ́ kan ni wọ́n rán lọ sọ́nà jíjìn láti lọ wá aya fún ọkùnrin ọ̀hún tó ń jẹ́ Ísákì. Síbẹ̀, tọkọtaya yìí, tó gbé ayé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọdún sẹ́yìn, mọwọ́ ara wọn débi pé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ wọn máa ń dán mọ́rán. Inú pápá ni Ísákì ti pàdé alárinà àti aya rẹ̀. Ẹni tó ṣe alárinà wọn “sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣèròyìn fún Ísákì nípa gbogbo ohun tí òun ti ṣe.” Ìtàn Bíbélì nípa ìgbéyàwó yìí sọ pé: “Lẹ́yìn ìyẹn, Ísákì mú obìnrin náà [Rèbékà] wọ inú àgọ́ Sárà ìyá rẹ̀ [ohun tó ṣe yìí ló dúró fún ìgbéyàwó]. Nípa báyìí, ó mú Rèbékà, ó sì di aya rẹ̀; ó sì kó sínú ìfẹ́ fún obìnrin náà.”—Jẹ́nẹ́sísì 24:62-67.
Kíyè sí i pé Ísákì kọ́kọ́ gbọ́ ìròyìn nípa Rèbékà, “lẹ́yìn ìyẹn” ló wá fi ṣe aya. Ìránṣẹ́ kan tó ṣeé gbára lé, ẹni tó ń fi tọkàntọkàn sin Jèhófà Ọlọ́run bíi ti Ísákì sì ni alárinà wọn. Nítorí náà, ìdí tó ṣe gúnmọ́ wà tí Ísákì fi lè gbẹ́kẹ̀ lé ọkùnrin yìí. Ẹ̀yin gbogbo èyí ni Ísákì wá “kó sínú ìfẹ́” fún Rèbékà ìyàwó rẹ̀.
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ Ísákì àti Rèbékà máa ń yéra wọn? Lẹ́yìn tí Ísọ̀ ọmọ wọn lọ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin Hétì méjì, ìṣòro ńlá kan bẹ́ sílẹ̀ nínú ìdílé wọn. Rèbékà “ń wí ṣáá fún” Ísákì pé: “Mo ti wá fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ìgbésí ayé tèmi yìí nítorí àwọn ọmọbìnrin Hétì. Bí Jékọ́bù [tó jẹ́ àbúrò] bá lọ mú aya nínú àwọn ọmọbìnrin Hétì . . . , ire wo ni ìgbésí ayé jẹ́ fún mi?” (Jẹ́nẹ́sísì 26:34; 27:46) Kò sí àní-àní pé, bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀ gan-an ló sọ fún ọkọ rẹ̀.
Ísákì baba wọn sọ fún Jákọ́bù tí òun pẹ̀lú Ísọ̀ jọ jẹ́ ìbejì pé kò gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin Kénáánì. (Jẹ́nẹ́sísì 28:1, 2) Èyí fi hàn pé ọ̀rọ̀ Rèbékà yé Ísákì. Àwọn méjèèjì jọ sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ ẹlẹgẹ́ yìí, wọ́n sì gbọ́ ara wọn yé, èyí tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wa lónìí. Àmọ́ o, tí èdèkòyédè bá wà láàárín tọkọtaya ńkọ́? Kí ni wọ́n lè ṣe?
Bí Èdèkòyédè Bá Wà Láàárín Tọkọtaya Ńkọ́?
Bí èdèkòyédè bá wà láàárín ìwọ àti ẹnì kejì rẹ, má ṣe di kùnrùngbùn. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé inú rẹ ò dùn, o ò sì fẹ́ kí inú ọkọ tàbí aya rẹ náà dùn. Bẹ́ẹ̀, ọkọ rẹ tàbí aya rẹ lè má mọ ohun tó ò ń fẹ́ àti ohun tó ń dùn ọ́.
Ohun tó máa dára kí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ ṣe ni pé kẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ náà kó yanjú. Bó bá jẹ́ ọ̀rọ̀ tó lè mú kí ẹnì kejì gbaná jẹ ni, ó lè má rọrùn láti fi sùúrù sọ ọ́. Àkókò kan wà tí ìṣòro ńlá kan wà nínú ìdílé Ábúráhámù àti Sárà, àwọn òbí Ísákì. Nítorí pé àgàn ni Sárà, ó fi Hágárì ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ fún Ábúráhámù ọkọ rẹ̀ kí Hágárì lè bímọ fún un, gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn láyé ìgbà yẹn. Hágárì wá bí ọmọkùnrin kan fún Ábúráhámù, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Íṣímáẹ́lì. Àmọ́ nígbà tó yá, Sárà alára lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan tí wọ́n sọ ní Ísákì. Nígbà tí Sárà fẹ́ já Ísákì lẹ́nu ọmú, ó rí i pé Íṣímáẹ́lì ń fi ọmọ òun ṣe yẹ̀yẹ́. Sárà wòye pé inú ewu lọmọ òun wà, ló wá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ Ábúráhámù pé kó lé ẹrúbìnrin yìí àti Íṣímáẹ́lì ọmọ rẹ̀ jáde. Dájúdájú, Sárà sọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀. Àmọ́ inú Ábúráhámù kò dùn sóhun tó ní kó ṣe yẹn rárá.
Báwo ni wọ́n ṣe wá yanjú ọ̀rọ̀ yìí? Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run wí fún Ábúráhámù pé: ‘Má ṣe jẹ́ kí ohun tí Sárà ń sọ fún ọ di ohun tí kò dùn mọ́ ọ nínú nípa ọmọdékùnrin náà àti nípa ẹrúbìnrin rẹ. Fetí sí ohùn rẹ̀, nítorí pé nípasẹ̀ Ísákì ni ohun tí a ó pè ní irú-ọmọ rẹ yóò wà.’” Ábúráhámù ṣe ohun tí Jèhófà Ọlọ́run sọ.—Jẹ́nẹ́sísì 16:1-4; 21:1-14.
O lè máa sọ pé: ‘Ká ní Ọlọ́run lè máa bá wa sọ̀rọ̀ látọ̀run ni, yóò rọrùn fún wa láti yanjú èdèkòyédè tó bá wáyé!’ Èyí ló mú wa dé orí ohun pàtàkì míì tó lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ láti yanjú èdèkòyédè tó bá wáyé. Ó ṣeé ṣe fáwọn tọkọtaya láti gbọ́ ohun tí Ọlọ́run ń sọ. Lọ́nà wo? Nípa jíjùmọ̀ ka Bíbélì àti gbígba ohun tó bá sọ gẹ́gẹ́ bí ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.—1 Tẹsalóníkà 2:13.
Obìnrin Kristẹni kan tó ní ìrírí sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé bí abilékọ kan bá wá bá mi pé kí n fóun nímọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ lọ́kọláya, màá bi í bóyá òun àti ọkọ rẹ̀ máa ń ka Bíbélì pa pọ̀. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó ní ìṣòro nínú ìgbéyàwó wọn ló jẹ́ pé wọn kì í ka Bíbélì pa pọ̀.” (Títù 2:3-5) Gbogbo wa la lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ọ̀rọ̀ arábìnrin yẹn. Rí i pé ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ jọ ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa dà bíi pé ò ń gbọ́ tí Ọlọ́run ń bá ọ sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe yẹ kó o máa hùwà lójoojúmọ́. (Aísáyà 30:21) Ṣùgbọ́n ṣọ́ra fún nǹkan kan o. Má ṣe sọ Bíbélì di pàṣán tí wàá máa fi na ọkọ tàbí aya rẹ, kó jẹ́ pé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o rò pé ọkọ tàbí aya rẹ kì í tẹ̀ lé ni wàá kàn máa tọ́ka sí ṣáá. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbìyànjú láti wo bí ẹ̀yin méjèèjì ṣe lè fi ohun tẹ́ ẹ̀ ń kà sílò.
Tó o bá ń gbìyànjú láti yanjú ìṣòro ńlá kan, o ò ṣe wo ohun tí ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Indexa sọ nípa ohun náà gan-an? Ó lè jẹ́ pé ò ń tọ́jú àwọn òbí tó ti dàgbà, tí ìyẹn sì ń fa wàhálà nínú ìdílé yín. Dípò tí wàá fi máa bá ọkọ tàbí aya rẹ jiyàn lórí ohun tó yẹ kó ṣe tàbí tí kò yẹ kó ṣe, ẹ̀yin méjèèjì ò ṣe jókòó, kẹ́ ẹ jọ wo ìwé atọ́ka yẹn pa pọ̀? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ wo àkòrí náà “Parents” (Àwọn Òbí). Ẹ lè wo àwọn kókó tó wà lábẹ́ àwọn ìsọ̀rí tó wà níbẹ̀, irú bí “caring for aged parents” (bíbójútó àwọn òbí tó ti dàgbà). Ẹ jọ ka àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ lórí kókó wọ̀nyí nínú àwọn ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìyàlẹ́nu ló máa jẹ́ fún ọ láti rí bí àǹfààní tí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ yóò jẹ látinú àwọn ìtọ́ni tá a gbé ka Bíbélì yẹn á ṣe pọ̀ tó, èyí tó ti ran ọ̀pọ̀ ojúlówó Kristẹni lọ́wọ́.
Tẹ́ ẹ bá jọ wá àwọn ìwé tí ìwé atọ́ka náà tọ́ka sí, tẹ́ ẹ sì jọ kà wọ́n, ẹ ó mọ ohun tẹ́ ẹ lè ṣe sí ìṣòro yín. Ẹ óò rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí àtàwọn tá a fà yọ tó máa jẹ́ kẹ́ ẹ mọ èrò Ọlọ́run nípa ìṣòro náà. Ẹ wo àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn kẹ́ ẹ sì kà wọ́n pa pọ̀. Ó dájú pé, ẹ óò gbọ́ ohun tí Ọlọ́run sọ nípa ìṣòro yín!
Ẹ Máa Bá Ara Yín Sọ̀rọ̀ Déédéé
Ǹjẹ́ o ti gbìyànjú lọ́jọ́ kan láti ṣí ilẹ̀kùn kan tó ti pẹ́ gan-an tí wọ́n ti ṣí i? Ńṣe ni àgbékọ́ ilẹ̀kùn náà tó ti dógùn-ún yóò máa pariwo bó ṣe ń ṣí díẹ̀díẹ̀. Àmọ́ ká ní ẹ máa ń ṣí ilẹ̀kùn náà déédéé ńkọ́, tẹ́ ẹ sì ń fi epo sáwọn àgbékọ́ rẹ̀ dáadáa? Kò sí àní-àní pé yóò rọrùn láti ṣí. Bákan náà lọ̀rọ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ṣe rí. Bó ṣe jẹ́ pé fífi epo sí àgbékọ́ ilẹ̀kùn máa ń jẹ́ kó rọrùn láti ṣí, tẹ́ ẹ bá ń bá ara yín sọ̀rọ̀ déédéé, tẹ́ ẹ sì ń fi ìfẹ́ hàn sí ara yín, yóò rọrùn fún yín láti máa sọ èrò ọkàn yín, àní bẹ́ ẹ bá ní ìṣòro ńlá pàápàá.
Ibì kan lẹ ti máa bẹ̀rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ lè má rọrùn níbẹ̀rẹ̀, má ṣe jẹ́ kó sú ọ. Bí àkókò ṣe ń lọ, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ yóò máa lọ déédéé, ẹ ó sì máa gbọ́ ara yín lágbọ̀ọ́yé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Bí èdèkòyédè bá wà láàárín ẹ̀yin méjèèjì, ẹ ò ṣe wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run?