ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/14 ojú ìwé 3
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
km 4/14 ojú ìwé 3

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní April 28, 2014.

  1. Kí ló ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ tó fi lè sá kúrò lọ́dọ̀ ìyàwó Pọ́tífárì tó fẹ́ kó bá òun ṣèṣekúṣe? (Jẹ́n. 39:7-12) [Mar. 3, w13 2/15 ojú ìwé 4 ìpínrọ̀ 6; w07 10/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 16]

  2. Ọ̀nà wo ni Jósẹ́fù gbà jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún àwọn tí wọ́n bá hùwà ìrẹ́jẹ sí àtàwọn tí àjálù dé bá? (Jẹ́n. 41:14, 39, 40) [Mar. 10, w04 1/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 6; w04 6/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 4]

  3. Kí ló mú kí Jósẹ́fù fi ojú àánú hàn sí àwọn arákùnrin rẹ̀? [Mar. 17, w99 1/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 6 sí 7]

  4. Báwo ni ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 49:27 ṣẹ? [Mar. 24, w12 1/1 àpótí tó wà lójú ìwé 29]

  5. Kí ni Ẹ́kísódù 3:7-10 kọ́ wa nípa Jèhófà? [Mar. 31, w09 3/1 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 3 sí 6]

  6. Nígbà ayé Mósè, báwo ni Jèhófà ṣe mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ? (Ẹ́kís. 3:14, 15) [Mar. 31, w13 3/15 ojú ìwé 25 sí 26 ìpínrọ̀ 5 àti 6]

  7. Bí Ẹ́kísódù 7:1 ṣe sọ, báwo ni Ọlọ́run ṣe fi Mósè ṣe “Ọlọ́run fún Fáráò”? [Apr. 7, w04 3/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 7]

  8. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti rí bí Jèhófà ṣe fi agbára rẹ̀ gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì, kí ni wọ́n ṣe nígbà tó yá, ẹ̀kọ́ wo lèyí sì kọ́ wa? (Ẹ́kís. 14:30, 31) [Apr. 14, w12 3/15 ojú ìwé 26 sí 27 ìpínrọ̀ 8 sí 10]

  9. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé gbólóhùn náà “gbé yín lórí ìyẹ́ apá àwọn idì” jẹ́ ká mọ pé ń ṣe ni Jèhófà fìfẹ́ bójú tó orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀? (Ẹ́kís. 19:4) [Apr. 28, w96 6/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 2]

  10. Ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà mú “ìyà ìṣìnà àwọn baba wá” sórí àtìrandíran wọn? (Ẹ́kís. 20:5) [Apr. 28, w04 3/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́