ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 8/1 ojú ìwé 4-8
  • Ijumọsọrọpọ—Ju Kìkì Ọ̀rọ̀ Sísọ Lasan Lọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ijumọsọrọpọ—Ju Kìkì Ọ̀rọ̀ Sísọ Lasan Lọ
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fifi Ìjìnlẹ̀-Òye Hàn
  • Liloye Ìgbà ti Ó Ti Kọja
  • Nigba Ti Ìgbà ti Ó Ti Kọja Ba Jẹ́ ti Iloninilokulo
  • A fi Ifibinuhan Dẹkùn Mú Wọn
  • Ikẹrabajẹ Ń Ṣepalara fun Ijumọsọrọpọ
  • Yiyanju Awọn Iṣoro
  • Ó Ju Kìkì Wíwà fun Akoko Gigun Lọ
  • Àwọn Ohun Tó Lè Mú Kí Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Máa Lọ Déédéé Láàárín Tọkọtaya
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ó Ṣeé Ṣe Kí Ìgbéyàwó Yín Má Forí Ṣánpọ́n O!
    Jí!—2001
  • Máa Bọ̀wọ̀ fún Ọkọ Tàbí Aya Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ẹ máa bá ara yín sọ̀rọ̀ kẹ́ ẹ lè túbọ̀ ṣera yín lọ́kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 8/1 ojú ìwé 4-8

Ijumọsọrọpọ—Ju Kìkì Ọ̀rọ̀ Sísọ Lasan Lọ

FINUWOYE ogunlọgọ awọn arinrin-ajo ti wọn ń wo iran ilẹ kan ti a gbin koriko si daradara. Bi o tilẹ jẹ pe gbogbo awọn eniyan naa ń wo iran kan-naa, ẹnikọọkan ń rí i ní ọ̀nà ti o yatọsira. Eeṣe? Nitori pe olukuluku duro si ibi ti o yatọsira. Kò si ẹni meji ti ó duro si ipo kan-naa ni pato. Siwaju sii, kìí ṣe gbogbo eniyan ni wọn ń wo apa ibi kan-naa ninu iran naa. Olukuluku rí apá kan ti o yatọ gẹgẹ bi eyi ti ń ru ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ soke ni pataki.

Ohun kan-naa ni o jẹ́ otitọ ninu igbeyawo. Ani nigba ti wọn bá bá araawọn mu gan-an, kò si awọn tọkọtaya meji ti wọn ni oju-iwoye kan-naa lori awọn ọ̀ràn. Ọkọ ati aya yatọ ninu iru awọn ipo-ọran bi iru imọlara ti ẹnikan ní, awọn iriri ìgbà ọmọde, ati agbara idari idile. Awọn oju-iwoye ti kò jọra ti o jẹ́ iyọrisi rẹ̀ lè di orisun ija kikoro. Aposteli Paulu sọ pẹlu otitọ-inu pe: “Awọn ti wọn ṣegbeyawo yoo ní irora ati ẹdun-ọkan.”—1 Korinti 7:28, The New English Bible.

Ijumọsọrọpọ ní ninu isapa naa lati mu awọn iyatọ wọnyi wọ inu ibatan ẹlẹ́ran-ara-kan. Eyi ń beere fun fifi akoko silẹ lati sọrọ. (Wo apoti ni oju-iwe 7.) Ṣugbọn pupọ sii ni ó ní ninu.

Fifi Ìjìnlẹ̀-Òye Hàn

Owe Bibeli kan sọ pe: “Àyà ọlọgbọn mu [ki ẹnu rẹ̀ fi ìjìnlẹ̀-òye hàn, NW], o sì mu ẹkọ pọ̀ ni ètè rẹ̀.” (Owe 16:23) Ọ̀rọ̀ Heberu naa ti a tumọ si ‘mu ki o fi ìjìnlẹ-òye hàn’ nihin-in ni ipilẹ tumọsi lati jẹ́ olóye, lati fi tiṣọratiṣọra gbe ọ̀rọ̀ yẹwo ninu ero-inu. Nitori naa, apá ibi ti ijumọsọrọpọ ti o gbeṣẹ dá lé lori ni ọkan-aya, kìí ṣe ẹnu. Olubanisọrọpọ daradara kan gbọdọ ṣe ju jíjẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kan lọ; ó gbọdọ jẹ olutẹtisilẹ kan ti ń gbatẹniro. (Jakọbu 1:19) Ó gbọdọ foyemọ awọn imọlara ati awọn ọ̀ràn ti o wà nidii ihuwa ẹnikeji kan lorefee.—Owe 20:5.

Bawo? Nigba miiran eyi ni a lè ṣaṣeyọri rẹ̀ nipa ṣiṣakiyesi awọn ipo-ọran ti o yi rogbodiyan kan ká. Ẹnikeji rẹ ha wa labẹ ikimọlẹ ero-imọlara tabi ti ara lilekoko bi? Aisan kan ha ń pakun iṣọwọhuwa ẹnikeji rẹ bi? “Ẹ wo bi o ti jẹ ohun ayọ tó lati rí ọ̀rọ̀ yiyẹ fun akoko ti o tọ́!” ni Bibeli sọ. (Owe 15:23, Today’s English Version) Nitori naa gbigbe awọn ipo-ọran naa yẹwo yoo ran ọ lọwọ lati dahunpada lọna ti o tọ́.—Owe 25:11.

Bi o tilẹ ri bẹẹ, ohun ti o saba maa ń ṣokunfa rogbodiyan ní gbongbo rẹ̀ ninu awọn ọ̀ràn ti kò si lara ipo-ọran ti lọọlọọ.

Liloye Ìgbà ti Ó Ti Kọja

Awọn iriri nigba ọmọde ṣe pupọ lati fi ironu wa soju ila títọ́ nigba agbalagba. Niwọn bi o ti jẹ́ pe awọn alabaaṣegbeyawo wá lati inu awọn idile ti o yatọ, awọn oju-iwoye ti ń faragbunra kò ṣee yẹ̀ silẹ.

Iṣẹlẹ kan ti a kọ silẹ ninu Bibeli ṣapejuwe eyi. Nigba ti a dá apoti ẹ̀rí pada si Jerusalemu, Dafidi fi itara rẹ̀ hàn ni gbangba. Ṣugbọn iyawo rẹ̀, Mikali ńkọ́? Bibeli sọ fun wa pe: “Mikali ọmọbinrin Saulu sì wò lati oju ferese, ó sì ri Dafidi ọba ń fò soke ó sì ń jó niwaju Oluwa; oun sì kẹ́gàn rẹ̀ ni ọkàn rẹ̀.”—2 Samueli 6:14-16.

Mikali gbé iwa alainigbagbọ ti baba rẹ̀, Saulu, yọ. Awọn alálàyé Bibeli naa C. F. Keil ati F. Delitzsch dabaa pe idi niyii ti a fi tọka si Mikali ni ẹsẹ 16 gẹgẹ bi “ọmọbinrin Saulu” dipo gẹgẹ bi aya Dafidi. Lọnakọna ṣa, aáwọ̀ ti o tẹlee laaarin wọn mu ki o ṣe kedere pe Dafidi ati Mikali kò ṣajọpin oju-iwoye kan-naa nipa iṣẹlẹ alayọ yii.—2 Samueli 6:20-23.

Apẹẹrẹ yii ṣaṣefihan pe awọn agbara ìdarí ọlọ́gbọ́n àyínìke nipa ọ̀nà ti a gbà tọnidagba lè fa ki ọkọ ati aya wo awọn ọ̀ràn ni ọ̀nà ti o yatọ sira gan-an. Eyi jẹ́ otitọ ani bi awọn mejeeji bá tilẹ ń ṣiṣẹsin Jehofa ni iṣọkan. Fun apẹẹrẹ, aya kan ti a kò fun ni itilẹhin ero-imọlara ti o pọ̀ tó gẹgẹ bi ọmọ kan lè fi aini ara-ọtọ fun itẹwọgba ati ifilọkanbalẹ hàn. Eyi lè dààmú ọkọ rẹ̀. “Mo lè sọ fun un ni ọgọrun-un ìgbà pe mo nifẹẹ rẹ̀,” ni oun lè fìkanra sọ, “sibẹsibẹ ki yoo tó!”

Ninu iru ọ̀ràn yii, ijumọsọrọpọ ní ninu “ki olukuluku yin ki o maṣe wo ohun tirẹ̀, ṣugbọn olukuluku ohun ti ẹlomiran.” (Filippi 2:4) Lati jumọsọrọpọ, ọkọ kan gbọdọ fi oju awọn iriri aya rẹ̀ ni ìgbà ti o ti kọja wò ó dipo ki o fi oju ti araarẹ̀ wò ó. Dajudaju, aya kan ni a sì gbọdọ sún lati ṣe ohun kan-naa fun ọkọ rẹ̀.—1 Korinti 10:24.

Nigba Ti Ìgbà ti Ó Ti Kọja Ba Jẹ́ ti Iloninilokulo

Níní ọkàn-ìfẹ́ ninu rẹ̀ gẹgẹ bi ẹnikan pọndandan ni pataki bi a bá ti fipa bá ẹnikeji naa lòpọ̀ rí tabi ki a ti lò ó ni ilokulo niti ibalopọ takọtabo gẹgẹ bi ọmọde kan—lọna ti o banininujẹ, iṣoro kan ti ń ga soke ni eyi jẹ́ lonii. Aya kan, fun apẹẹrẹ, lè rí i pe ni awọn akoko isunmọra ti ibalopọ takọtabo, oun kò lè fi iyatọ saaarin akoko lọwọlọwọ ati eyi ti o ti kọja, laaarin ẹnikeji rẹ̀ ati ẹni ti o huwa ẹṣẹ naa, tabi laaarin ibalopọ takọtabo ati iloninilokulo niti ibalopọ-takọtabo. Eyi lè mu ki nǹkan súni, paapaa bi ọkọ naa kò bá gbé ọ̀ràn ẹlẹgẹ yii yẹwo lati iha ọ̀dọ̀ ti aya rẹ̀.—1 Peteru 3:8.

Nigba ti o kò lè mú ki ohun ti o ti kọja pada ti o kò sì lè wo awọn ipa iyọrisi rẹ̀ sàn patapata, iwọ lè ṣe pupọ lati tu ẹnikeji kan ti a kó irẹwẹsi bá ninu. (Owe 20:5) Bawo? “Ẹyin ọkọ nilati gbiyanju lati loye awọn aya ti ẹ ń bá gbé,” ni Peteru kọwe. (1 Peteru 3:7, Phillips) Liloye ìgbà ti o ti kọja ti alabaaṣegbeyawo rẹ jẹ́ apá ṣiṣepataki kan ninu ijumọsọrọpọ. Laisi ibanikẹdun agbatẹniro, awọn ọ̀rọ̀ rẹ yoo jẹ eyi ti kò nilaari.

‘Aanu ṣe’ Jesu nigba ti o pade awọn ti ń ṣòjòjò, bi o tilẹ jẹ pe oun funraarẹ kò ni iriri awọn àrùn wọn ri. (Matteu 14:14) Bakan-naa, iwọ funraarẹ lè ma tii ni iriri iru iṣati tabi iloninilokulo kan-naa bii ti aya rẹ rí, ṣugbọn dipo kíkóyán irora rẹ̀ kéré, fẹ̀rí imọdaju nipa ìgbà rẹ̀ ti o ti kọja hàn, ki o si fun un ni itilẹhin rẹ. (Owe 18:13) Paulu kọwe pe: “Ǹjẹ́ ó yẹ ki awa ti o lera iba maa ru ẹrù ailera awọn alailera, ki a má sì ṣe ohun ti o wu ara wa.”—Romu 15:1.

A fi Ifibinuhan Dẹkùn Mú Wọn

Igbeyawo kan dabi ohun-eelo alaiṣeediyele. Nigba ti a bá fi panṣaga bà á jẹ́, ipalara ti kò ṣeediwọn a maa ṣẹlẹ. (Owe 6:32) Lotiitọ, bi ẹnikeji alaimọwọmẹsẹ naa bá pinnu lati dariji, àfọ́kù naa ni a lè lẹ̀ papọ nipasẹ ìlàjà. Ṣugbọn ojú ibi ti ó sán naa ṣì wà nibẹ, bi ọ̀ràn ijiyan bá sì ṣẹlẹ, itẹsi lè wà lati wo ojú ibi ti ó sán wọnyẹn ki a sì lo akoko ti o ti kọja gẹgẹ bi ohun ija kan.

Ifibinuhan jẹ́ idahunpada ti o wadeedee si aiṣododo ẹnikeji ninu igbeyawo. Ṣugbọn ti o ba ti dariji ẹnikeji rẹ, ṣọra fun jíjẹ́ ki ìkannú ti kò tán nilẹ bọ̀rọ̀ ba rere ti o ti rígbà nipasẹ iṣe idariji jẹ́. Yala ifibinuhan naa ń sọ wúkẹ́wúkẹ́ ninu lọ́hùn-ún tabi ó ru jade lailaaanu ni, ifibinuhan ti ń lọ lọwọ a maa ṣepalara fun tọkọtaya. Eeṣe? Dokita kan damọran pe: “Bi ẹnikeji rẹ bá ń mu inu bi ọ, ó jẹ́ nitori pe iwọ ṣì bikita nipa rẹ̀. Nitori naa nipa fifasẹhin tabi nipa wíwá igbẹsan, kìí ṣe pe o ń ṣepalara fun ẹnikeji rẹ nikan ni ṣugbọn o ń pa araarẹ rẹ run. O ń baa lọ ní títú ibatan ti o daniyan pe ki o jẹ́ odindi palẹ̀.”

Bẹẹni, o kò lè làjà awọn aáwọ̀ ninu igbeyawo rẹ lai pa ibinu rẹ lẹnu mọ. Nitori naa, ni akoko kan nigba ti awọn ero-imọlara kò bá gbona, jiroro awọn imọlara rẹ pẹlu ẹnikeji rẹ. Ṣalaye idi rẹ̀ ti inu fi bí ọ, ohun ti o nilo lati nimọlara ifilọkanbalẹ, ati ohun ti iwọ yoo ṣe lati pa ipo-ibatan naa mọ́. Maṣe lo ohun ti o ti kọja kiki gẹgẹ bi ohun ija kan lati jere ipo ti o lagbara ninu iyàn jíjà kan.

Ikẹrabajẹ Ń Ṣepalara fun Ijumọsọrọpọ

Igbeyawo kan ń koju pakanleke lilekoko nigba ti ẹnikeji kan bá ń lo ọtí tabi òògùn ni ilokulo. Ẹnikeji ti kò kẹrabajẹ naa lè wà ninu ipo kan ti o jọra pẹlu ti Abigaili, gẹgẹ bi a ti rohin rẹ̀ ninu Bibeli. Nigba ti ọkọ rẹ̀ Nabali “ti mu ọti ni amupara,” Abigaili ń fi tagbaratagbara gbiyanju lati yi awọn iyọrisi ihuwa alaibọgbọnmu rẹ̀ pada. (1 Samueli 25:18-31, 36) Awọn igbeyawo ninu eyi ti ọ̀kan ninu awọn alajọṣegbeyawo ti fi ikẹrabajẹ rẹ̀ dá idarudapọ silẹ ti enikeji si ń gbiyanju lati yi iwa ẹni ti o ti kẹrarẹbajẹ naa pada saba ti maa ń jọra pẹlu ti agbo-ile Nabali ati Abigaili.a

A mọ̀ pe, imọlara itura ńláǹlà a maa wà nigba ti ẹnikan ti o ti kẹrarẹbajẹ bá bẹrẹ sii ni imularada. Ṣugbọn ibẹrẹ kan lasan ni eyi wulẹ jẹ́. Finuwoye iji-lile nla kan ti ń ṣọṣẹ́ ni ilu kekere kan. Awọn ile ń wó lulẹ, awọn igi ni a ń fà tu, awọn okùn tẹlifoonu ń já lulẹ. Ayọ nla yoo wà nigba ti ìjì naa bá kọja. Ṣugbọn nisinsinyi a nilo atunṣe kan ti o nasẹ jinna. Ohun kan-naa ni o jẹ́ otitọ nigba ti ẹnikeji kan bá bẹrẹ sii ni imularada. Awọn ibatan ti o ti wolulẹ ni a gbọdọ túnkọ́. Igbẹkẹle ati iwatitọ ni a gbọdọ tun gbekalẹ. A nilati ṣatunkọ awọn ìlà ijumọsọrọpọ. Fun akẹrabajẹ kan, iṣatunkọ ni kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ yii jẹ apakan “akopọ animọ-iwa titun” ti Bibeli beere lọwọ awọn Kristian lati gbé wọ̀. Akopọ animọ-iwa titun yii gbọdọ ni “ipá ti ń sún ero-inu yin ṣiṣẹ” ninu.—Efesu 4:22-24, NW.

Ikẹkọọ Bibeli kan mú ki o ṣeeṣe fun Leonard ati Elaine lati dawọ lílo oògùn ni ilokulo duro, ṣugbọn ipá ti ń sún ero-inu ṣiṣẹ naa kò tíì wá sẹnu iṣẹ ni kikun.b Laipẹ laijinna awọn ikẹrabajẹ miiran yọju. “Fun 20 ọdun a gbiyanju lati fi awọn ilana Bibeli silo ki a sì ni igbeyawo ti ń tẹnilọrun, ṣugbọn otubantẹ naa ni,” ni Elaine sọ. “Ikẹrabajẹ wa ti ta gbongbo jinlẹ. Kò ṣeeṣe fun wa lati fi ikẹkọọ tabi adura mú un kuro.”

Leonard ati Elaine wá imọran lati lóye okunfa ikẹrabajẹ wọn. Akojọpọ-ọrọ ti o bọ sí kòńgẹ́ lati ọwọ “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu” lori lilo ọmọde ni ilokulo, ìmukúmu-ọtí, ati ọ̀wọ̀ fun awọn obinrin ti jẹ́ aranṣe pataki.c (Matteu 24:45-47, NW) “A ti ràn wá lọwọ lati ṣatunṣe ibajẹ naa ti a sì mú ipo-ibatan wa padabọsipo,” ni Elaine sọ.

Yiyanju Awọn Iṣoro

Rebeka nimọlara irora ti kò ṣee faragbà nipa aya ọmọkunrin rẹ̀ Esau. Ní bibẹru pe ọmọ rẹ̀ keji, Jakọbu, yoo tẹle apẹẹrẹ Esau, Rebeka sọ imujakulẹ rẹ̀ jade nipa sisọ fun ọkọ rẹ̀ Isaaki pe: “Agara ayé mi ma dá mi nitori awọn ọmọbinrin Heti, bi Jakọbu bá fẹ́ aya ninu awọn ọmọbinrin Heti, bi iru awọn wọnyi tí í ṣe ninu awọn ọmọbinrin ilẹ yii, ayé mi o ha ti ri?”—Genesisi 27:46.

Ṣakiyesi pe nigba ti o jẹ pe Rebeka sọrọ pẹlu idaniloju nipa awọn imọlara rẹ̀, oun kò gbejako Isaaki funraarẹ. Oun kò wi pe, “Ẹ̀bi rẹ ni gbogbo rẹ̀!” tabi, “Iwọ kì bá ti ṣekawọ ipo yii lọna ti o tubọ dara ju!” Kaka bẹẹ, Rebeka lo arọpo ọ̀rọ̀ orukọ naa “emi” lati ṣapejuwe bi iṣoro naa ṣe nipa lori rẹ̀. Ọ̀nà ti o gbà sọ ọ́ yii mú ki Isaaki fi igbatẹniro dahunpada, kìí ṣe ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ lati wá ojurere. Bi kò ti nimọlara igbejakoni, ó hàn gbangba pe idahunpada Isaaki si ẹ̀bẹ̀ Rebeka jẹ́ loju ẹsẹ.—Genesisi 28:1, 2.

Awọn ọkọ ati aya lè kẹkọọ lati inu apẹẹrẹ Rebeka. Nigba ti aáwọ̀ bá ṣẹlẹ, ẹ gbejako iṣoro naa dipo ẹnikinni keji yin. Gẹgẹ bii Rebeka, sọ ijakulẹ rẹ jade pẹlu oju-iwoye naa nipa bi eyi ṣe ni ipa lori rẹ. “Mo ni ijakulẹ nitori pe . . .” tabi, “Mo nimọlara pe o ṣì mi lóye nitori pe . . .” gbeṣẹ gidigidi ju “Iwọ kó ijakulẹ bá mi!” tabi, “Iwọ kò loye mi ri lae!”

Ó Ju Kìkì Wíwà fun Akoko Gigun Lọ

Igbeyawo tọkọtaya akọkọ naa, Adamu ati Efa, ń baa lọ fun ọpọ ọrundun, ni mimu idile ti o ní ọmọkunrin ati ọmọbinrin jade. (Genesisi 5:3-5) Ṣugbọn eyi kò tumọsi pe igbeyawo wọn yẹ ni eyi ti àáfarawé. Ní ibẹrẹ, ẹmi ominira ati aibọwọ fun awọn ofin òdodo Ẹlẹdaa naa ba isopọ ara-kan wọn jẹ́.

Bakan-naa, igbeyawo kan lonii le jẹ eyi ti ń baa lọ, sibẹ ki o ṣaini awọn eroja ṣiṣepataki ti ijumọsọrọpọ. Awọn ironu ti a rinkinkin mọ́ lọna lilagbara ati awọn animọ ara-ẹni ti kò bojumu ni a lè nilati fàtu. (Fiwe 2 Korinti 10:4, 5.) Igbesẹ idanilẹkọọ ti ń lọ lọwọ ni eyi jẹ́. Ṣugbọn isapa naa yẹ fun un. Jehofa Ọlọrun lọkan-ifẹ jijinlẹ ninu eto igbeyawo, niwọn bi o ti jẹ́ pe oun ni Oludasilẹ rẹ̀. (Malaki 2:14-16; Heberu 13:4) Nitori naa, bi a bá ṣe ipa tiwa, a lè ni idaniloju pe oun yoo mọ awọn isapa wa yoo sì pese ọgbọ́n ati okun ti ó yẹ lati wo ijakulẹ eyikeyii ninu ijumọsọrọpọ ninu igbeyawo sàn.—Fiwe Orin Dafidi 25:4, 5; 119:34.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Iranlọwọ fun idile awọn onimukumu-ọti ni a jiroro ninu itẹjade Ji! May 22, 1992 (Gẹẹsi), oju-iwe 3 si 7.

b Awọn orukọ ni a ti yipada.

c Wo itẹjade Ji! ti March 8, 1992, May 22, 1992 (Gẹẹsi), ati July 8, 1992.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

“Pàǹtírí gba akoko ti o pọju!”

Ọkọ ati aya kan ti wọn ń niriiri awọn iṣoro igbeyawo ni a ní ki wọn ṣiro iye akoko ti wọn ń lò ní dída pàǹtírí nù ní ọsọọsẹ. Idahun wọn jẹ́ nǹkan bi iṣẹju 35 ní ọsẹ kan, tabi iṣẹju 5 ní ọjọ kan. Lẹhin naa, a bi wọn leere iye akoko ti wọn ń lò ninu sisọrọ papọ. Ọkọ naa ta kìjí. “Pàǹtírí gba akoko ti o pọju!” ni oun wi, ni fifikun un pe: “A ń tan araawa jẹ bi a bá ronu pe iṣẹju marun-un ní ọjọ kan jẹ́ akoko ti o tó lati bojuto igbeyawo kan. Dajudaju kìí sìí ṣe akoko ti o tó lati mu ki igbeyawo dagba.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

Gbé Awọn Ilana Ìwàhíhù Kalẹ

◻ Ẹ jiroro koko-ọrọ kan lẹẹkan (1 Korinti 14:33, 40)

◻ Ẹ sọ imọlara yin; ẹ maṣe fẹsun kanni (Genesisi 27:46)

◻ Kò si gbígbáni (Efesu 5:28, 29)

◻ Kò si fiforukọ ẹ̀gàn peni (Owe 26:20)

◻ Ẹ ni gongo pipari ìjà lọkan, kìí ṣe bibori (Genesisi 13:8, 9)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Nigba ti aáwọ̀ bá ṣẹlẹ, ẹ gbejako iṣoro naa dipo ẹnikinni keji yin

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Sọ awọn imọlara jade; maṣe fẹsun kanni

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́