A Ṣètò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Láti Wàásù Ìhìn Rere
Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí tá a ti ṣètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti máa wàásù ìhìn rere. À ń lo ọgọ́rọ̀ọ̀rún-ún èdè láti wàásù ìhìn rere náà, a sì ń wàásù ní ilẹ̀ tó lé ní ọ̀gọ́rùn-ún méjì ó lé ọgbọ̀n [230], èyí sì ni iṣẹ́ ìwàásù tó tíì gbòòrò jù lọ lórí ilẹ̀ ayé. (Mát. 24:14) Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe iṣẹ́ yìí? Báwo la ṣe ń ṣe é jákèjádò ayé? Fídíò náà, A Ṣètò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Láti Wàásù Ìhìn Rere, ìyẹn Jehovah’s Witnesses—Organized to Share the Good News, dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, ó sì tún ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa onírúurú ọ̀nà tá à ń gbà ṣe iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Lẹ́yìn tó o bá ti wo fídíò náà, ronú nípa àwọn ìbéèrè yìí.
Báwo ni fídíò náà ṣe mú kó o túbọ̀ mọrírì (1) ìsapá tí ètò Jèhófà ńṣe láti wàásù ìhìn rere? (2 Tím. 4:2) (2) ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà káàkiri ayé? (3) ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá à ń fún àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn alábòójútó? (2 Tím. 2:2) (4) bó ti ṣe pàtàkì tó láti bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú kíka ẹsẹ Bíbélì kan àti mímúra sílẹ̀ fún ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀? (Ìṣe 17:11) (5) àǹfààní tó wà nínú lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni? (Héb. 10:24, 25) (6) àǹfààní tó o máa ní nígbà tí Párádísè bá dé? (Aísá. 11:9) (7) àǹfààní tó o ní láti máa kópa nínú iṣẹ́ ìkórè tó ń lọ lọ́wọ́?—Jòh. 4:35.
Fídíò yìí ti jẹ́ irinṣẹ́ tó wúlò gan-an láti mú kí àwọn olùfìfẹ́hàn mọ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé. (8) Ìgbà wo ló dára jù lọ láti fi fídíò yìí han àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìbátan wa àtàwọn míì? (9) Àwọn ọ̀rọ̀ tó wúni lórí wo làwọn èèyàn sọ nígbà tó o fi fídíò náà hàn wọ́n?
Bá a ṣe ń ronú nípa àwọn ohun tí Jèhófà ti gbé ṣe, ó ń sún wa láti tún ọ̀rọ̀ onísáàmù yìí sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣe, Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, àní àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti ìrònú rẹ sí wa; kò sí ẹnì kankan tí a lè fi ọ́ wé.” (Sm. 40:5) Ẹ jẹ́ ká máa lo fídíò náà lọ́nà táá mú kí àwọn èèyàn túbọ̀ mọrírì Jèhófà àti ètò rẹ̀!