Àwọn Irin Iṣẹ́ Tó Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́, Tó Ń Súnni Ṣiṣẹ́, Tó sì Tún Ń Fúnni Lókun
1 Wọ́n lágbára gan-an fún kíkọ́ àwọn èèyàn nípa Bíbélì àti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn mú ìdúró gbọn-in gbọ-in fún òtítọ́. Wọ́n ti fún ìgbàgbọ́ àti ìmọrírì àwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n ti ṣe ìyàsímímọ́ lókun. Kí tiẹ̀ làwọn nǹkan náà. Àwọn fídíò tí ètò àjọ Jèhófà ṣe ni. Ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti wo mẹ́wẹ̀ẹ̀wá? Ìgbà wo lo ti wò wọ́n gbẹ̀yìn? Ṣé o máa ń lò wọ́n nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ? Ǹjẹ́ o ti kọ̀wé béèrè fún èyíkéyìí nínú wọn? Báwo lo ṣe lè jàǹfààní síwájú sí i látinú àwọn irin iṣẹ́ àgbàyanu yìí?
2 Àpilẹ̀kọ náà, “Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Déédéé Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé,” tí ó wà nínú Ilé Ìṣọ́ July 1, 1999, dámọ̀ràn pé “ya àkókò pàtó sọ́tọ̀ láti wo díẹ̀ lára àwọn fídíò Society tó kún fún ẹ̀kọ́ . . . lẹ́yìn náà kẹ́ẹ wá jíròrò rẹ̀.” Ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn dáradára yẹn, a óò máa gbé fídíò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yẹ̀ wò nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní oṣù mẹ́ta-mẹ́ta síra. A fún olúkúlùkù nínú ìjọ níṣìírí láti wo fídíò náà nílé kó tó dìgbà tí a máa jíròrò rẹ̀ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn.
3 Lóṣù yìí, a máa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú fídíò àkọ́kọ́ tí a ṣe, ìyẹn ni Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name. Wò ó kí o sì fetí sí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:
◼ Kí ni a mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jù lọ fún?
◼ Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ní a so gbogbo ohun tí a ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì mọ́?
◼ Nǹkan wo tó ṣẹlẹ̀ nínú Bíbélì lo rí tí a ṣe, tí a yà ní fọ́tò, tí a sì wá kùn lọ́dà fún lílò nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa?
◼ Kí ni ohun tó wọ̀ ọ́ lọ́kàn nípa ọ̀nà tí a ń gbà ṣe ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa?
◼ Ẹyọ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mélòó ni Society tẹ̀ jáde láti ọdún 1920 sí 1990?
◼ Àwọn wo ní pàtàkì láàárín àwọn ènìyàn Ọlọ́run ló yẹ kó tẹ̀ síwájú láti tóótun fún iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì?—Òwe 20:29.
◼ Láwọn ọ̀nà wo ni ìdílé Bẹ́tẹ́lì ti fi àpẹẹrẹ tó tayọ lélẹ̀ fún gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
◼ Kí ló wú ọ lórí nípa iṣẹ́ tí a ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì láti mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó?
◼ Báwo la ṣe ń pèsè owó tí à ń ná sí iṣẹ́ náà yíká ayé?
◼ Ìgbòkègbodò wo la lè fìtara tì lẹ́yìn, ẹ̀mí wo ló sì yẹ ká fi ṣe é?—Jòh. 4:35; Ìṣe 1:8.
◼ Kí lo rò nípa ètò àjọ náà tí à ń jẹ́ orúkọ mọ́?
◼ Báwo lo ṣe lè lo fídíò yìí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́?
Lóṣù December, a óò ṣàyẹ̀wò fídíò tó ń jẹ́ The Bible—Accurate History, Reliable Prophecy.