Awọn Olupokiki Ijọba Rohin
Ọ̀dọ́ Onitara-Ọkan Ninu Rélùwéè Kẹkọọ Otitọ
BI ỌKAN-AYA ẹnikan bá tẹ̀ siha òdodo, nigba naa ni Jehofa Ọlọrun, ní lílo Kristi Jesu ati awọn angẹli ọ̀run, yoo rí sí i pe iru ẹni-bi-agutan bẹẹ ni a kàn lára pẹlu ihinrere Ijọba naa ni asẹhinwa-asẹhinbọ. Laipẹ-laijinna ẹni yẹn lè wá si apá ọ̀tún ojurere Jesu. (Matteu 25:31-33) Eyi jẹ́ otitọ nipa ọ̀dọ́ onitara-ọkan ninu rélùwéè ni Austria ẹni ti o di ojulumọ pẹlu otitọ ni ọ̀nà alailẹgbẹ kan.
Apá ti o ń ru ọdọmọkunrin yii soke jù ninu eré-ìpawọ́dà rẹ̀ ni lati rinrin-ajo ni jijokoo pẹlu awakọ nibi ẹnjinni ọkọ̀ rélùwéè, pẹlu iyọọda awọn alaboojuto rélùwéè. Ó gba irin-ajo kọọkan silẹ lori kamẹra fidio ki o baa lè wò ó lẹẹkan sii ni ile rẹ̀. Ninu irin-ajo kan ti o lọ lati Vienna si Salzburg, awakọ rélùwéè naa jẹ́ ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ó lo anfaani naa lati sọrọ nipa Ijọba naa fun onitara-ọkan rélùwéè naa. Lakọọkọ ó ya ọdọmọkunrin naa lẹnu lati gbọ́ ti awakọ naa ń sọrọ nipa Ọlọrun ati Bibeli, ṣugbọn lakooko irin-ajo naa, ó kó afiyesi jọ sori awọn ìran naa ju sori ohun ti awakọ̀ naa ń sọ fun un lọ.
Nigba ti o tun pada dé ile, ọ̀dọ́ onitara-ọkan yii wo ohun ti o gbà silẹ lori fidio rẹ̀ kìí ṣe lẹẹkan ṣugbọn nigba mẹwaa, niwọn bi o ti nifẹẹ si irin-ajo yii. Niwọn bi o sì ti gba ohùn rẹ̀ silẹ pẹlu, ó gbọ́ ohun ti Ẹlẹ́rìí naa ti sọ fun un leralera. Bi o ti tubọ ń wo fidio naa, bẹẹ ni o tubọ ń dojulumọ ohun ti a ti sọ fun un tó. Ó wá bẹrẹ sii ronu nipa rẹ̀ nisinsinyi, ati nikẹhin ó di onitara-ọkan nipa agbayanu isọfunni ti a gbekalẹ lati inu Bibeli. Ó fẹ́ lati tubọ mọ̀ sii.
Ó ranti orukọ awakọ naa ó sì mọ̀ pe ó ń gbé ni ibikan ni Vienna. Nitori naa ó lọ si ile-ifiweranṣẹ ó sì bẹrẹ sii tẹ nọmba tẹlifoonu kan lẹhin omiran ti a tò sabẹ orukọ yẹn ninu iwe itolẹsẹẹsẹ orukọ awọn ti o ní tẹlifoonu. Ibeere rẹ̀ fun awọn wọnni ti wọn gbé tẹlifoonu naa ni: “Awakọ rélùwéè ha ni ọ bi?” Bi idahun naa bá jẹ́ bẹẹkọ, oun yoo tẹ nọmba miiran. Nikẹhin, ó rí awakọ̀ naa. Ó sọ ìtàn rẹ̀ fun un ati pe oun nifẹẹ ninu ihin-iṣẹ Bibeli naa ti oun ti gbọ́ lori fidio naa.
Ẹlẹ́rìí naa ṣeto nipasẹ ọfiisi ẹ̀ka fun ẹnikan ti ń gbé lẹbaa ọdọmọkunrin naa lati ṣe ikesini sọdọ rẹ̀. Ó ṣẹlẹ bẹẹ pe ninu ijọ adugbo, Ẹlẹ́rìí miiran kan wà ti oun pẹlu tun jẹ́ awakọ oju-irin. Awakọ keji yii ṣebẹwo sọdọ onitara-ọkan ninu reluwee naa, ikẹkọọ Bibeli kan sì bẹrẹ. Ni ìgbà ẹ̀rùn 1991, ọdọmọkunrin naa ni a baptisi.
Jehofa, ẹni ti ń ṣayẹwo gbogbo ọkan-aya, ti gbọdọ rí i pe ẹni yii ní ifẹ olotiitọ-inu fun òdodo. Fun idi yii, ó mú un wá ṣalabaapade otitọ Bibeli—bi o tilẹ jẹ́ ni ọ̀nà alailẹgbẹ kan.—1 Kronika 28:9; Johannu 10:27.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]
Iyọnda oninuure ti ajọ Rélùwéè ti ilẹ Austria