Ipa Tí Àwọn Fídíò Tá A Fi Ń Jẹ́rìí Ń Ní Lórí Àwọn Èèyàn
1 “Kí ọmọkùnrin wa tó bẹ̀rẹ̀ sí í rìn ló ti ń wo fídíò ọ̀hún. Ńṣe ló máa ń wò ó láwòtúnwò. Ó mà dára tá a ní àwọn ohun èlò tó lè gbin ìfẹ́ fún Jèhófà sínú àwọn ọmọ wa o!” Fídíò wo ni òbí Kristẹni yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Èyí tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Noah—He Walked With God [Nóà—Ó Bá Ọlọ́run Rìn] ni. Ìyá kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ẹni tí ọmọkùnrin rẹ̀ ti wo fídíò Noah nílé ẹnì kan, fi ọrẹ owó tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà ó lé irínwó àti méjìdínlọ́gọ́ta [₦10,458] ránṣẹ́ sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa, ó sì béèrè bóyá a tún ní àwọn fídíò mìíràn tó wà fáwọn ọmọdé. Àwọn fídíò tí ètò àjọ Jèhófà mú jáde ń nípa tó lágbára lórí tọmọdé tàgbà.
2 Nínú Ìdílé: Lẹ́yìn tí ìdílé Ẹlẹ́rìí kan ti wo fídíò Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault [Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Dúró Gbọn-in Láìkà Àtakò Gbígbóná Janjan Nazi Sí], ìyá wọn sọ pé: “Mo máa ń fìgbà gbogbo ronú nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn lásánlàsàn láti fara da àwọn ìyà tó pọ̀ lápọ̀jù yìí! Ríronú nípa èyí máa ń rán mi létí bí àwọn ìṣòro tí mo ní kò ṣe jẹ́ nǹkankan rárá lẹ́gbẹ̀ẹ́ tiwọn. Wíwo fídíò yìí pẹ̀lú àwọn ọmọ wa ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti túbọ̀ rí i kedere pé ó ṣe pàtàkì láti gbára lé Jèhófà. Nípa jíjíròrò rẹ̀ pẹ̀lú wọn lẹ́yìn náà, a ti ran àwọn ọmọbìnrin wa lọ́wọ́ láti túbọ̀ gbára dì kí wọ́n bàa lè kojú ìṣòro tàbí inúnibíni èyíkéyìí tí wọ́n lè bá pàdé.”
3 Ní Ilé Ẹ̀kọ́: Ọ̀dọ́langba Ẹlẹ́rìí kan fi díẹ̀ lára fídíò Stand Firm han àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí apá kan iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ṣáájú ìgbà yẹn, olùkọ́ rẹ̀ ti sọ pé òun kò fẹ́ràn àwọn Ẹlẹ́rìí. Lẹ́yìn tó wo fídíò náà, ó sọ pé: “Fídíò yìí ti jẹ́ kí ojú tí mo fi ń wo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yí padà pátápátá. Mo ṣèlérí pé nígbà tí wọ́n bá tún wá sẹ́nu ọnà mi, màá fetí sílẹ̀ sí wọn, màá sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ wọn!” Kí lohun tó yí èrò tó ní nípa wa padà? Ó sọ pé ohun náà ni “ìfẹ́ tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin wa.”
4 Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́: Arábìnrin kan pàdé obìnrin kan tó lọ́ tìkọ̀ láti tẹ́wọ́ gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní àwọn ìbéèrè kan tó fẹ́ béèrè nípa wa àti nípa àwọn ohun tá a gbà gbọ́. Arábìnrin náà padà lọ pẹ̀lú fídíò náà, Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name [Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ètò Àjọ Tí Ń Jẹ́ Orúkọ Yẹn], ó sì jẹ́ kí obìnrin náà àti ọkọ rẹ̀ wò ó. Fídíò yìí wú wọn lórí gan an, wọ́n sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Látàrí ìjẹ́rìí àtàtà tí wọ́n ti gbà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìgbésí ayé wọn bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.
5 Ṣé ò ń lo àwọn fídíò wa bó ti tọ́ àti bó ti yẹ lọ́nà tí wọ́n á fi ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn?