ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/00 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 9
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 16
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 23
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 30
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 6
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 10/00 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

ÀKÍYÈSÍ: Ní gbogbo àkókò tí a fi máa gbé àwọn fídíò Society yẹ̀ wò ní àwọn ìpàdé iṣẹ́ ìsìn, a óò pèsè àwọn àkójọ ọ̀rọ̀ tí yóò jẹ́ àfidípò. A ó lo èyí nígbà tó bá ṣẹlẹ̀ pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn akéde kò tíì wo fídíò náà tàbí tí wọn ò tiẹ̀ ní lè wò ó ṣáájú ọjọ́ tí a ṣètò.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 9

Orin 11

8 min: Ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ táa mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.

12 min: “Máa Lọ sí Àwọn Àpéjọ àti Àpéjọpọ̀ ní Àwọn Ibi Tí Ètò Àjọ Jèhófà Yàn.” Kí alàgbà kan bójú tó o lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 5.

25 min: “Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun—Kí Ni Ká Máa Retí?” Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn jíròrò rẹ̀ tìtaratìtara. Lẹ́yìn tí o bá ti ka ìfilọ̀ tó wà nínú lẹ́tà July 3, 2000, tí Society kọ sí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà, kí o fún olúkúlùkù àwọn tó pésẹ̀ sípàdé ní ẹ̀dà kan Ìròyìn Ìjọba No. 36. Lẹ́yìn náà, kí o wá jíròrò àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Sọ ètò tí ìjọ ti ṣe láti kárí gbogbo ìpínlẹ̀ tí ó jẹ́ ti ìjọ náà. Ṣàgbéyẹ̀wò bí a ṣe lè ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ kí wọ́n bàa lè tóótun láti di akéde tí kò tí ì ṣe batisí. Jẹ́ kí á ṣe àṣefihàn kan tí kò gùn. Tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí gbogbo wa kópa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú ìpínkiri yìí.

Orin 53 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 16

Orin 104

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Rán àwọn akéde létí pé àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! pẹ̀lú Ìròyìn Ìjọba No. 36 ni a óò fi lọni nínú ìgbòkègbodò òpin ọ̀sẹ̀.

15 min: “Àwọn Irin Iṣẹ́ Tó Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́, Tó Ń Súnni Ṣiṣẹ́, Tó sì Tún Ń Fúnni Lókun.” (Ìpínrọ̀ 1 àti 2 nìkan.) Àsọyé. Ní ṣókí, ṣàtúnyẹ̀wò bí Society ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ṣe fídíò jáde. (Wo ìwé Proclaimers, ojú ìwé 600 àti 601.) Fún àwùjọ níṣìírí láti wo fídíò Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name ní ìmúrasílẹ̀ fún ìjíròrò rẹ̀ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ October 30. Àwọn tí wọ́n ní fídíò náà lè fún àwọn tí kò ní láti wò ó, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ jọ wò ó pa pọ̀. TÀBÍ “Fífi Ọwọ́ Títọ̀nà Mú Ọ̀rọ̀ Òtítọ́.” Àsọyé tí a gbé karí Ilé Ìṣọ́ January 1, 1996, ojú ìwé 29 sí 31.

20 min: Gbogbo Wa Lè Fi Ẹ̀mí Aṣáájú Ọ̀nà Hàn. Ìjíròrò láàárín olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ àti olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, a gbé e karí Ilé Ìṣọ́ October 15, 1997, ojú ìwé 22 àti 23. Ẹ jíròrò ìdí tó fi dára láti ní àwọn aṣáájú ọ̀nà púpọ̀ sí i nínú ìjọ, àti bí gbogbo akéde ṣe lè sa ipá tiwọn láti bá góńgó yìí. Ẹ tún jíròrò àwọn ọ̀nà tí a lè gbà fún àwọn tí wọ́n ń ṣe aṣáájú ọ̀nà lọ́wọ́ báyìí níṣìírí pé kí wọ́n máa bá a nìṣó àti bí gbogbo ará nínú ìjọ ṣe lè ní ìtara púpọ̀ sí i fún iṣẹ́ òjíṣẹ́.

Orin 131 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 23

Orin 150

10 min: Àwọn Ìfilọ̀ ìjọ.

15 min: “Jàǹfààní Nínú Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Jèhófà.” Àsọyé. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti máa wá déédéé sí àwọn ìpàdé márààrún tí ìjọ máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

20 min: Ẹ Múra Àwọn Ìpàdé Sílẹ̀ Dáadáa. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Àǹfààní tí a ń jẹ nínú ìpàdé sinmi púpọ̀ lórí bí ìsapá tí a ṣe láti múra sílẹ̀ ti pọ̀ tó. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn àmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ tí a fún wa nínú Ilé Ìṣọ́ March 1, 1998, ojú ìwé 15 àti 16, ìpínrọ̀ 8 sí 11. Sọ pé kí àwùjọ ṣàlàyé bí wọ́n ṣe mú ìfẹ́ fún mímúra ìpàdé sílẹ̀ dàgbà àti bí wọ́n ṣe wá àkókò fún mímúrasílẹ̀.

Orin 211 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 30

Orin 167

8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán gbogbo akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù October sílẹ̀.

12 min: Àwọn Ìrírí Tí A Ní Nígbà Tí A Fi Ìròyìn Ìjọba No. 36 Lọni. Sọ pé kí àwọn akéde mélòó kan lónírúurú sọ àwọn àbájáde tó ń fúnni níṣìírí tí wọ́n ní nínú pípín Ìròyìn Ìjọba No. 36. Sọ pé kí àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé àti aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ sọ ìmọrírì tí wọ́n ní fún ìgbòkègbodò tó túbọ̀ pọ̀ sí i nígbà ìpínkiri yìí àti àǹfààní tí wọ́n ní láti bá oríṣiríṣi akéde ṣiṣẹ́.

25 min: Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Jíròrò àwọn ìbéèrè tó wà ní ìpínrọ̀ kẹta “Àwọn Irin Iṣẹ́ Tó Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́, Tó Ń Súnni Ṣiṣẹ́, Tó sì Tún Ń Fúnni Lókun.” Fún àwùjọ ní ìmọ̀ràn lórí bí a ṣe lè fi fídíò yìí ran àwọn tó ń fìfẹ́ hàn lọ́wọ́ láti túbọ̀ dojúlùmọ̀ ètò àjọ wa sí i. Fi ìrírí kan tàbí méjì tí kò gùn kún un.—Wo Ilé Ìṣọ́, October 1, 1992, ojú ìwé 30 àti 31. TÀBÍ “Ìtùnú àti Ìṣírí—Àwọn Ohun Iyebíye Alápá Púpọ̀.” Àsọyé tí a gbé ka Ilé Ìṣọ́ January 15, 1996, ojú ìwé 21 sí 23.

Orin 15 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 6

Orin 198

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ṣàyẹ̀wò bí ìpínkiri Ìròyìn Ìjọba No. 36 ṣe ń tẹ̀ síwájú. Sọ iye ìpínlẹ̀ tí ẹ ti ṣe látìgbà tí a ti bẹ̀rẹ̀ ìpínkiri yìí àti àwọn ohun tí ẹ ní láti ṣe kí ẹ lè kárí gbogbo ìpínlẹ̀ tó kù títí November 17.

20 min: Kí La Gbà Gbọ́? Arákùnrin kan ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹnì kan tó béèrè pé, “Kí ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ni tó mú kí wọ́n yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀sìn yòókù?” Jíròrò àwọn kókó inú àpótí tó wà ní ojú ìwé 6 nínú Ilé Ìṣọ́ October 1, 1998. Ṣàlàyé bí àwọn ẹ̀sìn yòókù ṣe fojú kéré tàbí kọ àwọn lájorí òtítọ́ inú Bíbélì sílẹ̀ nítorí àwọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́.

10 min: Orin Kíkọ—Apá Pàtàkì Ìjọsìn Wa. Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kan bá akéde kan tàbí méjì sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń kọrin ní àwọn ìpàdé ìjọ. Ó ti kíyè sí i pé ọ̀nà tí wọ́n gbà ń kọrin kò tani jí. Ó jíròrò àwọn kókó díẹ̀ látinú Ilé Ìṣọ́ February 1, 1997, ojú ìwé 27 àti 28 pẹ̀lú wọn. Wọ́n ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ inú ọ̀kan lára àwọn orin tí wọn yóò kọ ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ní ọ̀sẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí a ṣe dá a lábàá nínú Ilé Ìṣọ́, July 1, 1999, ojú ìwé 20, ìpínrọ̀ 12. Bí a bá ń fi tọkàntọkàn kọrin, ńṣe là ń fi ara yíyá gágá yin Jèhófà lógo.

Orin 223 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́