Àwọn Ẹlẹ́rìí Ń Borí Onírúurú Ìṣòro ní Panama
“PANAMA, orílẹ̀-èdè tó dà bí afárá tó so ayé pọ̀.” Ní nǹkan bí àádọ́ta ọdún sẹ́yìn, wọ́n máa ń sọ gbólóhùn yẹn nínú ètò orí rédíò kan tó gbajúmọ̀ lórílẹ̀-èdè Panama, èyí tó wà ní àárín Àríwá Amẹ́ríkà àti Gúúsù Amẹ́ríkà. Àmọ́ lónìí, ńṣe ni gbólóhùn yẹn ń sọ èrò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní nípa orílẹ̀-èdè yìí.
Orílẹ̀-èdè Panama dà bí afárá tó so Àríwá Amẹ́ríkà pọ̀ mọ́ Gúúsù Amẹ́ríkà. Yàtọ̀ síyẹn, afárá gidi kan wà níbẹ̀ tí wọ́n ń pè ní Afárá Amẹ́ríkà, èyí tí wọ́n ṣe gba orí Ipadò Panama tó gbajúmọ̀ gan-an. Ipadò náà la orílẹ̀-èdè náà kọjá láti ìpẹ̀kun kan sí èkejì, ó wá so Òkun Àtìláńtíìkì àti Òkun Pàsífíìkì pọ̀. Ká má purọ́, iṣẹ́ ńlá làwọn tó gbẹ́ ipadò náà ṣe. Ibẹ̀ ni ọ̀nà àbùjá táwọn ọkọ̀ ojú omi láti ibi gbogbo láyé ń gbà kọjá láàárín wákàtí díẹ̀ péré, dípò tí wọn ì bá fi máa lo ọ̀pọ̀ ọjọ́ tàbí ọ̀sẹ̀ lórí omi. Bẹ́ẹ̀ ni o, ńṣe ni Panama dà bí afárá tó so ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn orílẹ̀-èdè ayé pọ̀.
Ó Dà Bí Afárá, Ó Tún Jẹ́ Ibi Tí Onírúurú Èèyàn Wà
Panama tún jẹ́ ibi tí onírúurú èèyàn láti ilẹ̀ àti ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti jọ ń gbé pọ̀. Àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè wọ̀nyí àtàwọn ọmọ ìbílẹ̀ sì ti wá pọ̀ gan-an káàkiri orílẹ̀-èdè ẹlẹ́wà yìí. Àmọ́, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí ẹ̀kọ́ iyebíye tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú káwọn èèyàn wọ̀nyí jọ fìmọ̀ ṣọ̀kan, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra, olówó àti tálákà wà láàárín wọn, wọ́n ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n sì ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀?
Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe. Ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Éfésù 2:17, 18 jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, àti Júù àti Kèfèrí, borí irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀, lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi tó ń mú kí ìṣọ̀kan ṣeé ṣe. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ó [Jésù] wá polongo ìhìn rere àlàáfíà fún yín, ẹ̀yin tí ẹ jìnnà réré, àti àlàáfíà fún àwọn tí ń bẹ nítòsí, nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ àwa, ènìyàn méjèèjì, ní ọ̀nà ìwọlé sọ́dọ̀ Baba nípasẹ̀ ẹ̀mí kan.”
Lóde òní náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń polongo “ìhìn rere àlàáfíà” fún àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti ní àwùjọ-àwùjọ tí wọ́n wá sí Panama láti ọ̀nà jíjìn tí ẹ̀sìn wọn sì yàtọ̀ síra. Ìṣọ̀kan tó ń mára tuni wà láàárín àwọn tí wọ́n “ní ọ̀nà ìwọlé sọ́dọ̀” Jèhófà. Látàrí èyí, a ti dá ọ̀pọ̀ ìjọ sílẹ̀ ní Panama ní èdè mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn ni èdè Sípéènì, èdè Káńtọ̀n, Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Panama, èdè Gẹ̀ẹ́sì, àti méjì lára àwọn èdè ìbílẹ̀, ìyẹn Kuna àti Ngobere (Guaymí). Ohun ìwúrí ni yóò jẹ́ tá a bá mọ bí àwọn kan lára àwọn tó ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọ̀nyí ṣe jọ di ọmọ ìyá nínú ìjọsìn Jèhófà.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Ń Borí Ìṣòro Ní Igbó Tí Ìjọba Yà Sọ́tọ̀
Ẹ̀yà Ngobe ló pọ̀ jù nínú gbogbo ẹ̀yà mẹ́jọ tó para pọ̀ jẹ́ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Panama. Nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́jọ ààbọ̀ [170,000] ni wọ́n, ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló sì ń gbé ní igbó ńlá kan tí ìjọba yà sọ́tọ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí tí wọ́n ń pè ní comarca. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé òkè págunpàgun nìkan ló wà ní gbogbo àgbègbè tó jẹ́ igbó kìjikìji yìí, ẹsẹ̀ nìkan lèèyàn sì fi lè débẹ̀. Bákan náà làwọn ibi ẹlẹ́wà kan tún wà létíkun, tó jẹ́ pé orí òkun nìkan lèèyàn lè gbà débẹ̀. Etí odò àti etíkun làwọn èèyàn sábà máa jọ ń kọ́lé sí, nítorí pé èyí ń jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti rìnrìn-àjò láti ibì kan síbòmíràn. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń gbénú igbó ńlá yìí ló jẹ́ pé ìwọ̀nba ohun tí wọ́n ń rí nínú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe lóko kọfí ní àwọn òkè ńlá, iṣẹ́ ẹja pípa tàbí iṣẹ́ àgbẹ̀ ni wọ́n fi ń gbéra. Ṣọ́ọ̀ṣì ni púpọ̀ lára wọn ń lọ. Àmọ́, àwọn kan wà tí wọ́n ń ṣe ẹ̀sìn ìbílẹ̀ táwọn èèyàn mọ̀ sí Mama Tata. Adáhunṣe (sukias) làwọn míì ń lọ bá fún ìwòsàn tára wọn ò bá yá tàbí tí wọ́n bá rò pé àwọn ẹ̀mí èṣù ń yọ àwọn lẹ́nu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè Sípéènì ni ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ń sọ lórílẹ̀-èdè yìí, èdè Ngobere ni wọ́n gbọ́ jù.
Wọ́n Ń Wakọ̀ Òbèlè Lọ Sọ́dọ̀ Àwọn Èèyàn Láti Gbin Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí Wọn Lọ́kàn
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kí wọ́n ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lóye òtítọ́. Síbẹ̀, wọ́n mọ̀ pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kí ohun tí wọ́n ń kọ́ wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Èyí á jẹ́ kí wọ́n ṣe àwọn àyípadà tó yẹ nígbèésí ayé wọn kí wọ́n lè máa pa àwọn ìlànà Bíbélì mọ́. Látàrí èyí, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe mẹ́jọ tí ètò Ọlọ́run yàn sí àgbègbè mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú igbó tí ìjọba yà sọ́tọ̀ náà ti kọ́ èdè Ngobere pẹ̀lú ìrànwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ tí wọ́n gbọ́ èdè náà dáadáa.
Ẹ̀rí fi hàn pé ìtẹ̀síwájú ṣì máa wà gan-an nítorí pé ìjọ mẹ́rìnlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti dá sílẹ̀ níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn, ètò Ọlọ́run rán tọkọtaya aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan tí wọ́n ń jẹ́ Dimas àti Gisela sí ìjọ kékeré kan tó ní ogójì akéde, ní àgbègbè Tobobe tó wà létíkun. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ débẹ̀, kò rọrùn fún wọn láti máa wakọ̀ ojú omi nígbà gbogbo lọ wàásù fáwọn èèyàn onírẹ̀lẹ̀ tó ń gbé ní Etíkun Àtìláńtíìkì. Tọkọtaya yìí rí i pé omi tó pa rọ́rọ́ nísinsìnyí lè bẹ̀rẹ̀ sí í ru gùdù ká tó pajú pẹ́. Ńṣe ni ọwọ́ àti ẹ̀yìn sì máa ń ro wọ́n bí wọ́n ṣe ń wakọ̀ láti abúlé kan dé abúlé míì. Ohun mìíràn tó tún dà bí òkè ìṣòro ni bí wọ́n á ṣe kọ́ èdè ìbílẹ̀. Àmọ́ o, gbogbo ìsapá àti ìforítì wọn ò já sásán. Lọ́dún 2001, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé méjìléláàádọ́ta [552] èèyàn ló wá síbi Ìrántí Ikú Kristi.
Òdìkejì etíkun Tobobe ni abúlé Punta Escondida wà. Láwọn àkókò kan, àwọn akéde bíi mélòó kan máa ń wakọ̀ láti abúlé náà wá sí òdìkejì odò láti wá ṣèpàdé ní Tobobe, ìyẹn bí ojú ọjọ́ bá jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn. Ìròyìn sì fi hàn pé bí àkókò ṣe ń lọ ìjọ tuntun ṣì máa wà ní àgbègbè náà. Ohun tó fà á nìyí tí wọ́n fi ní kí Dimas àti Gisela tún lọ máa sìn ní abúlé Punta Escondida. Kò pé ọdún méjì rárá tí ìjọ kan fi wà ní abúlé náà, akéde méjìdínlọ́gbọ̀n ló sì wà níbẹ̀. Àwọn bí àádọ́fà ó lé mẹ́rin [114] ló máa ń wá síbi àsọyé fún gbogbo èèyàn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Lọ́dún 2004, inú àwọn tó wà ní ìjọ tuntun náà dùn gan-an láti mọ̀ pé lápapọ̀, irínwó ó lé méjìdínlọ́gọ́ta [458] èèyàn ló wá sí Ìrántí Ikú Kristi.
Bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Ṣe Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Láti Dẹni Tó Mọ̀ọ́kọ-Mọ̀ọ́kà
Bí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ran ọ̀pọ̀ àwọn tó fẹ́ fi tọkàntọkàn sin Jèhófà lọ́wọ́ láti mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà ti jẹ́ kí wọ́n sún mọ́ Ọlọ́run. Bí ọ̀rọ̀ obìnrin kan tí kò tíì dàgbà púpọ̀ tó ń jẹ́ Fermina ṣe rí nìyẹn. Ibì kan tó jẹ́ àgbègbè olókè ló ń gbé nínú igbó tí ìjọba yà sọ́tọ̀ náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ míṣọ́nnárì tí wọ́n ń wàásù ní àgbègbè àdádó tó ń gbé kíyè sí i pé ó máa ń tẹ́tí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Bíbélì. Nígbà tí wọ́n bi í bóyá ó fẹ́ kí wọ́n máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ní bẹ́ẹ̀ ni. Àmọ́, ó ní ìṣòro kan o. Ó gbọ́ èdè Sípéènì àti Ngobere, àmọ́ kò sí èyí tó lè kà nínú èdè méjèèjì, bẹ́ẹ̀ ni kò lè fi wọ́n kọ̀wé. Ọ̀kan lára àwọn míṣọ́nnárì náà wá sọ pé òun yóò kọ́ ọ, ìwé pẹlẹbẹ Apply Yourself to Reading and Writinga ló sì lò.
Akẹ́kọ̀ọ́ tó ń fojú sí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni Fermina. Gbogbo ẹ̀kọ́ rẹ̀ ló máa ń múra sílẹ̀, ó máa ń ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n ní kó ṣe sílẹ̀, ó sì máa ń pe ọ̀rọ̀ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Láàárín ọdún kan, ó ti tẹ̀ síwájú débi pé ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ ìwé pẹlẹbẹ Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!b Ó tún bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé nígbà tí wọ́n ṣètò rẹ̀. Àmọ́ torí pé àtijẹ-àtimu nira nínú ìdílé Fermina, kò rọrùn fún un rárá láti máa sanwó ọkọ̀ òun àtàwọn ọmọ rẹ̀ lọ sípàdé. Ọ̀kan lára àwọn aṣáájú-ọ̀nà náà tó mọ bí Fermina ṣe wà dámọ̀ràn pé kó wò ó bóyá yóò lè máa ṣe aṣọ ìbílẹ̀ táwọn obìnrin Ngobe máa ń wọ̀, kó sì máa tà á. Bí Fermina ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan míì ṣì wà tó ní láti náwó lé lórí, ó rí i dájú pé orí lílọ sí ìpàdé ìjọ nìkan ni òun ń ná owó tó ń rí lé. Òun àti ìdílé rẹ̀ ti kó lọ sí àgbègbè mìíràn báyìí, ó sì ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Inú wọn dùn pé kì í ṣe ìṣòro àìmọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà nìkan làwọn borí, àmọ́ ní pàtàkì jù, àwọn ti wá mọ Jèhófà.
Bí Wọ́n Ṣe Borí Ìṣòro Wíwàásù Fáwọn Adití
Nílẹ̀ Panama, ojú máa ń ti ọ̀pọ̀ ìdílé tí wọ́n bá lẹ́ni tó jẹ́ adití. Nígbà míì, wọn kì í rán àwọn adití nílé ìwé rárá. Ọ̀pọ̀ àwọn adití máa ń wò ó pé wọ́n ya àwọn sọ́tọ̀, wọ́n sì pa àwọn tì, torí pé ó ṣòro láti bá wọn sọ̀rọ̀.
Èyí wá jẹ́ kó hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí ní láti wá nǹkan ṣe kí wọ́n lè wàásù fáwọn adití. Ọ̀rọ̀ ìṣírí tí alábòójútó arìnrìn-àjò kan sọ ló mú kí àwọn aṣáájú-ọ̀nà onítara kan àtàwọn míì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Èdè Adití Lọ́nà Ti Panama. Ìsapá wọn ò sì já sásán.
Nígbà tó fi máa di ìparí ọdún 2001, wọ́n ti dá àwùjọ kan tó ń sọ èdè àwọn adití sílẹ̀ ní ìlú Panama City. Nǹkan bí ogún èèyàn ló sì ń wá sípàdé. Bí èdè náà ṣe ń yọ̀ mọ́ àwọn ará tó ń kọ́ èdè náà lẹ́nu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi èdè náà wàásù fún àwọn adití tó jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa gbọ́ ìhìn rere nìyẹn. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí táwọn ọmọ wọn ò lè gbọ́rọ̀ dáadáa bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé, wọ́n sì rí i pé ó túbọ̀ rọrùn fún àwọn ọmọ wọn láti lóye ẹ̀kọ́ Bíbélì, bẹ́ẹ̀ ni ìtara tí wọ́n ní fún òtítọ́ túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Àwọn òbí sábà máa ń kọ́ bí wọ́n ṣe lè lo èdè yìí, èyí sì ti jẹ́ kí wọ́n lè túbọ̀ bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀. Ó ti wá ṣeé ṣe báyìí fún àwọn òbí láti túbọ̀ fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ kọ́ àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì ti rí i pé nǹkan ti dára sí i nínú ìdílé àwọn. Ìrírí Elsa àti Iraida ọmọbìnrin rẹ̀ fi èyí hàn kedere.
Nígbà tí Ẹlẹ́rìí kan tó ń lọ sípàdé àwọn tó ń sọ èdè adití gbọ́ nípa Iraida, ó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì fún un ní ìwé pẹlẹbẹ Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!c Inú Iraida dùn gan-an sí àwọn ẹ̀kọ́ táwọn àwòrán tó rí nípa ayé tuntun kọ́ ọ. Àwọn Ẹlẹ́rìí wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìwé pẹlẹbẹ náà kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí wọ́n parí ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé náà, wọ́n lo ìwé Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?d Ibi tí ọ̀rọ̀ dé nìyí tí Iraida fi bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ìyá rẹ̀ pé kó máa ran òun lọ́wọ́ láti múra ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀, kó sì máa ṣàlàyé fún òun.
Àmọ́ o, Elsa ìyá rẹ̀ ní ìṣòro méjì: Kò mọ ẹ̀kọ́ òtítọ́ inú Bíbélì torí pé kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, kò sì mọ èdè àwọn adití. Àwọn èèyàn ti sọ fún un pé kò gbọ́dọ̀ fi èdè àwọn adití bá ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀, pé kí ọmọ rẹ̀ lọ kọ́ bí yóò ṣe máa sọ̀rọ̀. Bó ṣe di pé òun àtọmọ rẹ̀ kì í fi bẹ́ẹ̀ bára wọn sọ̀rọ̀ nìyẹn. Ẹ̀bẹ̀ tí Iraida ń bẹ ìyá rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ ló mú kí ìyá rẹ̀ sọ fún Ẹlẹ́rìí kan nínú ìjọ pé kó máa kọ́ ọmọ òun lẹ́kọ̀ọ́. Ìyá rẹ̀ sọ pé: “Tìtorí ọmọ mi ni mo ṣe bẹ̀ wọ́n, nítorí mi ò tíì rí ohun tó mú inú Iraida dùn bẹ́ẹ̀ yẹn rí.” Elsa náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í jókòó ti ọmọ rẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́, ó sì ń kọ́ èdè àwọn adití. Bí Elsa ṣe túbọ̀ ń lo àkókò púpọ̀ sí i pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn sọ̀rọ̀ dáadáa. Iraida bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sára nípa àwọn tó ń bá rìn, àwọn ará ìjọ ló sì ń bá kẹ́gbẹ́. Ní báyìí, ìyá àti ọmọ ti ń lọ sípàdé déédéé. Àìpẹ́ yìí ni Elsa ṣèrìbọmi, Iraida náà sì ti ń tẹ̀ síwájú kóun náà lè ṣèrìbọmi. Elsa sọ pé òun ṣẹ̀sẹ̀ ń lóye ọmọ òun dáadáa ni báyìí, àwọn sì ti lè sọ̀rọ̀ báyìí nípa ọ̀pọ̀ nǹkan pàtàkì tó jẹ àwọn méjèèjì lógún.
Àwùjọ tó ń sọ èdè àwọn adití yẹn di ìjọ ní April 2003, ó sì ti ń gbèrú báyìí. Àádọ́ta akéde ló wà níbẹ̀, àwọn tó sì jùyẹn lọ ló ń wá sípàdé. Ó lé ní ìdámẹ́ta wọn tó jẹ́ adití. Àwọn Ẹlẹ́rìí tún ń ṣètò láti dá àwọn àwùjọ tó ń sọ èdè àwọn adití sílẹ̀ láwọn ìlú mẹ́ta tí kò tóbi tó Panama City. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ló ṣì wà láti ṣe fún àǹfààní àwọn tó ń sọ èdè àwọn adití, kò sí àní-àní pé àwọn Ẹlẹ́rìí ti sapá gan-an ni láti rí i dájú pé àwọn adití tí wọ́n fẹ́ sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ń gbọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá wọn onífẹ̀ẹ́.
Káàkiri orílẹ̀-èdè Panama ni irú àwọn nǹkan tó ń múnú ẹni dùn bẹ́ẹ̀ ti ń ṣẹlẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn èèyàn ń sọ ní Panama, táwọn olówó àtàwọn tálákà wà níbẹ̀, tí àṣà ìbílẹ̀ wọn sì yàtọ̀ síra, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ lára wọn ti wà níṣọ̀kan nínú ìjọsìn Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo náà. Ó ti ṣeé ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló mú kó ṣòro láti wàásù fún àwọn èèyàn lórílẹ̀-èdè tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé “ó dà bí afárá tó so ayé pọ̀” yìí.—Éfésù 4:4.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí.
b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí.
c Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí.
d Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí.
[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 8]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÒKUN CARIBBEAN
PANAMA
Tobobe
ÒKUN PÀSÍFÍÌKÌ
Ipadò Panama
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà Kuna mú aṣọ aláràbarà dání
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Arábìnrin kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì ń wàásù fún obìnrin kan tó jẹ́ ẹ̀yà Ngobe
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n wá láti Ngobe fẹ́ wọ ọkọ̀ òbèlè lọ sí àpéjọ àkànṣe
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Àwọn Ẹlẹ́rìí ń fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì kọ́ àwọn ará Panama bó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè wọn àti àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Wọ́n ń fi èdè àwọn adití ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ “Ilé Ìṣọ́”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Elsa àti Iraida ọmọ rẹ̀ ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ tọmọ-tìyá
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]
Ọkọ̀ òkun àtàwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà Kuna: © William Floyd Holdman/Index Stock Imagery; abúlé: © Timothy O’Keefe/Index Stock Imagery