Fídíò Tuntun Tí A Ó Máa Fi Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti wo fídíò kan tí kò gùn púpọ̀ tó ti wà lórí ìkànnì jw.org. Àkòrí fídíò náà ni “Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” A ṣe fídíò yìí lọ́nà tó máa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn kí wọ́n lè gbà pé ká máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A máa rí fídíò yìí tá a bá tẹ ibi tá a pè ní “Béèrè Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì,” èyí tó wà ní ìsàlẹ̀ ojúde ìkànnì wa. A sì tún lè fi fóònù alágbèéká wa wọlé sórí ìkànnì náà tá a bá lo àmì ìlujá tá a tẹ̀ sẹ́yìn àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú wa tuntun. Àwọn ọ̀nà mélòó kan rèé tá a lè gbà lo fídíò náà.
Tó o bá lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò, o lè sọ pé: “Ǹjẹ́ mo lè fi fídíò kan tí kò gùn púpọ̀ hàn ẹ́, ó ṣàlàyé bó o ṣe lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó o ní látinú Bíbélì?” Tó bá gbà, fi fídíò náà hàn án lórí fóònù rẹ tàbí lórí kọ̀ǹpútà tirẹ̀.
Tá a bá fún ẹnì kan ní ọ̀kan lára àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú wa tuntun nígbà tá à ń jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà tàbí nígbà tá à ń wàásù níbi térò pọ̀ sí, fi àmì ìlujá tó wà lẹ́yìn ìwé náà hàn án kó o sì ní kó lọ sórí àmì náà látorí fóònù rẹ̀ kó lè gbé e lọ sí ibi tí fídíò náà wà lórí ìkànnì wa. Ní ọ̀pọ̀ èdè, àmì ìlujá náà máa gbé èèyàn lọ sí ibi tí fídíò náà wà lórí ìkànnì wa, torí náà onítọ̀hún lè wo fídíò náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lórí fóònù rẹ̀.
Sọ nípa fídíò náà fún àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọ iléèwé rẹ, àwọn ìbátan rẹ àtàwọn míì tó o mọ̀, kó o sì fi hàn wọ́n. O sì lè fi àdírẹ́sì abala tí fídíò náà wà lórí ìkànnì wa ránṣẹ́ sí wọn lórí e-mail, kó o sì ní kí wọ́n lọ wò ó.
Tá a bá ń lo fídíò tuntun yìí, a máa lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì púpọ̀ sí i, a sì máa ran ọ̀pọ̀ àwọn ‘tí wọ́n ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun’ lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá mọ Ọlọ́run.—Ìṣe 13:48.