Máa Lo Fídíò Láti Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
1. Báwo ni Jèhófà ṣe lo ohun tó ṣeé rí láti kọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ìgbàanì lẹ́kọ̀ọ́, ipa wo ló sì ní?
1 Bí Jèhófà bá fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lóye àwọn ìsọfúnni kan tó ṣe kókó, nígbà míì ó máa ń lo ìran àti àlá. Ṣé o rántí ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa kẹ̀kẹ́ ẹṣin òkè ọ̀run Jèhófà? (Ìsík. 1:1-28) Wo bó ṣe rí lára Dáníẹ́lì lẹ́yìn tá a ti fi àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ àwọn agbára ayé hàn án lójú àlá. (Dán. 7:1-15, 28) Tá a bá tiẹ̀ tún wá ń sọ nípa ti ìṣípayá amóríyá tá a fi han àpọ́sítélì Jòhánù nípasẹ̀ “àwọn àmì” tó dá lórí àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lákòókò “ọjọ́ Olúwa” ńkọ́? (Ìṣí. 1:1, 10) Jèhófà bá àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sọ̀rọ̀ nípa lílo àwòrán mèremère àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àràmàǹdà, nípa bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ fún wọn wà lọ́kàn wọn fún àkókò pípẹ́.
2. Kí la lè lò láti fi kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ Bíbélì?
2 Bá a bá fẹ́ ṣàlàyé òtítọ́ Bíbélì kó sì wọ àwọn èèyàn lọ́kàn débi tí wọn ò fi ní tètè gbàgbé, àwa náà lè lo àwọn fídíò wa láti kọ́ni. Àwọn fídíò wa sọ̀rọ̀ lórí ọ̀pọ̀ kókó ẹ̀kọ́, wọ́n ń jẹ́ ká lè ní ìgbàgbọ́ nínú Bíbélì àti ètò Jèhófà, wọ́n sì ń jẹ́ ká lè máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Kristẹni tó lè jẹ́ kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀. Wo àwọn ọ̀nà díẹ̀ tá a lè gbà lo àwọn fídíò wa láti kọ́ni. Àpẹẹrẹ àwọn fídíò tá a lè lò rèé.
3. Kí lo lè lò láti darí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sínú ètò Ọlọ́run?
3 Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́: Ṣó o ti ń sọ fún ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nípa bá a ṣe jẹ́ ẹgbẹ́ ará kárí ayé? Fi fídíò náà Our Whole Association of Brothers hàn án. O lè yá a pé kó wò ó kó o tó padà wá nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tàbí kẹ́ ẹ jọ wò ó nígbà tó o bá padà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn náà kẹ́ ẹ jọ wá jíròrò àwọn ìbéèrè tó wà fún àtúnyẹ̀wò nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 2002.
4. Irin iṣẹ́ ìkọ́ni wo ni ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan lè lò nílé ẹ̀kọ́?
4 Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ lè bá olùkọ́ yín sọ̀rọ̀ bóyá wọ́n á lè fún yín láyè láti ṣàfihàn àwọn fídíò bíi Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault tàbí Faithful Under Trials—Jehovah’s Witnesses in the Soviet Union fáwọn tẹ́ ẹ jọ wà ní kíláàsì. Sọ pé àwọn ìbéèrè kan wà lórí fídíò náà tí wàá mú wá. Kó o wá tún àwọn ìbéèrè tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 2001 tàbí ti February 2003 kọ lọ́nà tó máa bá àwọn ọmọ kíláàsì rẹ mu.
5. Kí làwọn òbí ní níkàáwọ́ láti lò nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé?
5 Pẹ̀lú Ìdílé Yín Àtàwọn Ọ̀rẹ́ Yín: Ẹ̀yin òbí, ǹjẹ́ ẹ kíyè sí i pé ó ti ṣe díẹ̀ táwọn ọmọ yín ti wo fídíò náà, Young People Ask—How Can I Make Real Friends? kẹ́yìn. Ẹ ò ṣe tún un wò nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín tó máa tẹ̀lé e? Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti April 2002 ṣètòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìbéèrè tá a fi lè jíròrò rẹ̀ táá fi lárinrin tí òótọ́ ibẹ̀ á sì jáde.
6. Ọ̀nà wo lo lè gbà ṣètò láti gbádùn àkókò tí ń gbéni ró pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ?
6 Ṣé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ kan wà nínú ìjọ tẹ́ ẹ lè pè wá sílé yín? Bẹ́ ẹ bá jọ wo fídíò Respect Jehovah’s Authority lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́, ó máa jẹ́ ìrọ̀lẹ́ alárinrin tí ń gbéni ró pàápàá tẹ́ ẹ bá lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 2004 láti jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ tó wà níbẹ̀.
7. Àwọn ọ̀nà mìíràn wo lo rò pé o lè gbà lo àwọn fídíò wa?
7 Àwọn Àǹfààní Mìíràn: Ọ̀nà mìíràn wo lo lè gbà lo àwọn fídíò wa tí iye wọn jẹ́ ogún? Ǹjẹ́ fífi ọ̀kan tàbí méjì lára àwọn fídíò náà han ẹni tó o máa ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ déédéé á jẹ́ kó máa tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Ṣé o lè lọ ṣàfihàn rẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn ọmọ aláìlóbìí? Ǹjẹ́ o rò pé fídíò yìí ò ní jẹ́ káwọn mọ̀lẹ́bí rẹ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, àwọn aládùúgbò àtàwọn tẹ́ ẹ jọ wà níbi iṣẹ́ kan náà yí ojú tí wọ́n fi ń wo ohun tá a gbà gbọ́ padà? Àwọn fídíò wa máa ń wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, wọ́n ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ táá yéni yékéyéké. Lò wọ́n láti kọ́ni.