Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù October: Àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Bí wọ́n bá fi ìfẹ́ hàn nígbà ìpadàbẹ̀wò, a lè fi ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn lọ̀ wọ́n. A ó bẹ̀rẹ̀ sí í pín Ìròyìn Ìjọba No. 36 láti October 16. November: Pípín Ìròyìn Ìjọba No. 36 yóò máa bá a nìṣó. Àwọn ìjọ tó bá kárí ìpínlẹ̀ wọn tán nípa mímú Ìròyìn Ìjọba No. 36 dé ọ̀dọ̀ gbogbo onílé àti ibi tí àwọn ènìyàn wà, lè fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí ìwé Ìmọ̀ lọni. Bí àwọn èèyàn bá ti ní ìwọ̀nyí tẹ́lẹ̀, a lè lo ìwé Walaaye Titilae. December: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. January: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí ìjọ bá ní, tí a ti tẹ̀ jáde ṣáájú ọdún 1986.
◼ “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run ti Ọdún 2001” ni àkìbọnú tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí, kí ẹ tọ́jú rẹ̀ kí ẹ lè rí i lò jálẹ̀ ọdún 2001.
◼ Bí àwọn àkókò tí ìjọ yín máa ń ṣe ìpàdé yóò bá yí padà ní January 1, kí akọ̀wé fi ìyípadà náà tó Society létí nípa fífi fọ́ọ̀mù Congregation Meeting Information and Handbill Request (S-5) ránṣẹ́ sí Society. Bí ẹ bá ń fẹ́ ìwé ìléwọ́ tuntun, ẹ lè fi fọ́ọ̀mù kan náà béèrè fún un. Kí ẹ rí i dájú pé ẹ kọ̀wé béèrè fún ìwé ìléwọ́ ní, ó kéré tán, ọ̀sẹ̀ mẹ́jọ ṣáájú àkókò tí ẹ fẹ́ kó tẹ̀ yín lọ́wọ́.
◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tó Wà Báyìí:
Ayé Yii Yoo Ha Làájá Bi? (Ìwé àṣàrò kúkúrú No. 19)—Gẹ̀ẹ́sì
Gbadun Igbesi-Aye Idile (Ìwé àṣàrò kúkúrú No. 21)—Gẹ̀ẹ́sì
Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!—Gẹ̀ẹ́sì
Igbesi-aye ninu Aye Titun alalaafia kan (Ìwé àṣàrò kúkúrú No. 15)—Gẹ̀ẹ́sì
Ìtùnú fun Awọn ti o Soríkọ́ (Ìwé àṣàrò kúkúrú No. 20)—Gẹ̀ẹ́sì
Ireti Wo ni Ó Wà fun Awọn Ololufẹ Tí wọn Ti Kú? (Ìwé àṣàrò kúkúrú No. 16)—Gẹ̀ẹ́sì
Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ẹ́fíìkì, Gẹ̀ẹ́sì
Ki Ni Ète Igbesi-Aye?
Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?—Ìgbò
Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?—Ìgbò, Yorùbá
Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì!—Ẹ́fíìkì
Our Problems—Who Will Help Us Solve Them?—Gẹ̀ẹ́sì
Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí—Ẹ́fíìkì, Gẹ̀ẹ́sì
Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?—Gẹ̀ẹ́sì
Ta Ni Ń Ṣakoso Ayé Niti Tòótọ? (Ìwé àṣàrò kúkúrú No. 22)—Gẹ̀ẹ́sì
◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà:
Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́—Ẹ́fíìkì