Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 5
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 5
Orin 33 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 6 ìpínrọ̀ 16 sí 21 àti àpótí tó wà lójú ìwé 65 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 23-26 (10 min.)
No. 1: Ẹ́kísódù 25:1-22 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Jèhófà Nìkan La Gbọ́dọ̀ Máa Jọ́sìn—td 9D (5 min.)
No. 3: Kí Ni Ó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ—lr orí 16 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Fi Àwọn Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù May. Ìjíròrò. Kọ́kọ́ fi àwọn abá méjì tó wà lójú ìwé yìí ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni. Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò àwọn àbá náà láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin. Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, fún àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n ka àwọn ìwé ìròyìn náà dáadáa, kí wọ́n sì fìtara kópa nínú fífi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí? Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní nígbà tí wọ́n lo àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Ṣèrànwọ́ fún Ẹni Tẹ́ Ẹ Jọ Ṣiṣẹ́ Lóde Ẹ̀rí.” Ní kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní.
Orin 103 àti Àdúrà